Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwọn Ìwé Ìhìn Rere Mẹ́rin ti Mokvi, tí wọ́n fọwọ́ kọ lédè Jọ́jíà ní ọgọ́rùn-ún ọdún kẹrìnlá

JỌ́JÍÀ | 1924-1990

Bíbélì Lédè Jọ́jíà

Bíbélì Lédè Jọ́jíà

ÈDÈ JỌ́JÍÀ wà lára àwọn èdè tí wọ́n kọ́kọ́ túmọ̀ Bíbélì sí, bíi ti èdè Àméníà, Coptic, Latin, Syriac àtàwọn èdè míì. Àárín ọgọ́rùn-ún ọdún karùn-ún tàbí ṣáájú ìgbà yẹn ni àwọn ìwé àfọwọ́kọ lédè Jọ́jíà ti wà, irú bí àwọn ìwé Ìhìn Rere, àwọn lẹ́tà Pọ́ọ̀lù àti ìwé Sáàmù. Láwọn ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún tó tẹ̀ lé e, àwọn Bíbélì tí wọ́n ń túmọ̀ sí èdè Jọ́jíà pọ̀ sí i, àwọn ẹ̀dà tí wọ́n fọwọ́ kọ sì ń pọ̀ sí i, ìyẹn wá mú kí oríṣiríṣi ìtúmọ̀ Bíbélì wà. *

Àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè Jọ́jíà bẹ̀rẹ̀ sí í lo ọ̀rọ̀ inú Bíbélì gan-an nínú àwọn ìwé tí wọ́n ń ṣe, ó ń hàn nínú àṣà wọn pàápàá. Bí àpẹẹrẹ, nínú ìtàn kan tó ṣeé ṣe kí wọ́n kọ ní òpin ọgọ́rùn-ún ọdún karùn-ún nípa ohun tó gbẹ̀yìn Ọbabìnrin Shushanik, wọ́n fa ọ̀rọ̀ yọ látinú oríṣiríṣi ẹsẹ Bíbélì, wọ́n sì tọ́ka sí àwọn ẹsẹ Bíbélì kan. Bákan náà, nínú ewì tí àkòrí rẹ̀ ń jẹ́ Vepkhvistqaosani (Akọgun Tó Gbé Awọ Ẹkùn Wọ̀) tí Ọ̀gbẹ́ni Shota Rustaveli kọ ní nǹkan bí ọdún 1220, ó mẹ́nu kan àwọn ìwà Kristẹni. Ó kọ ewì tó dá lórí ọ̀rẹ́ níní, kéèyàn jẹ́ ọ̀làwọ́, kéèyàn sì nífẹ̀ẹ́ àlejò. Àwọn ará Jọ́jíà ṣì ka àwọn ìwà yìí sí ìwà tó yẹ ọmọlúàbí dòní.

^ ìpínrọ̀ 3 Tó o bá fẹ́ mọ̀ sí i, wo àpilẹ̀kọ “Ìṣura Kan Tó Fara Sin Láti Ọgọ́rọ̀ọ̀rún Ọdún,” nínú Ilé Ìṣọ́ June 1, 2013.