Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Kí Ló Lè Mú Kí Ìdílé Láyọ̀?

Kí Ló Lè Mú Kí Ìdílé Láyọ̀?

Ṣé o rò pé . . .

  • ìfẹ́ ni?

  • àbí owó?

  • àbí nǹkan míì?

OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ

“Aláyọ̀ ni àwọn tó ń gbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, tí wọ́n sì ń pa á mọ́!”​—Lúùkù 11:28, Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun.

ÀǸFÀÀNÍ TÓ O MÁA RÍ

Wàá rí ìfẹ́ tòótọ́.​—Éfésù 5:​28, 29.

Wàá gbádùn ọ̀wọ̀ tó jinlẹ̀.​—Éfésù 5:33.

Ọkàn rẹ á balẹ̀ pẹ̀sẹ̀.​—Máàkù 10:​6-9.

ṢÉ A LÈ GBA OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ GBỌ́?

Bẹ́ẹ̀ ni. Méjì lára ìdí tó fi yẹ ká gba ọ̀rọ̀ Bíbélì gbọ́ rèé:

  • Ọlọ́run ló dá ìdílé sílẹ̀. Bíbélì sọ pé ọ̀dọ̀ Jèhófà Ọlọ́run ni “gbogbo ìdílé . . . ti gba orúkọ rẹ̀.” (Éfésù 3:14, 15) Ìyẹn túmọ̀ sí pé Jèhófà ló dá ìdílé sílẹ̀. Ẹ̀kọ́ wo nìyẹn kọ́ wa?

    Rò ó wò ná: Tó o bá ń jẹ oúnjẹ aládùn kan, tó o sì fẹ́ mọ ohun tí wọ́n fi sè é, ọwọ́ ta ló yẹ kó o ti béèrè? Ṣebí ọwọ́ ẹni tó sè é ni?

    Bákan náà, tá a bá fẹ́ mọ àwọn ohun tó máa mú kí ayọ̀ wà nínú ìdílé, ọ̀dọ̀ Jèhófà ló yẹ ká yíjú sí, torí pé òun ló dá ìdílé sílẹ̀.​—Jẹ́nẹ́sísì 2:18-24.

  • Ọ̀rọ̀ wa jẹ Ọlọ́run lógún. Àwọn ìdílé tó bá jẹ́ ọlọgbọ́n máa ń tẹ̀ lé àwọn ìmọ̀ràn tí Jèhófà ń fún wa nínú Ọ̀rọ̀ rẹ̀. ‘Nítorí ó ń bójú tó wa.’ (1 Pétérù 5:6, 7) Ohun tó dáa ni Jèhófà ń fẹ́ fún wa, àwọn ìmọ̀ràn rẹ̀ sì máa ń wúlò nígbà gbogbo!​—Òwe 3:5, 6; Àìsáyà 48:17, 18.

RÒ Ó WÒ NÁ

Báwo lo ṣe lè jẹ́ ọkọ rere, aya rere tàbí òbí rere?

Bíbélì dáhùn ìbéèrè yìí nínú ìwé ÉFÉSÙ 5:1, 2 àti KÓLÓSÈ 3:18-21.