Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÌBÉÈRÈ 2

Ṣó Yẹ Kí N Máa Da Ara Mi Láàmú Torí Bí Mo Ṣe Rí?

Ṣó Yẹ Kí N Máa Da Ara Mi Láàmú Torí Bí Mo Ṣe Rí?

ÌDÍ TỌ́RỌ̀ YÌÍ FI ṢE PÀTÀKÌ

Àwọn ohun kan wà tó ṣe pàtàkì ju ìrísí lọ.

LO MÁA ṢE?

Fojú inú wo ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí: Nígbà tí Julia ń wo ara rẹ̀ nínú dígí, ó bẹ̀rẹ̀ sí í ronú pé òun ti sanra jù, ó wá ń sọ lọkàn ara ẹ̀ pé. “Mo ti ń sanra jù o, ó yẹ kí n wá nǹkan ṣe sí i,” bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn òbí ẹ̀ àtàwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ máa ń sọ fún un pé “lẹ̀pa” ni.

Julia tiẹ̀ ti ń rò ó tẹ́lẹ̀ pé ohun tó bá gbà lòun máa fún un, ó kéré tán òun máa dín ohun tó tó “ìwọ̀n kìlógíráàmù méjì” kù lára òun. Ńṣe lá wá bẹ̀rẹ̀ sí í febi pa ara ẹ̀ . . .

Tó bá ń ṣe ẹ́ bíi ti Julia, kí lo máa ṣe?

RÒ Ó WÒ NÁ!

Ó dà bí ìgbà tó ò ń wo ara ẹ nínú dígí tí kò dáa, o lè máà rí bó o ṣe rò pé o rí

Kò sóhun tó burú nínú kéèyàn máa jẹ́ kí ìrísí òun jẹ òun lọ́kàn. Bíbélì tiẹ̀ sọ̀rọ̀ àwọn èèyàn kan tó dáa ní ìrísí, àwọn bíi Sárà, Rákélì, Ábígẹ́lì, Jósẹ́fù àti Dáfídì. Bíbélì sọ pé obìnrin kan tó ń jẹ́ Ábíṣágì “lẹ́wà dé góńgó.”​—1 Ọba 1:⁠4.

Àmọ́ ṣá o, ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́ ló ti jẹ́ kí ìrísí wọn gbà wọ́n lọ́kàn ju bó ṣe yẹ lọ. Èyí sì lè mú kí wọ́n níṣòro tó le gan-an. Bí àpẹẹrẹ:

  • Ìwádìí kan fi hàn pé nǹkan bí ọ̀dọ́bìnrin mẹ́fà nínú mẹ́wàá ló máa ń sọ pé àwọn ti sanra jù, nígbà tó sì jẹ́ pé méjì nínú wọn ló sanra jù lóòótọ́.

  • Ìwádìí míì fi hàn pé àwọn obìnrin bíi márùn-ún nínú mẹ́wàá ló máa ń sọ pé àwọn ti sanra jù, nígbà tó sì jẹ́ pé wọn ò sanra rárá.

  • Torí kí àwọn ọ̀dọ́ kan lè dín bí wọ́n ṣe sanra kù, wọ́n máa ń febi pa ara wọn, ìyẹn sì ti mú kí wọ́n ní àìsàn kan tí kì í jẹ́ kí oúnjẹ wu èèyàn jẹ, tó sì lè gbẹ̀mí ẹni.

Tó o bá ti ń kíyè sí i pé o kì í jẹun kánú, àfi kó o wá ẹni tó máa ràn ẹ́ lọ́wọ́. Ó máa dáa kó o sọ fún òbí ẹ tàbí ẹnì kan tó o lè fọ̀rọ̀ lọ̀, kí wọ́n lè ràn ẹ́ lọ́wọ́. Bíbélì sọ pé: “Alábàákẹ́gbẹ́ tòótọ́ a máa nífẹ̀ẹ́ ẹni ní gbogbo ìgbà, ó sì jẹ́ arákùnrin tí a bí fún ìgbà tí wàhálà bá wà.”​—Òwe 17:⁠17.

