Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

BÍBÉLÌ MÁA Ń YÍ ÌGBÉSÍ AYÉ ÀWỌN ÈÈYÀN PA DÀ

Ńṣe Layé Mi Túbọ̀ Ń Bà Jẹ́ Sí I

Ńṣe Layé Mi Túbọ̀ Ń Bà Jẹ́ Sí I
  • Ọdún Tí Wọ́n Bí Mi: 1971

  • Orílẹ̀-Èdè Mi: Tonga

  • Irú Ẹni Tí Mo Jẹ́ Tẹ́lẹ̀: Mò ń loògùn olóró, ẹlẹ́wọ̀n

ÌGBÉSÍ AYÉ MI ÀTẸ̀YÌNWÀ

 Orílẹ̀-èdè Tonga tó ní àádọ́sàn-án (170) erékùṣù, ní gúúsù ìwọ̀ òòrùn Òkun Pàsífíìkì ni ìdílé mi ti wá. Ní Tonga a ò fi bẹ́ẹ̀ rí já jẹ, kò sí iná, bẹ́ẹ̀ ni kò sí mọ́tò. Àmọ́ a lómi ẹ̀rọ àtàwọn adìyẹ díẹ̀. Nígbà ọlidé, èmi, ẹ̀gbọ́n mi àtàbúrò mi tá a jẹ́ ọkùnrin máa ń bá bàbá wa ṣiṣẹ́ lóko iṣu, pákí, ọ̀gẹ̀dẹ̀ àti kókò. Àwọn irè oko yìí ni ìdílé wa fi ń gbéra torí owó tó ń wọlé nídìí iṣẹ́ tí bàbá wa ń ṣe kò tó nǹkan. Ìdílé wa ní ọ̀wọ̀ tó jinlẹ̀ fún Bíbélì, a ò sì ń pa ṣọ́ọ̀ṣì jẹ bíi ti ọ̀pọ̀ àwọn aládùúgbò wa. Síbẹ̀, a gbà pé téèyàn bá fẹ́ gbádùn ìgbésí ayé tó dáa àfi kó lọ sí orílẹ̀-èdè tí nǹkan ti rọ̀ṣọ̀mù.

 Nígbà tí mo pé ọmọ ọdún mẹ́rìndínlógún (16), àbúrò ìyá mi ṣètò pé kí ìdílé wa kó lọ sí ìpínlẹ̀ Kalifóníà, lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà. Ara wa ò tètè mọlé torí àṣà àwọn ará ibẹ̀ yàtọ̀ pátápátá sí ti Tonga. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé nǹkan túbọ̀ ṣẹnuure fún wa, àdúgbò táwọn ọ̀daràn àtàwọn tó ń lo oògùn olóró pọ̀ sí là ń gbé. Ọ̀pọ̀ ìgbà la máa ń gbọ́ ìró ìbọn lálẹ́, tí ẹ̀rù á sì máa ba àwọn aládùúgbò torí àwọn ọ̀daràn yẹn. Ọ̀pọ̀ èèyàn máa ń mú ìbọn dání láti dáàbò bo ara wọn tàbí kí wọ́n fi parí ìjà. Kódà ọta ìbọn kan tí wọ́n yìn lù mí níbi tí wọ́n ti ń jà ṣì wà láyà mi.

 Nígbà tí mo wà nílé ìwé girama, ó wù mí kí n máa ṣe bíi tàwọn ọ̀dọ́ ẹlẹgbẹ́ mi. Díẹ̀díẹ̀ nimú ẹlẹ́dẹ̀ mi ń wọgbà, mo bẹ̀rẹ̀ sí í lọ sáwọn àríyá aláriwo, ọtí àmuyíràá, ìwà ipá àtàwọn oògùn tí ò bófin mu sì tún di ara fún mi. Nígbà tó yá, kokéènì di bárakú fún mi. Mo tún bẹ̀rẹ̀ sí í jalè kí n lè máa rówó ra oògùn olóró. Nínú ìdílé wa, a ò fi lílọ sí ṣọ́ọ̀ṣì ṣeré rárá, síbẹ̀ mi ò fìgbà kankan rí ìtọ́sọ́nà gbà lórí bí mi ò ṣe ní màa báwọn ẹgbẹ́ mi hùwà tí kò tọ́. Ọ̀pọ̀ ìgbà lọwọ́ àwọn ọlọ́pàá tẹ̀ mí torí ìwà ipá tí mò ń hù. Ńṣe layé mi túbọ̀ ń bà jẹ́ sí i. Ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, mo dèrò ẹ̀wọ̀n.

