Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ohun Tó O Lè Ṣe Kí Àrùn Corona Má Bàa Jẹ́ Kí Nǹkan Tojú Sú Ẹ

Ohun Tó O Lè Ṣe Kí Àrùn Corona Má Bàa Jẹ́ Kí Nǹkan Tojú Sú Ẹ

 Ṣé bí àrùn Corona ṣe ń dẹ́rù ikú bani yìí ti jẹ́ kí gbogbo nǹkan tojú sú ẹ? Tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, mọ̀ pé bó ṣe rí fún ọ̀pọ̀ èèyàn náà nìyẹn. Láti ọ̀pọ̀ oṣù sẹ́yìn ni ọ̀pọ̀ èèyàn kárí ayé ti ń gbé nínú ìbẹ̀rù torí àrùn tó ń dẹ́rù ikú bani yìí. Dókítà Hans Kluge, tó jẹ́ Olùdarí Ẹ̀ka Yúróòpù fún Àjọ Ìlera Àgbáyé sọ pé ọ̀pọ̀ èèyàn “ti fi ọ̀pọ̀ nǹkan du ara wọn kí wọ́n lè fòpin sí bí àrùn Corona ṣe ń tàn kálẹ̀. Lẹ́yìn èyí, ó rọrùn ó sì bá ìwà ẹ̀dá mu pé kí wọ́n má rí ti àrun náà rò mọ́, kí wọ́n má kà á sí mọ́, kí agara sì dá wọn.”

 Tó bá jẹ́ pé àrùn yìí ti jẹ́ kí nǹkan tojú sú ìwọ náà, ṣe ni kó o mọ́kàn le. Bíbélì ń ran ọ̀pọ̀ èèyàn lọ́wọ́ kí wọ́n lè fara dà á lákòókò tí nǹkan ò rọgbọ yìí. Ó lè ran ìwọ náà lọ́wọ́.

 Báwo ni àrùn ṣe ń jẹ́ kí nǹkan tojú súni?

 Ti pé nǹkan tojú sú ẹ torí àrùn tó ń gbẹ̀mí àwọn èèyàn kò túmọ̀ sí pé o ṣàìsàn, ṣe ló wulẹ̀ jẹ́ bí nǹkan ṣe ń rí lára àwọn èèyàn tó bá ti pẹ́ tí àrùn kan ti ń jà, tó ti yí ọ̀pọ̀ nǹkan pa dà, tí wọn ò sì mọ ibi tó máa já sí. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé bó ṣe rí lára olúkúlùkù lè yàtọ̀ síra, lára àmì tá a sábà fi ń mọ̀ pé àrùn ti dáni lágara rèé:

  •   Kí nǹkan kan má wu èèyàn ṣe

  •   Àìjẹun àti àìsùn bíi ti tẹ́lẹ̀ mọ́

  •   Ìkanra

  •   Kí iṣẹ́ téèyàn ti ń ṣe dáadáa tẹ́lẹ̀ máa ṣòroó ṣe

  •   Àìlè-pọkàn-pọ̀

  •   Ó lè máa ṣe èèyàn bíi pé nǹkan ò lè dáa mọ́

 Kí nìdí tó fi léwu kí àrùn jẹ́ kí nǹkan tojú súni?

 Tá a bá jẹ́ kí àrùn mú kí nǹkan tojú sú wa, ó léwu fún wa ó sì tún léwu fún àwọn míì. Tá ò bá wá nǹkan ṣe sí i, ó lè má wù wá mọ́ láti ṣe ohun tó yẹ ká ṣe láti dáàbò bo ara wa lọ́wọ́ àrùn COVID-19. Tó bá yá, a lè má bìkítà mọ̀ nípa ewu tó wà nínú àrùn náà, bó tiẹ̀ jẹ́ pé ó ṣì ń tàn kálẹ̀ tó sì ń pa àwọn èèyàn. Tó bá ti wá sú wa torí pé àrùn náà ò jẹ́ ká lè ṣe ọ̀pọ̀ nǹkan, ó lè máa wù wá láti ní òmìnira púpọ̀ sí i, ìyẹn sì lè wu àwa àtàwọn míì léwu.

 Ní àkókò tí nǹkan ò fara rọ yìí, ọ̀pọ̀ ti wá ń rí i pé òótọ́ ni ohun tí Bíbélì sọ pé: “Tí o bá rẹ̀wẹ̀sì ní ọjọ́ wàhálà, agbára rẹ ò ní tó nǹkan.” (Òwe 24:10) Bíbélì fún wa ní àwọn ìlànà tá a fi lè mọ bá ó ṣe kojú àwọn ipò tó ń múni rẹ̀wẹ̀sí, tó fi mọ́ ti àrùn COVID-19 yìí.