ÀTÚNṢE TÓ YẸ KÓ O ṢE!

Irú ẹni tá a jẹ́ nínú lọ́hùn-ún ló máa pinnu bóyá ìrísí wa fani mọ́ra tàbí kò fani mọ́ra. Gbọ́ ohun tí Bíbélì sọ nípa Ábúsálómù ọmọ Dáfídì Ọba. Ó ní:

“Kò sí ọkùnrin kankan tí ó lẹ́wà bí Ábúsálómù tí ó yẹ fún ìyìn. . . . Kò sí àbùkù kankan lára rẹ̀.”​—2 Sámúẹ́lì 14:⁠25.

Àmọ́, ọ̀dọ́kùnrin yìí ní ìgbéraga, ó ń wá ipò ọlá, ọ̀dàlẹ̀ sì ni. Ìdí nìyẹn tí Bíbélì ò fi sọ̀rọ̀ Ábúsálómù dáadáa, ṣe ló jẹ́ ká mọ̀ pé apààyàn àti ọ̀dàlẹ̀ tí kò nítìjú ni.

Ìdí nìyẹn tí Bíbélì fi gbà wá nímọ̀ràn yìí:

“Ẹ fi àkópọ̀ ìwà tuntun wọ ara yín láṣọ.”​—Kólósè 3:⁠10.

“Kí ọ̀ṣọ́ yín má sì jẹ́ ti irun dídì lóde ara . . . , ṣùgbọ́n kí ó jẹ́ ẹni ìkọ̀kọ̀ ti ọkàn-àyà.”​—1 Pétérù 3:​3, 4.

Mọ̀ pé kò sóhun tó burú nínú kó máa wu ẹnì kan pé kóun ní ìrísí tó dáa, àmọ́ má gbàgbé pé ìwà ẹ ló ṣe pàtàkì jù. Tó bá yá, ohun tó máa mú káwọn èèyàn túbọ̀ sún mọ́ ẹ ni àwọn ànímọ́ rere tó o ní, kì í ṣe ìrísí rẹ. Ọ̀dọ́bìnrin kan tó ń jẹ́ Phylicia sọ pé, “Ẹwà máa ń tètè jọ èèyàn lójú, àmọ́, irú ẹni tó o jẹ́ nínú lọ́hùn-ún àtàwọn ànímọ́ rere tó o ní làwọn èèyàn á máa rántí jù lọ.”

ṢÀYẸ̀WÒ ÌRÍSÍ RẸ

Ṣé gbogbo ìgbà ni inú ẹ máa ń bàjẹ́ torí bó o ṣe rí?

Ṣó o ti rò ó rí pé wàá lọ ṣe iṣẹ́ abẹ kó o lè lẹ́wà sí i tàbí pé wàá máa febi pa ara ẹ kó o má bàa sanra?

Tó bá ṣeé ṣe, kí ló wù ẹ́ pé kó o yí pa dà nípa ìrísí rẹ? (Mú èyí tó o fẹ́.)

  • BÍ MO ṢE GA SÍ

  • BÍ MỌ ṢE TẸ̀WỌ̀N TÓ

  • IRUN MI

  • BÍ ÁRA MI ṢE RÍ

  • BÍ OJÚ MI ṢE RÍ

  • ÀWỌ̀ MI

Tó bá jẹ́ pé bẹ́ẹ̀ ni lo dáhùn sáwọn ìbéèrè méjì àkọ́kọ́, tó o sì mú nǹkan mẹ́ta tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ ní ìbéèrè kẹta, ohun kan wà tó yẹ kó o fi sọ́kàn: Ó ṣeé ṣe kó máà jẹ́ pé ojú tó o fi ń wo ara ẹ yẹn làwọn èèyàn fi ń wò ẹ́. Ó rọrùn gan-an láti máa ronú ju bó ṣe yẹ lọ nípa ìrísí ẹ, ó sì rọrùn láti ní in lọ́kàn pé ohun tó bá gbà ni wàá fún un.​—1 Sámúẹ́lì 16:⁠7.