Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwọn ará wa ò yéé sin Jèhófà bí wọ́n tiẹ̀ ń ba àwọn ohun ìní wọn jẹ́

JỌ́JÍÀIA | 1998-2006

Wọ́n Ń Sin Jèhófà, Bí Ọ̀tá Tiẹ̀ Ń Gbógun

Wọ́n Ń Sin Jèhófà, Bí Ọ̀tá Tiẹ̀ Ń Gbógun

Àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa ò juwọ́ sílẹ̀, wọ́n ń pàdé pọ̀ déédéé. Àwọn alàgbà dá ọgbọ́n tí wọ́n á fi lè máa dáàbò bo àwọn akéde. Arákùnrin André Carbonneau, ọmọ ilẹ̀ Kánádà tó jẹ́ agbẹjọ́rò, gbèjà àwọn ará wa láwọn ọdún yẹn. Ó sọ pé: “Arákùnrin kan máa dúró sí tòsí ibi tí àwọn ará ti ń ṣèpàdé, á sì mú fóònù dání. Tó bá rí i pé àwọn jàǹdùkú ń bọ̀, ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ló máa pe àwọn alàgbà kó lè kìlọ̀ fún wọn pé ewu ti ń bọ̀.”

Àwọn jàǹdùkú dáná sun ilé tí ìdílé Shamoyan ń gbé (lápá òsì) àti ibì kan táwọn ará ti ń kówèé (lápá ọ̀tún)

Ní gbogbo ìgbà tí wàhálà bá ti ṣẹlẹ̀, àwọn aṣojú méjì láti ẹ̀ka ọ́fíìsì máa ń bẹ àwọn ará wò kí wọ́n lè gbé wọn ró. André sọ pé, “Ó máa ń wúni lórí pé táwọn aṣojú ẹ̀ka ọ́fíìsì bá dé ibi táwọn ará kóra jọ sí, wọ́n máa ń rí i pé ṣe ni inú àwọn ará ń dùn, tí wọ́n sì ń rẹ́rìn-ín.”

Àwọn alátakò ń yọ àwọn ará lẹ́nu nílé ẹjọ́ àti ní ìgboro

Ohun kan náà làwọn tọ́rọ̀ yìí ò fi bẹ́ẹ̀ kàn pinnu láti ṣe, títí kan àwọn tó ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. André rántí obìnrin kan tó ti fẹ́rẹ̀ẹ́ di akéde tí kò tíì ṣèrìbọmi tí wọ́n jọ sọ̀rọ̀ nígbà yẹn. Obìnrin náà sọ fún un pé, “Nígbà tí mo wo ohun táwọn jàǹdùkú yẹn ń ṣe lórí tẹlifíṣọ̀n, mo rí ohun táwọn Kristẹni tòótọ́ fi yàtọ̀ sáwọn èké Kristẹni, Kristẹni tòótọ́ sì ni mo fẹ́ jẹ́ ní tèmi.”

Wọ́n Fìgboyà Gbèjà Àwọn Ará Bíi Tiwọn

Láwọn ọdún tí nǹkan le yẹn, bí àwọn akéde ṣe tẹra mọ́ iṣẹ́ ìwàásù fi hàn pé ìgbàgbọ́ wọn lágbára, wọ́n sì nígboyà. Irú ìgbàgbọ́ táwọn ará tó ń gbèjà àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wọn nílé ẹjọ́ náà ní nìyẹn.

Ṣe làwọn oníròyìn ń ba àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lórúkọ jẹ́ káàkiri pé wọ́n máa ń tú ìdílé ká, wọn kì í gba ìtọ́jú ilé ìwòsàn, wọ́n sì máa ń ta ko ìjọba. Ohun tó léwu làwọn agbẹjọ́rò tó ń gbèjà àwọn ará ń ṣe, torí iṣẹ́ wọn ni wọ́n fi ń ṣeré yẹn, orúkọ wọn sì lè bà jẹ́.

Àwọn arákùnrin tó nígboyà láti Ẹ̀ka Tó Ń Bójú Tó Ọ̀rọ̀ Òfin lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà gbèjà àwọn ará nílé ẹjọ́

John Burns, agbẹjọ́rò tó wá láti ẹ̀ka ọ́fíìsì orílẹ̀-èdè Kánádà ran àwọn ará ní Jọ́jíà lọ́wọ́ láwọn ọdún yẹn. Ó sọ pé: “Àwọn ará tó jẹ́ agbẹjọ́rò ní Jọ́jíà yọ̀ǹda ara wọn láti ṣèrànwọ́. Ẹ̀rù ò bà wọ́n láti lọ fara hàn nílé ẹjọ́ pé Ẹlẹ́rìí Jèhófà làwọn, bó tiẹ̀ jẹ́ pé iṣẹ́ lè bọ́ lọ́wọ́ wọn.” Àwọn Ẹlẹ́rìí tó nígboyà yìí lọ́wọ́ nínú “gbígbèjà àti fífi ìdí ìhìn rere múlẹ̀ lọ́nà òfin.”Fílí. 1:7.

