Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÌFỌ̀RỌ̀WÁNILẸ́NUWÒ | RAJESH KALARIA

Onímọ̀ Nípa Àrùn Ọpọlọ Ṣàlàyé Ohun Tó Gbà Gbọ́

Onímọ̀ Nípa Àrùn Ọpọlọ Ṣàlàyé Ohun Tó Gbà Gbọ́

Ó LÉ ní ogójì [40] ọdún báyìí tí ọ̀jọ̀gbọ́n Rajesh Kalaria tó wà ní Yunifásítì Newcastle ti orílẹ̀-èdè England, ti ń ṣèwádìí nípa ọpọlọ èèyàn. Tẹ́lẹ̀, èrò rẹ̀ ni pé ńṣe ni gbogbo ohun alààyè kàn ṣàdédé wà, bí ẹ̀kọ́ ẹfolúṣọ̀n ṣe sọ ọ́, àmọ́ nígbà tó yá, ìgbàgbọ́ rẹ̀ yí pa dà. Ó ṣàlàyé nípa iṣẹ́ rẹ̀ àti ohun tó gbà gbọ́ fún àwọn akọ̀ròyìn Jí!

Ẹ̀sìn wo ni ìdílé yín ń ṣe?

Orílẹ̀-ède India ni wọ́n bí bàbá mi sí, ọmọ ilẹ̀ India ni ìyá mi náà, àmọ́ orílẹ̀-èdè Uganda ní wọ́n bí wọn sí. Àwọn méjéèjì ti jingíri sínú àwọn àṣà Hindu. Èmi ni ìkejì nínú ọmọ mẹ́ta tí wọ́n bí. Ìlú Nairobi ní orílẹ̀-èdè Kenya là ń gbé. Ọ̀pọ̀ àwọn ẹ̀yà Hindu ló ń gbé ìtòsí ibẹ̀.

Kí nìdí tó o fi fẹ́ràn sáyẹ́ǹsì?

Mo fẹ́ràn àwọn ẹranko, mo sì sábà máa ń tẹ̀ lé àwọn ọ̀rẹ́ mi lọ wo oríṣiríṣi àwọn ẹranko àgbàyanu. Tẹ́lẹ̀, ohun tó wù mí ni pé kí n di dókítà tó máa ń tọ́jú àwọn ẹranko. Àmọ́ nígbà tí mo parí ilé ẹ̀kọ́ kan ní ìlú Nairobi, mo kọjá sí Yunifásítì ti London ní orílẹ̀-èdè England láti lọ kẹ́kọ̀ọ́ nípa oríṣiríṣi àrùn àti ohun tí wọ́n ń fà nínú ara. Nígbà tó yá, mo kúkú wá gbájú mọ́ ìwádìí nípa ọpọlọ èèyàn.

Ipa wo ni ohun tó o kọ́ nílé ẹ̀kọ́ ní lórí ohun tó o gbà gbọ́?

Bí mo ṣe ń tẹ̀ síwájú sí i nínú ẹ̀kọ́ sáyẹ́ǹsì, bẹ́ẹ̀ náà ló ṣe túbọ̀ ń ṣòro fún mi láti fara mọ́ àwọn ìgbàgbọ́ àti àṣà Hindu, lára wọn ni ìjọsìn àwọn ẹranko àti ère.

Kí nìdí tó o fi gbà pé ńṣe ni gbogbo ohun alààyè kàn ṣàdédé wà, bí ẹ̀kọ́ ẹfolúṣọ̀n ṣe sọ?

Nígbà tí mo wà lọ́mọdé, mo máa ń gbọ́ tí ọ̀pọ̀ èèyàn máa ń sọ pé ilẹ̀ Áfíríkà ni àwọn ohun alààyè kan ti bẹ̀rẹ̀ sí í di èèyàn díẹ̀díẹ̀. A sì máa ń kọ́ ẹ̀kọ́ náà ní ilé ìwé, ìyẹn ẹ̀kọ́ ẹfolúṣọ̀n. Àti pé àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n àtàwọn olùkọ́ wa ní yunifásítì máa ń sọ pé gbogbo àwọn olókìkí onímọ̀ sáyẹ́ǹsì tí aráyé ń wárí fún ló gba ẹ̀kọ́ efolúṣọ̀n gbọ́.

