Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

ÀLÀYÉ ÀWỌN ẸSẸ BÍBÉLÌ

Ìṣe 1:8—“Ẹ̀yin Yóò Gba Agbára”

Ìṣe 1:8—“Ẹ̀yin Yóò Gba Agbára”

 “Ẹ ó gba agbára nígbà tí ẹ̀mí mímọ́ bá bà lé yín, ẹ ó sì jẹ́ ẹlẹ́rìí mi ní Jerúsálẹ́mù, ní gbogbo Jùdíà àti Samáríà àti títí dé ibi tó jìnnà jù lọ ní ayé.”​—Ìṣe 1:8, Ìtumọ̀ Ayé Tuntun.

 “Ẹ̀yin yóò gba agbára, nígbà tí Ẹ̀mí Mímọ́ bá bà lé e yín: ẹ̀yin yóò sì máa ṣe ẹlẹ́rìí mi ni Jerusalẹmu, àti ní gbogbo Judea, àti ní Samaria, àti títí dé òpin ilẹ̀ ayé.”​—Ìṣe 1:8, Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní.

Ìtumọ̀ Ìṣe 1:8

 Jésù ṣèlérí fáwọn ọmọlẹ́yìn ẹ̀ pé ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run máa fún wọn lágbára láti wàásù dé ibi tó jìnnà jù lọ ní ayé.

 “Ẹ ó gba agbára nígbà tí ẹ̀mí mímọ́ bá bà lé yín.” Jésù ti ṣèlérí fáwọn ọmọlẹ́yìn ẹ̀ tẹ́lẹ̀ pé wọ́n máa gba ẹ̀mí mímọ́ a lẹ́yìn tóun bá pa dà sí ọ̀run. Ó wá tún ìlérí náà ṣe fún wọn. (Jòhánù 14:16, 26) Ọjọ́ mẹ́wàá lẹ́yìn tí Jésù pa dà sọ́run lọ́dún 33 Sànmánì Kristẹni, àwọn ọmọlẹ́yìn náà gba ẹ̀mí mímọ́ tó ṣèlérí. (Ìṣe 2:1-4) Ẹ̀mí mímọ́ yìí mú kó ṣeé ṣe fún wọn láti sọ̀rọ̀ ní onírúurú èdè, kí wọ́n sì ṣe ọ̀pọ̀lọpọ̀ iṣẹ́ ìyanu. Kò tán síbẹ̀ o, ó tún mú kó ṣeé ṣe fún wọn láti fìgboyà wàásù nípa Jésù.​—Ìṣe 3:1-8; 4:33; 6:8-10; 14:3, 8-10.

 “Ẹ ó sì jẹ́ ẹlẹ́rìí mi.” Ọ̀rọ̀ tí wọ́n lò fún “ẹlẹ́rìí” túmọ̀ sí “ẹni tó ń jẹ́rìí nípa nǹkan tó ṣojú ẹ̀ tàbí tó mọ̀ nípa ẹ̀.” Àwọn àpọ́sítélì lè jẹ́rìí sí ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà tí Jésù ń ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ ẹ̀, nígbà tó kú àti nígbà tó jíǹde torí àwọn nǹkan yìí ṣojú wọn. (Ìṣe 2:32; 3:15; 5:32; 10:39) Bí wọ́n ṣe fìgboyà sọ ohun tó ṣojú wọn yìí ló mú káwọn èèyàn gbà pé Jésù ni Kristi, ìyẹn Mèsáyà tí Ọlọ́run ṣèlérí. (Ìṣe 2:32-36, 41) Àwọn kan gba àwọn àpọ́sítélì náà gbọ́, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í jẹ́rìí nípa Jésù. Wọ́n wá ń wàásù nípa ìgbésí ayé Jésù, ikú rẹ̀ àti àjíǹde ẹ̀ fáwọn èèyàn.​—Ìṣe 17:2, 3; 18:5.

 “Títí dé ibi tó jìnnà jù lọ ní ayé.” Ọ̀rọ̀ yìí tún lè túmọ̀ sí “títí dé òpin ilẹ̀ ayé” tàbí “títí dé àwọn orílẹ̀-èdè míì.” Ọ̀rọ̀ Jésù yìí jẹ́ ká rí ibi táwọn ọmọlẹ́yìn ẹ̀ máa wàásù dé. Wọ́n máa wàásù láwọn agbègbè míì tó jìnnà gan-an sí Jùdíà àti Samáríà. Kódà, wọ́n á wàásù dé àwọn agbègbè tí Jésù ò dé. Àwọn tí wọ́n á sì wàásù fún máa pọ̀ gan-an ju àwọn tí Jésù wàásù fún lọ. (Mátíù 28:19; Jòhánù 14:12) Kò tó ọgbọ̀n (30) ọdún lẹ́yìn tí Jésù sọ̀rọ̀ yìí ni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé a ti wàásù ìhìn rere nípa Jésù “láàárín gbogbo ẹ̀dá tó wà lábẹ́ ọ̀run.” Kódà, ìwàásù náà ti dé àwọn ibi tó jìnnà bíi Róòmù, Pátíà (ìyẹn gúúsù Òkun Caspian) àti àríwá ilẹ̀ Áfíríkà.​—Kólósè 1:23; Ìṣe 2:5, 9-11.

Àwọn Ẹsẹ Tó Ṣáájú Àtèyí Tó Tẹ̀ Lé Ìṣe 1:8

 Ibi tí ìwé Lúùkù parí sí ni ìwé Ìṣe ti bẹ̀rẹ̀. (Lúùkù 24:44-49; Ìṣe 1:4, 5) Lúùkù ló kọ ìwé yìí, ó sì ṣàlàyé ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà tí Jésù fara han àwọn ọmọlẹ́yìn ẹ̀ lẹ́yìn tó jíǹde. (Ìṣe 1:1-3) Ẹ̀yìn ìyẹn ló wá ṣàlàyé bí ìjọ Kristẹni ṣe bẹ̀rẹ̀ àti bó ṣe gbòòrò láti ọdún 33 sí nǹkan bí ọdún 61 Sànmánì Kristẹni.​—Ìṣe 11:26.

 Àwọn ẹsẹ tó ṣáájú Ìṣe 1:8 fi hàn pé àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù rò pé Jésù máa di Ọba Ìjọba Ọlọ́run lákòókò yẹn. (Ìṣe 1:6) Jésù wá sọ fún wọn pé kí wọ́n má ṣe da ara wọn láàmú nípa ìgbà tí Ìjọba náà máa bẹ̀rẹ̀. (Ìṣe 1:7) Kàkà bẹ́ẹ̀, bí wọ́n ṣe máa wàásù nípa Jésù “títí dé ibi tó jìnnà jù lọ ní ayé” ló yẹ kí wọ́n gbájú mọ́. (Ìṣe 1:8) Ohun táwa Kristẹni tòótọ́ sì ń ṣe lónìí nìyẹn, à ń fìtara wàásù ìròyìn ayọ̀ nípa Ìjọba Ọlọ́run fáwọn èèyàn.​—Mátíù 24:14.

 Wo fídíò yìí kó o lè mọ ohun tó wà nínú ìwé Ìṣe.

a Ẹ̀mí mímọ́ ni agbára tí Ọlọ́run fi ń ṣiṣẹ́. (Jẹ́nẹ́sísì 1:2) Tó o bá fẹ́ mọ̀ sí i, ka àpilẹ̀kọ náà “Kí Ni Ẹ̀mí Mímọ́?