Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Ṣé Ẹ̀ṣẹ̀ Ni Tẹ́tẹ́ Títa?

Ṣé Ẹ̀ṣẹ̀ Ni Tẹ́tẹ́ Títa?

Ohun tí Bíbélì sọ

 Bíbélì ò ṣe kúlẹ̀kúlẹ̀ àlàyé nípa tẹ́tẹ́ títa, àmọ́ a lè fi òye mọ̀ pé ẹ̀ṣẹ̀ ni tẹ́tẹ́ títa lójú Ọlọ́run tá a bá ronú lórí àwọn ìlànà Bíbélì kan nípa rẹ̀.​—Éfésù 5:17. a

  •   Ojú kòkòrò ló máa ń fa tẹ́tẹ́ títa, Ọlọ́run sì kórìíra ojú kòkòrò. (1 Kọ́ríńtì 6:9, 10; Éfésù 5:3, 5) Àwọn tó ń ta tẹ́tẹ́ máa ń retí pé káwọn jèrè látinú àdánù àwọn mìíràn, Bíbélì kórìíra kí ojú èèyàn máa wọ nǹkan oníǹkan.​—Ẹ́kísódù 20:17; Róòmù 7:7; 13:9, 10.

  •   Téèyàn bá ń ta tẹ́tẹ́ lórí nǹkan kékeré pàápàá lè ru ìfẹ́ owó sókè lọ́kàn èèyàn.​—1 Tímótì 6:9, 10.

  •   Àwọn tó ń ta tẹ́tẹ́ máa ń gbára lé ìgbàgbọ́ nínú ohun àsán tàbí oríire. Àmọ́, Ọlọ́run ka irú àwọn ìwà bẹ́ẹ̀ sí ìbọ̀rìṣà, èyí sì ta ko ìjọsìn mímọ́ rẹ̀.​—Aísáyà 65:11.

  •   Dípò téèyàn á fi máa ronú a ti jèrè nǹkan lái ṣiṣẹ́ fún-un, Bíbélì gbà wá níyànjú pé ká ṣiṣẹ́ àṣekára. (Oníwàásù 2:24; Éfésù 4:28) Gbogbo àwọn tó bá tẹ̀ lé ìlànà Bíbélì yìí lè “jẹ oúnjẹ tí àwọn fúnra wọn ṣiṣẹ́ fún.”​—2 Tẹsalóníkà 3:10, 12.

  •   Tẹ́tẹ́ títa lè ru ẹ̀mí ìdíje sókè, Bíbélì sì dẹ́bi fún èyí.​—Galatians 5:26.

a Bíbélì dìídì mẹ́nu kan tẹ́tẹ́ títa nígbà tó ń sọ̀rọ̀ nípa bí àwọn ọmọ ogun Róòmù ṣe ṣẹ́ “kèké,” tàbí ta tẹ́tẹ́ nígbà tí wọ́n fẹ́ pín aṣọ Jésù.​—Mátíù 27:35; Jòhánù 19:23, 24.