Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Ṣé Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Máa Ń Tú Ìdílé Ká Ni àbí Wọ́n Ń Mú Kí Ìdílé Wà Níṣọ̀kan?

Ṣé Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Máa Ń Tú Ìdílé Ká Ni àbí Wọ́n Ń Mú Kí Ìdílé Wà Níṣọ̀kan?

 Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń sapá ká lè mú kí ìdílé wà níṣọ̀kan. A máa ń ṣe bẹ́ẹ̀ nínú ìdílé wa, a sì máa ń ran ìdílé àwọn aládùúgbò wa lọ́wọ́. A gbà pé Ọlọ́run ló ṣètò ìdílé. (Jẹ́nẹ́sísì 2:​21-​24; Éfésù 3:​14, 15) Nínú Bíbélì, ó kọ́ wa láwọn ìlànà tó ti ran ọ̀pọ̀ èèyàn lọ́wọ́ kárí ayé kí ìgbéyàwó wọn lè láyọ̀ kí àárín tọkọtaya sì gún régé.

Bí Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Ṣe Ń Ran Àwọn Èèyàn Lọ́wọ́ Kí Ìdílé Wọn Lè Dáa

 À ń ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe ká lè tẹ̀ lé ìmọ̀ràn inú Bíbélì, torí ó máa ń ràn wá lọ́wọ́ ká lè jẹ́ ọkọ tó dáa, ká lè jẹ́ ìyàwó tó dáa, ká sì lè jẹ́ òbí rere. (Òwe 31:10-​31; Éfésù 5:22–​6:4; 1 Tímótì 5:8) Ọ̀rọ̀ ọgbọ́n tó wà nínú Bíbélì máa ń ran àwọn tó wà nínú ìdílé lọ́wọ́ kí wọ́n lè ṣàṣeyọrí, tí ẹ̀sìn wọn bá tiẹ̀ yàtọ̀ síra. (1 Pétérù 3:​1, 2) Ẹ gbọ́ ohun táwọn kan tó ti ṣègbéyàwó sọ, àmọ́ tí wọn kì í se Ẹlẹ́rìí Jèhófà, tí ẹnì kejì wọn sì wá di Ẹlẹ́rìí Jèhófà:

  •   “Ṣe là ń jà ṣáá ní gbogbo ọdún mẹ́fà àkọ́kọ́ tá a ṣègbéyàwó, a sì máa ń múnú bí ara wa gan-an. Àmọ́ nígbà tí Ivete, ìyàwó mi di Ẹlẹ́rìí Jèhófà, o di eni tó ń ní sùúrù, ó sì wá nífẹ̀ẹ́ mi gan-an. Ìyípadà tó ṣe yìí ni ò jẹ́ kí ìgbéyàwó wa tú ká.”​—Clauir, láti orílẹ̀-èdè Brazil.

  •   “Nígbà tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ Chansa, ọkọ mi lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, mi ò gbà fún wọn, torí mo rò pé ṣe ni wọ́n máa ń tú ìdílé ká. Àmọ́ látìgbà yẹn, mo ti wá rí i pé ṣe ni ẹ̀kọ́ Bíbélì mú kí ìgbéyàwó wa dáa sí i.”​—Agness, láti orílẹ̀-èdè Zambia.

 Tá a bá ń wàásù fáwọn aládùúgbò wa, a máa ń fi ìmọ̀ràn ọlọ́gbọ́n tó wà nínú Bíbélì hàn wọ́n, èyí tó máa ràn wọ́n lọ́wọ́ kí wọ́n lè

Tẹ́nì kan bá yí ẹ̀sìn rẹ̀ pa dà, ǹjẹ́ ìyẹn lè fa èdèkòyédè nínú ìdílé?

 Lóòótọ́, ó máa ń rí bẹ́ẹ̀ nígbà míì. Bí àpẹẹrẹ, lọ́dún 1998, nígbà tí ilé iṣẹ́ Sofres ń ṣèwádìí nípa àwọn ìdílé tí ọkọ tàbí ìyàwó nìkan ti jẹ́ Ẹlẹ́rìí, wọ́n rí i pé tí wọ́n bá kó ogún (20) ìdílé jọ, ìdílé kan máa níṣòro torí pé ọkọ tàbí ìyàwó ti yí ẹ̀sìn rẹ̀ pa dà.

