Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ | ṢÉ WÀÁ FẸ́ KẸ́KỌ̀Ọ́ BÍBÉLÌ?

Ki Nidi To Fi Ye Ko O Kekoo Bibeli?

Ki Nidi To Fi Ye Ko O Kekoo Bibeli?
  • Kí nìdí tá a fi wà láyé?

  • Kí nìdí tá a fi ń jìyà tá a sì ń kú?

  • Kí ló máa ṣẹlẹ̀ ní ọjọ́ ọ̀la?

  • Ṣé Ọlọ́run bìkítà nípa mi?

Ǹjẹ́ o ti bi ara rẹ ní irú àwọn ìbéèrè yìí rí? Tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, mọ̀ pé kì í ṣe ìwọ nìkan lo ní irú èrò bẹ́ẹ̀. Kárí ayé làwọn èèyàn ti ń wá ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè tó ṣe pàtàkì nígbèésí ayé. Ǹjẹ́ o lè rí ìdáhùn?

Ọ̀pọ̀ èèyàn máa dáhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni!” Kí nìdí? Ìdí ni pé wọ́n ti rí àwọn ìdáhùn tó tẹ́ wọn lọ́rùn nínú Bíbélì. Ṣé wàá fẹ́ mọ ohun tí Bíbélì sọ? Tó o bá fẹ́ bẹ́ẹ̀, ẹ̀kọ́ Bíbélì tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń kọ́ àwọn èèyàn lọ́fẹ̀ẹ́ máa ṣe ẹ́ láǹfààní. *

Tó bá kan pé ká kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, àwọn kan máa ń sọ pé: “Mi ò kì í ráyè.” “Ó ti le jù.” “Mi ò fẹ́ràn kí n máa ṣàdéhùn.” Àmọ́, èrò àwọn míì yàtọ̀ síyẹn. Wọ́n gbà láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Jẹ́ ká wo àwọn àpẹẹrẹ mélòó kan:

  • “Mo ti lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì àti ti Pùròtẹ́sítáǹtì, mo lọ sí tẹ́ńpìlì àwọn ẹlẹ́sìn Sikh, mo ṣe ẹ̀sìn Búdà, mo sì lọ kẹ́kọ̀ọ́ ìsìn ní yunifásítì. Àmọ́, mi ò rí ìdáhùn sí ọ̀pọ̀ ìbéèrè tó ń jẹ mí lọ́kàn. Lọ́jọ́ kan, Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan wá sí ilé mi. Bó ṣe fi Bíbélì dáhùn àwọn ìbéèrè mi wú mi lórí. Èyí sì mú kí n gbà láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.”—Gill, ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì.

  • “Mo ní ọ̀pọ̀ ìbéèrè nípa ìgbésí ayé, àmọ́ pásítọ̀ ṣọ́ọ̀ṣì mi kò fún mi ní ìdáhùn tó tẹ́ mi lọ́rùn. Àmọ́, Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan fi Bíbélì nìkan dáhùn àwọn ìbéèrè mi. Nígbà tó béèrè bóyá máa fẹ́ kẹ́kọ̀ọ́ sí i, tayọ̀tayọ̀ ni mo gbà.”—Koffi, Benin.

  • “Mo fẹ́ mọ ohun tó ń ṣẹlẹ̀ sáwọn tó ti kú. Mo gbà pé àwọn òkú lè ṣe àwọn èèyàn ní jàǹbá, àmọ́ ó wù mí láti mọ ohun tí Bíbélì sọ nípa rẹ̀. Torí náà, mo bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́dọ̀ ọ̀rẹ́ mi tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà.”—José, Brazil.

  • “Mo ka Bíbélì, àmọ́ ohun tí mo kà kò yé mi. Lọ́jọ́ kan, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà wá sọ́dọ̀ mi, wọ́n sì ṣàlàyé àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì mélòó kan fún mi. Èyí mú kó wù mí láti mọ̀ sí i.”—Dennize, Mẹ́síkò.

  • “Mo máa ń ronú pé bóyá ni Ọlọ́run bìkítà nípa mi. Torí náà, mo gbàdúrà sí Ọlọ́run tí Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀. Ní ọjọ́ kejì, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà wá sílé mi, mo sì gbà láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.”—Anju, Nepal.

Àwọn ìrírí yìí rán wa létí ohun tí Jésù sọ pé: “Aláyọ̀ ni àwọn tí àìní wọn nípa ti ẹ̀mí ń jẹ lọ́kàn.” (Mátíù 5:3) Ká sòótọ́, ó máa ń wù wá láti mọ Ọlọ́run. Ọlọ́run nìkan sì lẹni tó lè mú ká mọ òun nípasẹ̀ Bíbélì, Ọ̀rọ̀ rẹ̀.

Báwo la ṣe ń ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì? Ọ̀nà wo ni ẹ̀kọ́ yìí máa gbà ṣe ẹ́ láǹfààní? A máa rí ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè yìí nínú àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé èyí.

^ ìpínrọ̀ 8 Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé Jèhófà ni orúkọ Ọlọ́run.