Àmọ́ kí nìdí tó o fi wá tún èrò rẹ pa, tó o sì ṣèwádìí nípa bí àwọn ohun alààyè ṣe bẹ̀rẹ̀?

Ó tó ọdún mélòó kan ti mo ti ń kẹ́kọ̀ọ́ nípa ohun alààyè àti ohun tó ń ṣẹlẹ̀ nínú ara èèyàn, kí ọmọ ilé ẹ̀kọ́ mi kan tó sọ fún mi nípa ohun tó kọ́ látinú Bíbélì lọ́dọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ó wu èmi náà Iáti mọ̀ nípa rẹ̀. Torí náà, nígbà tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà wá ṣe àpéjọ kan nínú gbọ̀ngàn kan nílé ẹ̀kọ́ wa ní ìlú Nairobi, èmi náà lọ síbẹ̀. Nígbà tó yá, àwọn míṣọ́nnárì méjì ṣàlàyé àwọn ẹ̀kọ́ Bíbélì kan fún mi. Wọ́n gbà pé Ẹlẹ́dàá Atóbilọ́lá kan wà tó mọ ìdáhùn sí gbogbo àwọn ìbéèrè tó ta kókó nípa ìgbésí ayé, mo sì wá rí i pé àlàyé wọn kì í ṣe ìtàn àròsọ lásán. Ọ̀rọ̀ wọn wọ̀ mí lọ́kàn, ó sì bọ́gbọ́n mu.

Ǹjẹ́ ohun tó o mọ̀ nípa ìṣègùn kò ṣèdíwọ́ fún ẹ láti gbà pé Ọlọ́run ló dá àwọn ohun alààyè?

Rárá o! Bí mo ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́ nípa ohun tó ń ṣẹlẹ̀ nínú ara èèyàn ni mo túbọ̀ ń rí i pé ohun àgbàyanu àti àwámáridìí gbáà ni àwọn ohun alààyè. Torí náà, mo ti wá rí i pé kò bọ́gbọ́n mu láti máa sọ pé irú àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀ kàn ṣàdédé wà ni.

Ǹjẹ́ o lè fún wa ní àpẹẹrẹ kan?

Láti ọdún 1971 ni mo ti ń ṣèwádìí nípa ọpọlọ èèyàn, gbogbo ìgbà sì ni ohun tí mò ń kọ́ nípa rẹ̀ máa ń yà mí lẹ́nu. Ọpọlọ la fi ń ronú, òun ló ń jẹ́ ká máa rántí nǹkan, òun la sì fi ń darí ọ̀pọ̀ ohun tí à ń ṣe. Òun gangan ló ń jẹ́ ká ní ìmọ̀lára, ì báà jẹ́ ohun tó ń ṣẹlẹ̀ nínú àgọ́ ara wa tàbí láyìíká wa.