 Jésù sọ tẹ́lẹ̀ pé àwọn tó bá ń tẹ̀ lé ẹ̀kọ́ òun ò ní bá ìdílé wọn rẹ́ nígbà míì. (Mátíù 10:32-​36) Òpìtàn kan tó ń jẹ́ Will Durant kíyè sí i pé lábẹ́ ìjọba Róòmù, “wọ́n fẹ̀sùn kan àwọn Kristẹni pé wọ́n máa ń tú ìdílé ká,” a wọ́n sì ń fi ẹ̀sùn yẹn kan àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà náà lónìí. Ṣé ohun tó wá túmọ̀ sí ni pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ló ń fa èdèkòyédè yìí?

Ilé Ẹjọ́ Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn ti Ilẹ̀ Yúróòpù

 Nígbà tí Ilé Ẹjọ́ Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn ti Ilẹ̀ Yúróòpù ń dá ẹjọ́ ẹ̀sùn tí wọ́n fi kan àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà pé wọ́n máa ń tú ìdílé ká, Ilé Ẹjọ́ náà sọ pé ọ̀pọ̀ ìgbà làwọn mẹ́ńbà ìdílé tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń dá ìjà sílẹ̀ torí pé wọn kì í “gbà pé ìbátan wọn tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní òmìnira láti ṣe ẹ̀sìn rẹ̀ ní gbangba.” Ilé Ẹjọ́ náà fi kún un pé: “Ohun kan náà ló máa ń ṣẹlẹ̀ sí àwọn tó wà nínú ìdílé míì tí ẹ̀sìn wọn yàtọ̀ síra, kò sì yọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà sílẹ̀.” b Kódà, nígbà tí wọ́n bá ń ṣe àtakò sí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà torí ọ̀rọ̀ ẹ̀sìn, a máa ń gbìyànjú láti tẹ̀ lé ìmọ̀ràn inú Bíbélì tó sọ pé: “Ẹ má ṣe fi ibi san ibi fún ẹnì kankan. . . . Bí ó bá ṣeé ṣe, níwọ̀n bí ó bá ti jẹ́ pé ọwọ́ yín ni ó wà, ẹ jẹ́ ẹlẹ́mìí àlàáfíà pẹ̀lú gbogbo ènìyàn.”​—Róòmù 12:17, 18.

Ìdí tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà fi gbà pé ẹni tó ń ṣe ẹ̀sìn wọn nìkan ló yẹ kí wọ́n fẹ́

 Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń tẹ̀ lé ìtọ́ni inú Bíbélì tó sọ pé kéèyàn gbéyàwó “kìkì nínú Olúwa,” ìyẹn ni pé, kí wọ́n fẹ́ eni tí wọ́n jọ ní ìgbàgbọ́ kan náà. (1 Kọ́ríńtì 7:​39) Bíbélì ló pa àṣẹ yìí, ó sì bọ́gbọ́n mu. Bí àpẹẹrẹ, àpilẹ̀kọ kan tó jáde lọ́dún 2010 nínú ìwé Journal of Marriage and Family sọ pé “àwọn tọkọtaya tí wọ́n jọ ń ṣe ẹ̀sìn kan náà, tí wọ́n sì ní ìgbàgbọ́ kan náà” sábà máa ń ní àjọṣe tó dáa. c

 Àmọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kì í sọ fún àwọn mẹ́ńbà wọn pé kí wọ́n fi ọkọ tàbí ìyàwó wọn tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà sílẹ̀. Bíbélì sọ pé: “Bí arákùnrin èyíkéyìí bá ní aya tí kò gbà gbọ́, síbẹ̀ tí obìnrin náà fara mọ́ bíbá a gbé, kí ó má fi obìnrin náà sílẹ̀; àti obìnrin tí ó ní ọkọ tí kò gbà gbọ́, síbẹ̀ tí ọkùnrin náà fara mọ́ bíbá a gbé, kí ó má fi ọkọ rẹ̀ sílẹ̀.” (1 Kọ́ríńtì 7:​12, 13) Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń tẹ̀ lé àṣẹ yìí.

a Wo ìwé Caesar and Christ, ojú ìwé 647.

b Wo ẹjọ́ tí wọ́n dá tó wà nínú ìwé Jehovah’s Witnesses of Moscow and Others v. Russia, ojú ìwé 26-27, ìpínrọ̀ 111.

c Wo ìwé náà, Journal of Marriage and Family, Volume 72, Number 4, (August 2010), ojú ìwé 963.