Àwọn Ọmọ Ilẹ̀ Jọ́jíà Sọ Pé Àwọn Ò Fara Mọ́ Ìwà Ipá Náà

Ìwà ipá tí wọ́n ń hù sáwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà yìí ò dáwọ́ dúró. Torí náà, bẹ̀rẹ̀ láti January 8, 2001, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà bẹ̀rẹ̀ sí í pín ìwé kan fáwọn èèyàn pé kí wọ́n buwọ́ lù ú tí wọ́n bá fẹ́ kí ìjọba dáàbò bo àwọn aráàlú lọ́wọ́ àwọn jàǹdùkú, kí wọ́n sì pe àwọn tó ń lu àwọn tí ò mọwọ́ mẹsẹ̀ lẹ́jọ́.

Arákùnrin Burns ṣàlàyé ìdí tí wọ́n fi pín ìwé náà, ó ní: “A fẹ́ jẹ́ kó ṣe kedere pé ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ ilẹ̀ Jọ́jíà ni ò fara mọ́ ìwà ipá táwọn èèyàn ń hù sí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà àti pé àwùjọ àwọn agbawèrèmẹ́sìn mélòó kan ló wà nídìí ọ̀rọ̀ náà.”

Láàárín ọ̀sẹ̀ méjì péré, ẹgbẹ̀rún mẹ́tàléláàádóje ó lé ọgọ́rùn-ún mẹ́ta àti márùndínlọ́gọ́rin [133,375] èèyàn káàkiri Jọ́jíà, tí ọ̀pọ̀ nínú wọn jẹ́ onísìn Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì ló buwọ́ lu ìwé náà. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé wọ́n kó àwọn ìwé náà lọ sọ́dọ̀ Ààrẹ Shevardnadze, ìwà ipá náà ò dáwọ́ dúró. Ṣe làwọn agbawèrèmẹ́sìn náà dìídì dájú sọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà.

Ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè Jọ́jíà ló buwọ́ lùwé láti fi hàn pé àwọn ò fara mọ́ ìwà ipá táwọn èèyàn ń hù sáwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Àmọ́ Jèhófà ò fi àwọn èèyàn rẹ̀ silẹ̀, ó sì ń bù kún wọn. Gbogbo bí àwọn agbawèrèmẹ́sìn ṣe ń yọ àwọn èèyàn Ọlọ́run lẹ́nu ni Jèhófà ń fa àwọn olóòótọ́ ọkàn kúrò nínú ìsìn èké.

Ó Kúrò Nínú Ìsìn Èké

Ọjọ́ pẹ́ tí Babilina Kharatishvili ti ń lọ Ṣọ́ọ̀ṣì Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì ní Jọ́jíà, kò sì fọ̀rọ̀ ẹ̀sìn rẹ̀ ṣeré. Nígbà tó lé lọ́gbọ̀n [30] ọdún, ó máa ń lọ láti ìlú dé ìlú, abúlé dé abúlé, á máa kọ́ àwọn èèyàn nípa ìgbésí ayé táwọn ẹni mímọ́ gbé.

Àmọ́ Babilina fẹ́ mọ Ọlọ́run sí i. Torí náà, ó pinnu pé òun á máa lọ ilé ẹ̀kọ́ ìsìn ti Ṣọ́ọ̀ṣì Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì ní Jọ́jíà. Lọ́jọ́ kan, olórí ìsìn kan fi ìwé Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun han àwọn ọmọ kíláàsì rẹ̀, ó sì ní kí wọ́n lọ gba ìwé náà lọ́wọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ó sọ fún wọn pé, “Ìwé yìí máa kọ́ yín ní ọ̀pọ̀ nǹkan nínú Bíbélì.”

Àyà Babilina là gààrà. Kì í gbọ́rọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tẹ́lẹ̀, àmọ́ ìwé wọn ni olórí ìsìn ní kí wọ́n lọ gbà yìí! Ó sọ lọ́kàn ara ẹ̀ pé, ‘Tó bá jẹ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ló máa kọ́ mi nípa Ọlọ́run, kí ni mo wá ń ṣe níbí?’ Ojú ẹsẹ̀ ló lọ bá àwọn Ẹlẹ́rìí nílùú Poti, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.