BÍ BÍBÉLÌ ṢE YÍ ÌGBÉSÍ AYÉ MI PA DÀ

 Lọ́jọ́ kan nígbà tí mo ṣì wà lẹ́wọ̀n lọ́dún 1997, ẹlẹ́wọ̀n kan rí Bíbélì lọ́wọ́ mi. Ọjọ́ Kérésìmesì ni, ọ̀pọ̀ àwọn ará Tonga ló sì kà á sí ọjọ́ mímọ́. Ó bi mí pé ṣé mo mọ ohun tí Bíbélì sọ nípa ìbí Jésù, àmọ́ mi ò mọ nǹkan kan nípa ẹ̀. Ó fi ìtàn tó ṣe kedere tí Bíbélì sọ nipa ìbí Jésù hàn mí, mo wá rí i pé ọ̀pọ̀ nǹkan táwọn èèyàn ń ṣe lọ́jọ́ Kérésìmesì ni ò sí nínú Bíbélì. (Mátíù 2:​1-12; Lúùkù 2:​5-14) Ìyàlẹ́nu gbáà ló jẹ́ fún mi, ó sì wù mí kí n mọ àwọn nǹkan míì tí Bíbélì sọ. Ọ̀gbẹ́ni yẹn ti ń lọ sí ìpàdé táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń ṣe lọ́gbà ẹ̀wọ̀n lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀, èmi náà bá bẹ̀rẹ̀ sí í bá a lọ. Ìwé Ìfihàn inú Bíbélì ni wọ́n ń jíròrò. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé díẹ̀ ló yé mi nínú ohun tí wọ́n ń sọ, mo rí i pé inú Bíbélì ni gbogbo ohun tí wọ́n ń kọ́ni ti wá.

 Tayọ̀tayọ̀ ni mo gbà nígbà táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà bi mí pé ṣé màá fẹ́ kí wọ́n máa kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Fúngbà àkọ́kọ́, mo kẹ́kọ̀ọ́ nípa ìlérí Ọlọ́run pé ayé máa di Párádísè. (Àìsáyà 35:​5-8) Ó wá ṣe kedere sí mi pé tí mo bá fẹ́ múnú Ọlọ́run dùn, àfi kí n ṣe àwọn ìyípadà tó pọn dandan ní ìgbésí ayé mi. Àti pé Ọlọ́run ò ní fàyè gba àwọn ìwà búburú bẹ́ẹ̀ nínú Párádísè. (1 Kọ́ríńtì 6:​9, 10) Torí náà mo pinnu pé máà jáwọ́ nínú bíbínú lọ́nà òdì, mímu sìgá, ọtí àmuyíràá pẹ̀lú lílo oògùn olóró.

 Lọ́dún 1999, àwọn aláṣẹ gbé mi lọ sí ẹ̀wọ̀n míì. Ó lé lọ́dún kan ti mi ò fi rí àwọn Elẹ́rìí Jèhófà mọ́. Ṣùgbọ́n mo pinnu pé mi ò ní jáwọ́ ṣíṣe àwọn ìyípadà rere yẹn. Ìjọba lé mi kúrò ní Amẹ́ríkà lọ́dún 2000, wọ́n sì dá mi pa dà sí Tonga.

 Bí mo ṣe dé Tonga, mo wá àwọn Elẹ́rìí Jèhófà lójú méjèèjì, mo sì bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pa dà. Mo fẹ́ràn ohun tí mò ń kọ́, ó sì wú mi lórí pé bí wọ́n ṣe ń lo Bíbélì láti fi kọ́ni ní Amẹ́ríkà náà ni wọ́n ń ṣe ní Tonga.