 Àwọn ìlànà Bíbélì wo ni ò ní jẹ́ kí àrùn mú kí nǹkan tojú sú ẹ?

  •   Má ṣe sún mọ́ àwọn èèyàn, ṣùgbọ́n máà sá fún wọn

     Ohun tí Bíbélì sọ: “Ọ̀rẹ́ tòótọ́ . . . [ni] a bí fún ìgbà wàhálà.”​—Òwe 17:17.

     Ìdí tó fi ṣe pàtàkì: Àwọn ọ̀rẹ́ tòótọ́ máa ń gbéni ró. (1 Tẹsalóníkà 5:11) Ṣùgbọ́n, tó bá pẹ́ tá a ti ya ara wa sọ́tọ̀, ó lè ṣàkóbá fún ìlera wa.​—Òwe 18:1.

     Gbìyànjú èyí wò: Máa fi fídíò orí Íńtánẹ́ẹ̀tì bá àwọn ọ̀rẹ́ rẹ sọ̀rọ̀, máa pè wọ́n sórí fóònù, máa kọ lẹ́tà orí kọ̀ǹpútà sí wọn, kó o sì máa tẹ àtẹ̀jíṣẹ́. Ti ohun kan bá ń bà ẹ́ lọ́kàn jẹ́, sọ fáwọn ọ̀rẹ́ rẹ, kíwọ náà sì máa béèrè àlàáfíà wọn déédéé. Ẹ bára yín sọ̀rọ̀ nípa bẹ́ ẹ ṣe ń kojú àrùn COVID-19 yìí. Wá bó o ṣe lè ṣe nǹkan tó máa ran ọ̀rẹ́ rẹ lọ́wọ́, inú ẹ̀yin méjèèjì á sì dùn.

  •   Lo àkókò rẹ lọ́nà tó dára jù lọ

     Ohun tí Bíbélì sọ: “Ẹ máa lo àkókò yín lọ́nà tó dára jù lọ.”​—Éfésù 5:16.

     Ìdí tó fi ṣe pàtàkì: Tó o bá ń lo àkókò rẹ lọ́nà tó dára, o ò ní máa ro èròkerò, o ò sì ní máa ṣàníyàn jù.​—Lúùkù 12:25.

     Gbìyànjú èyí wò: Dípò tí wàá fi máa ronú lórí ohun tó ò lè ṣe mọ́, wá bó o ṣe lè fi àkókò yìí ṣe ohun tó dáa. Bí àpẹẹrẹ, ṣé àwọn iṣẹ́ kan wà tó o lè ṣe báyìí àbí ó ní irú àwọn eré àfipawọ́ kan tó o lè máa ṣe? Ṣé o lè máa lo àkókò púpọ̀ sí i láti bójú tó ìdílé rẹ?

  •   Ní ìtòlẹ́sẹẹsẹ tí wàá máa tẹ̀ lé

     Ohun tí Bíbélì sọ: “Ẹ jẹ́ kí ohun gbogbo máa ṣẹlẹ̀ . . . létòlétò.”​—1 Kọ́ríńtì 14:40.

     Ìdí tó fi ṣe pàtàkì: Ara ọ̀pọ̀ èèyàn máa ń balẹ̀ dáadáa wọ́n sì máa ń láyọ̀ tí wọ́n bá ní ohun tí wọ́n ń ṣe déédéé.

     Gbìyànjú èyí wò: Ṣe ìtòlẹ́sẹẹsẹ tó bá ipò tó o wà báyìí mu. Ya àkókò pàtó sọ́tọ̀ fún iṣẹ́ iléèwé, iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ àti àwọn iṣẹ́ pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́ nínú ilé, kó o sì tún ní ìgbà tí ìdílé rẹ a fi máa kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Kó o tún wá àkókò fún àwọn ìgbòkègbodò míì tó ṣàǹfààní, irú bíi bíbójú tó ìdílé rẹ, jíjáde lọ àti ṣíṣe eré ìdárayá. Máa ṣe àtúnyẹ̀wò ìtòlẹ́sẹẹsẹ rẹ déédéé, kó o sì máa ṣe àtúnṣe tó bá yẹ sí i.

  •   Ṣètò tó bá bí ojú ọjọ́ ṣe rí mu

     Ohun tí Bíbélì sọ: “Ọlọ́gbọ́n rí ewu, ó sì fara pa mọ́.”​—Òwe 22:3.

     Ìdí tó fi ṣe pàtàkì: Bó tilẹ̀ jẹ́ pé atẹ́gùn máa jẹ́ kára tù ẹ́, tí oòrùn sì máa fún ara rẹ lókun, bí ojú ọjọ́ ṣe ń yí pa dà níbi tó ò ń gbé lè máà jẹ́ kó o gbádùn wọn tó bó ṣe yẹ.