Bí Babilina ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́ sí i látinú Bíbélì, ó bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe àwọn àtúnṣe pàtàkì nígbèésí ayé rẹ̀. Nígbà kan, ó sọ pé: “Nígbà tí mo fojú ara mi rí i nínú Bíbélì pé kò tọ́ ká máa jọ́sìn ère, mo jáwọ́ nínú gbogbo oríṣiríṣi ìbọ̀rìṣà. Ó dá mi lójú pé ohun tó tọ́ ni mo ṣe yẹn.” Babilina ti fẹ́rẹ̀ẹ́ pé ọgọ́rin [80] ọdún nígbà yẹn, síbẹ̀ ó pinnu pé òun máa di Ẹlẹ́rìí Jèhófà.

Babilina kọ́ Izabela ọmọ ọmọ rẹ̀ lẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́

Ó ṣeni láàánú pé lọ́dún 2001, Babilina bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàìsàn, ó sì ṣaláìsí kó tó ṣèrìbọmi. Àmọ́ nígbà tó yá, Izabela ọmọ ọmọ rẹ̀ ṣèrìbọmi, ó sì ń sin Jèhófà tọkàntọkàn.

Ó Fẹ́ Di Ajẹ́jẹ̀ẹ́ Ìnìkàngbé

Ẹni ọdún méjìdínlọ́gbọ̀n [28] ni Eliso Dzidzishvili nígbà tó pinnu pé òun fẹ́ di ajẹ́jẹ̀ẹ́ ìnìkàngbé. Torí pé kò sí ilé àwọn obìnrin tó jẹ́jẹ̀ẹ́ ìnìkàngbé ní tòsí ìlú ìbílẹ̀ rẹ̀, ìyẹn Tkibuli, ó kó lọ sílùú Tbilisi lọ́dún 2001. Ní gbogbo ìgbà tó fi ń wá àyè ní ilé àwọn ajẹ́jẹ̀ẹ́ ìnìkàngbé, ó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ àbọ̀ṣẹ́ kan, ìyẹn iṣẹ́ olùkọ́. Ọmọ arábìnrin kan tó ń jẹ́ Nunu wà lára àwọn ọmọ tó ń kọ́.

Eliso sọ pé: “A sábà máa ń sọ̀rọ̀ Bíbélì. Ìbínú ni mo fi máa ń gbèjà ìsìn Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì, àmọ́ ṣe ni Nunu máa ń fara balẹ̀ fi àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ hàn mí lọ́kọ̀ọ̀kan. Lọ́jọ́ kan, ó sọ pé òun máa ka ìwé Kí Ni Ọlọrun Ń Béèrè Lọ́wọ́ Wa? fún mi. Bá a ṣe ń ka àwọn ìpínrọ̀ tó wà níbẹ̀, tá a sì ń wo àwọn ẹsẹ Bíbélì tí wọ́n tọ́ka sí, mo rí i pé ó ta ko àṣẹ Ọlọ́run pé kéèyàn máa jọ́sìn ère.”

Nígbà tó yá, Eliso lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì àdúgbò wọn, ó sì béèrè àwọn ìbéèrè kan lọ́wọ́ àlùfáà ibẹ̀. Ohun tí àlùfáà náà sọ jẹ́ kó ṣe kedere pé àwọn ohun tí wọ́n ń kọ́ni ní ṣọ́ọ̀ṣì ò bá Bíbélì mu. (Máàkù 7:7, 8) Ó wá dá a lójú pé òun ti rí òtítọ́, torí náà, ojú ẹsẹ̀ ló bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́dọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, kò sì pẹ́ tó fi ṣèrìbọmi.

Eliso Dzidzishvili (lápá òsì) tó fẹ́ di ajẹ́jẹ̀ẹ́ ìnìkàngbé àti Nunu Kopaliani (lápá ọ̀tún)

Wọ́n Ń Kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba Láìfi Àtakò Pè

Ìgbà tó fi máa di ọdún 2001, àwọn ìjọ tó nílò ibi tó dáa tí wọ́n á ti máa jọ́sìn ti pọ̀ sí i. Nígbà tí wọ́n fojú bù ú, wọ́n rí i pé wọ́n á nílò tó àádọ́rin [70] Gbọ̀ngàn Ìjọba. Torí náà, wọ́n ṣètò bí wọ́n á ṣe máa kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba lórílẹ̀-èdè náà láìka àtakò táwọn èèyàn ń ṣe sí.Ẹ́sírà 3:3.

Kò pẹ́ tí àwùjọ tó ń kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba fi bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàtúnṣe sí ilé kan tí ọ̀pọ̀ ìjọ ní Tbilisi ń lò tẹ́lẹ̀. Ká tó ṣẹ́jú pẹ́, wọ́n ti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìkọ́lé méjì míì nílùú Tbilisi àti Chiatura, ní ìwọ̀ oòrùn Jọ́jíà.