 Olóyè pàtàkì ni Bàbá mi nínú ṣọ́ọ̀ṣì, èyí jẹ́ kí wọ́n gbajúmọ̀ ládùúgbò wa. Torí náà, ẹ̀dùn ọkàn kọ́kọ́ bá àwọn ará ilé mi bí wọ́n ṣe ń rí mi pẹ̀lú àwọn Elẹ́rìí Jèhófà. Àmọ́, nígbà tó yá, inú àwọn òbí mi dùn pé àwọn ìlànà Bíbélì ti mú kí n jáwọ́ nínú àwọn ìwà burúkú.

Ọ̀pọ̀ àkókò ni mo máa ń lò nídìí ọtí kava lọ́ṣọ̀ọ̀ṣẹ̀ bíi ti ọ̀pọ̀ ọkùnrin tó jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Tonga

 Ọ̀kan lára àwọn ohun tó ṣòro fún mi jù lọ láti jáwọ́ nínú ẹ̀ ni mímu ọtí ìbílẹ̀ kan tó ń jẹ́ kava tí wọ́n fi gbòǹgbò ata ṣe. Ọ̀pọ̀ àkókò lọ̀pọ̀ ọmọ ilẹ̀ Tonga lọ́kùnrin máa ń lò nídìí ọtí yìí lọ́ṣọ̀ọ̀ṣẹ̀. Ní bàyìí tí mo ti pa dà sílé, mo bẹ̀rẹ̀ sí í lọ sí ilé ọtí kava, màá sì mu ún títí màá fi yó kẹ́ri. Ohun míì tún ni pé mo bẹ̀rẹ̀ sí í bá àwọn tí kò fọwọ́ pàtàkì mú ìlànà Bíbélì rìn. Àmọ́ nígbà tó yá, ẹ̀kọ́ tí mò ń kọ́ jẹ́ kí n rí i pé àwọn àṣà yìí ò dùn mọ́ Ọlọ́run nínú. Mo bá bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe ìyípadà kí n lè rí ìbùkún Ọlọ́run àti ojú rere rẹ̀.

 Mo bẹ̀rẹ̀ sí í lọ sí gbogbo ìpàdé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Èyí ló mú kí n lè kojú àwọn ìdẹwò yẹn. Lọ́dún 2002, mo ṣèrìbọmi, mo sì di Ẹlẹ́rìí Jèhófà.

ÀǸFÀÀNÍ TÍ MO TI RÍ

 Mo ti jọlá sùúrù Ọlọ́run bí Bíbélì ṣe sọ pé: “Jèhófà . . . ń mú sùúrù fún yín torí kò fẹ́ kí ẹnikẹ́ni pa run sùgbọ́n ó fẹ́ kí gbogbo èèyàn ronú pìwà dà.” (2 Pétérù 3:⁠9) Ó kúkú lágbára láti fòpin sí ayé oníwà búburú yìí tipẹ́tipẹ́, àmọ́ kò ṣe bẹ́ẹ̀ torí ó fẹ́ kí irú àwọn èèyàn bíi tèmi wá di ọ̀rẹ́ òun. Mo máa ń rò ó pé ó lè lò mí láti ran àwọn ẹlòmíì lọ́wọ́ káwọn náà sì yí pa dà.

 Jèhófà ti ràn mí lọ́wọ́ láti yí ìgbésí ayé mi pa dà sí rere. Mi ò jalè mọ́ láti fi ra oògùn olóró tó ti di bárakú fún mi. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ni mò ń ran ọmọnìkejì mi lọ́wọ́ láti wá di ọ̀rẹ́ Jèhófà. Ọ̀dọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí mò ń bá rìn ni mo ti rí ìyàwó mi àtàtà tí mo fẹ́, Tea lorúkọ rẹ̀. A ti bí ọmọkùnrin kékeré kan, ìdílé wa sì ń láyọ̀. A jọ máa ń kọ́ àwọn míì ní ohun tí Bíbélì sọ nípa ọjọ́ iwájú pé àwa èèyàn máa gbé títí láé ní àlàáfíà nínú Párádísè.