     Gbìyànjú èyí wò: Bí ìgbà òtútù bá ń bọ̀, gbìyànjú láti tún pálọ̀ rẹ tàbí ibi tó o ti ń ṣiṣẹ́ tò kí oòrùn lè túbọ̀ wọlé síbẹ̀. Ṣètò ibi tó o lè jáde lọ bó tilẹ̀ jẹ́ pé ojú ọjọ́ á tutù. Tó bá ṣeé ṣe, ra aṣọ òtútù tó máa jẹ́ kó o lè dúró pẹ́ níta.

     Bí ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn bá ń bọ̀, ọ̀pọ̀ èèyàn á dà síta, torí náà sọ́ra ṣe o. Ṣètò ibi tó o máa lọ, kó o sì lọ ní àkókò tí èrò ò ní pọ̀ níbẹ̀.

  •   Máa ṣe ohun tí ò ní jẹ́ kó o kó àrùn Corona

     Ohun tí Bíbélì sọ: “Òmùgọ̀ kì í kíyè sára, ó sì máa ń dá ara rẹ̀ lójú jù.”​—Òwe 14:16.

     Ìdí tó fi ṣe pàtàkì: Àrùn tó ń pani ni Corona, ó sì lè ràn wá tá ò bá kíyè sára nítorí ẹ̀ mọ́.

     Gbìyànjú èyí wò: Máa ṣàyẹ̀wò àwọn ìtọ́ni tó ṣeé gbára lé tí ìjọba bá pèsè kó o sì máa bi ará rẹ bóyá o ṣì ń kíyè sára. Bí ohun tó ò ń ṣe ṣe máa kan ìwọ, ìdílé rẹ̀ àti àwọn míì ni kó o máa rò.

  •   Túbọ̀ sún mọ́ Ọlọ́run

     Ohun tí Bíbélì sọ: “Ẹ sún mọ́ Ọlọ́run, á sì sún mọ́ yín.”​—Jémíìsì 4:8.

     Ìdí tó fi ṣe pàtàkì: Ọlọ́run lè mú kó o kojú ìpèníjà èyíkéyìí.​—Àìsáyà 41:13.

     Gbìyànjú èyí wò: Máa ka Bíbélì, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, lójoojúmọ́. O tiẹ̀ lè tẹ̀ lé ètò Bíbélì kíkà yìí, ó máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ gan-an.

 O ò ṣe kàn sí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kó o lè kẹ́kọ̀ọ́ bí wàá ṣe jàǹfààní látinú ètò tí wọ́n ti ṣe láti máa pàdé pọ̀ nìṣó bó tilẹ̀ jẹ́ pé àrùn Cororna ṣì wà lóde? Bí àpẹẹrẹ, wọ́n ti ń lo fídíò orí Íńtánẹ́ẹ̀tì kárí ayé báyìí láti ṣe àwọn ìpàdé ìjọ, ìrántí ikú Kristi àti àpéjọ ọdọọdún.

 Àwọn ẹsẹ Bíbélì tó máa ràn ẹ́ lọ́wọ́

 Àìsáyà 30:15: “Ẹ máa lágbára tí ẹ bá fara balẹ̀, tí ẹ sì gbẹ́kẹ̀ lé mi.”

 Ìtumọ̀: Tá a bá tẹ̀ lé ìmọ̀ràn tí Ọlọ́run fún wa, áá jẹ́ ká lè fara balẹ̀ ní àkókò tí nǹkan bá le koko.

 Òwe 15:15: “Búburú ni gbogbo ọjọ́ ẹni tí ìyà ń jẹ, àmọ́ ẹni tí inú rẹ̀ ń dùn máa ń jẹ àsè nígbà gbogbo.”

 Ìtumọ̀: Tá a bá ń ronú lórí ohun tó dáa, á jẹ́ ká láyọ̀ bí nǹkan bá tiẹ̀ le koko.

 Òwe 14:15: “Aláìmọ̀kan máa ń gba gbogbo ọ̀rọ̀ gbọ́, àmọ́ aláròjinlẹ̀ máa ń ronú lórí ìgbésẹ̀ kọ̀ọ̀kan.”

 Ìtumọ̀: Máa tẹ̀ lé ìtọ́ni tí ò ní jẹ́ kó o kó àrùn, má sì tètè fọwọ́ yẹpẹrẹ mú irú ìtọ́ni bẹ́ẹ̀.

 Àìsáyà 33:24: “Kò sí ẹnì kankan tó ń gbé ibẹ̀ tó máa sọ pé: ‘Ara mi ò yá.’”

 Ìtumọ̀: Ọlọ́run ṣèlérí pé òun máa mú gbogbo àìsàn kúrò.