Gbọ̀ngàn Ìjọba kan rèé tẹ́lẹ̀ nílùú Tbilisi (lápá òsì), àmọ́ wọ́n tún un kọ́ (lápá ọ̀tún)

Arákùnrin Tamazi Khutsishvili, tó wà lára àwọn tó ṣiṣẹ́ ìkọ́lé ní Chiatura sọ pé: “Àwa mẹ́ẹ̀ẹ́dógún [15] la máa ń ṣiṣẹ́ níbẹ̀ lójoojúmọ́. Kò pẹ́ tí gbogbo aráàlú fi mọ̀ pé à ń kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba tuntun. Àwọn ìgbà míì wà tá a máa ń gbọ́ pé àwọn alátakò wa fẹ́ wá ba Gbọ̀ngàn Ìjọba tá à ń kọ́ jẹ́.”

Pẹ̀lú báwọn èèyàn ṣe ń ṣàtakò yìí, báwo làwọn ará ṣe máa ṣe iṣẹ́ ìkọ́lé náà láṣeyọrí? Tamazi sọ pé: “À ń báṣẹ́ wa lọ, oṣù mẹ́ta la sì fi parí Gbọ̀ngàn Ìjọba náà. Àwọn alátakò ń halẹ̀ lóòótọ́, àmọ́ wọn ò yọjú síbẹ̀ lẹ́ẹ̀kan.” *

Ìtura tí Wọ́n Ń Retí Dé

Wọ́n mú àwọn agbawèrèmẹ́sìn tó jẹ́ onísìn Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì àti Vasili Mkalavishvili ọ̀gá wọn

Ní October 2003, wọ́n bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìkọ́lé kan nílùú Samtredia. Làwọn agbawèrèmẹ́sìn bá tún bẹ̀rẹ̀ sí í gbógun ti àwọn ará. Kò pẹ́ táwọn ará mọ ògiri ilé náà dókè, kódà sìmẹ́ǹtì tí wọ́n fi mọ ọ́n kò tíì gbẹ táwọn tó ń ṣàtakò fi dé, tí wọ́n sì wó o palẹ̀.

Àmọ́ ní November 2003, nǹkan yí pa dà lórílẹ̀-èdè Jọ́jíà, ó sì mú kára tu àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa. Ìjọba yí pa dà, ìyẹn sì mú káwọn aráàlù túbọ̀ lómìnira ẹ̀sìn. Torí ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí, ọ̀pọ̀ àwọn agbawèrèmẹ́sìn tó jẹ́ onísìn Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì tó ti gbógun ti àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tẹ́lẹ̀ ni ìjọba mú.

Òjò Ìbùkún Rọ̀ Sórí Àwọn Èèyàn Ọlọ́run

Kò pẹ́ tí inúnibíni náà dáwọ́ dúró tí àwọn èèyàn Jèhófà ní Jọ́jíà fi rí ọ̀pọ̀ ìbùkún tẹ̀mí gbà. Ní àpéjọ àgbègbè tí wọ́n ṣe lọ́dún 2004, wọ́n mú Bíbélì Ìwé Mímọ́ Kristian Lédè Griki ní Ìtumọ̀ Ayé Titun jáde lédè Jọ́jíà.

Ní Àpéjọ Àgbègbè “Ìdáǹdè Kù Sí Dẹ̀dẹ̀!” tí wọ́n wá ṣe lọ́dún 2006, ìṣẹ̀lẹ̀ mánigbàgbé míì tún wáyé. Ìdùnnú ṣubú layọ̀ nígbà táwọn tó wá sí àpéjọ náà gbọ́ pé Arákùnrin Geoffrey Jackson, tó jẹ́ ọ̀kan lára Ìgbìmọ̀ Olùdarí máa bá àwùjọ náà sọ̀rọ̀. Ìyàlẹ́nu gbáà ló jẹ́ nígbà tí Arákùnrin Jackson mú Bíbélì Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun lódindi jáde lédè Jọ́jíà!

Wọ́n mú Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun jáde lédè Jọ́jíà lọ́dún 2006

Omijé ayọ̀ lé ròrò sójú ọ̀pọ̀ àwọn tó wà níbẹ̀. Arábìnrin kan sọ pé: “Mi ò lè sọ bínú mi ṣe dùn tó nígbà tá a gba Bíbélì yẹn lódindi. . . . Ọjọ́ pàtàkì lọjọ́ náà nínú ìtàn wa.” Àwọn tó lé ní ẹgbẹ̀rún mẹ́tàdínlógún [17,000] ló gbádùn oúnjẹ tẹ̀mí yìí, mánigbàgbé ló sì jẹ́ nínú ìtàn àwọn èèyàn Jèhófà lórílẹ̀-èdè Jọ́jíà.

^ ìpínrọ̀ 29 Lọ́dún 2001 sí 2003, Gbọ̀ngàn Ìjọba méje ni wọ́n kọ́ káàkiri orílẹ̀-èdè náà.