Àwọn sẹ́ẹ̀lì oríṣiríṣi ló wà nínú ọpọlọ wa, àwọn míì tún so kọ́ra lọ́nà àrà. Gbogbo nǹkan yìí ló ń jẹ́ kí ọpọlọ wa lè ṣe ọ̀pọ̀ nǹkan tó ń ṣe. Ọ̀pọ̀ bílíọ̀nù sẹ́ẹ̀lì ló wà nínú ọpọlọ wa, ohun kan tó dà bí okùn tẹ́ẹ́rẹ́ sì wà tó máa ń ta àtaré ìsọfúnni láti ara sẹ́ẹ̀lì kan sí òmíràn, kí gbogbo wọn lè máa bá ara wọn ṣiṣẹ́. Láti ara okùn tẹ́ẹ́rẹ́ yìí ni ẹgbẹgbẹ̀rún ìsọfúnni ti máa ń lọ sára ọ̀pọ̀ àwọn sẹ́ẹ̀lì míì nínú ọpọlọ. Èyí fi hàn pé ọ̀nà tí àwọn sẹ́ẹ̀lì tó ń ṣiṣẹ́ pọ̀ yìí gbà so kọ́ra kọjá àfẹnusọ! Ohun tó tún yani lẹ́nu ni pé àwọn sẹ́ẹ̀lì náà kò kan só kọ́ra jánganjàngan bí ìgbà téèyàn kàn lọ́ wáyà mọ́ra, ńṣe ni wọ́n wà létòlétò. Ohun àrà gbáà lèyí jẹ́.

Jọ̀ọ́, ṣàlàyé kó lè yé wa.

Ṣẹ́ ẹ rí i, látìgbà tí ọmọ bá ti bẹ̀rẹ̀ sí í dàgbà nínú ìyá rẹ̀ ni ìsokọ́ra yìí ti máa bẹ̀rẹ̀ létòlétò lọ́nà tó gadabú, á sì máa bá a lọ bẹ́ẹ̀ lẹ́yìn tí wọ́n bá bí ọmọ náà. Àwọn sẹ́ẹ̀lì kan á fi ìsọfúnni ránṣẹ́ sí sẹ́ẹ̀lì míì tó jọ pé ó wà nítòsí àmọ́ tí wọ́n jìnnà síra gidi. Bẹ́ẹ̀ sì rèé, tí sẹ́ẹ̀lì kan bá fi ìsọfúnni ránṣẹ́ sí sẹ́ẹ̀lì míì, apá ibi tó yẹ kí ìsọfúnni náà lọ gangan ló máa lọ ní tààràtà kì í wulẹ̀ ṣe inú odindi sẹ́ẹ̀lì náà.

Bí ìsọfúnni tuntun kan bá jáde láti ara sẹ́ẹ̀lì kan, kẹ́míkà kan á ti wà ní sẹpẹ́ tí á máa darí ìsọfúnni náà bí atọ́nà tó ń sọ pé “dúró,” “máa lọ,” tàbí “yà” títí tó fi máa dé ibi tó ń lọ. Láìsí ohun tó dà bí atọ́nà yìí, ńṣe ni ìsọfúnni á kàn máa sọ nù ṣeré nínú ọpọlọ wa. Gbogbo ohun tá à ń sọ yìí ò kàn dédé máa ṣẹlẹ̀ o, látinú àpilẹ̀ àbùdá wa ló ti bẹ̀rẹ̀.

Ṣẹ́ ẹ wá rí i báyìí pé ìwọ̀nba ni ohun tá a ṣì mọ̀ nípa bí ọpọlọ àwa èèyàn ṣe ń ṣiṣẹ́, bó ṣe ń kó ìsọfúnni jọ ká lè máa rántí nǹkan, bó ṣe ń mú ká ní ìmọ̀lára àti bó ṣe ń mú ká ronú? Ní tèmi, ti pé ọpọlọ àwa èèyàn tiẹ̀ ń ṣiṣẹ́ nìkan tó fún mi láti gbà pé ẹnì kan tí ìrònú rẹ̀ ga lọ́nà tí kò láfiwé ló ṣẹ̀dá wa, ká má ṣẹ̀ṣẹ̀ sọ bí ọpọlọ wa ń ṣe ń dàgbà lọ́nà àrà.

Kí nìdí tó o fi wá di Ẹlẹ́rìí Jèhófà?

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà fi àwọn ẹ̀rí tó jóòótọ́ hàn mí pé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ni Bíbélì. Bí àpẹẹrẹ, bó tiẹ̀ jẹ́ pé Bíbélì kì í ṣe ìwé sáyẹ́ǹsì, gbogbo ohun tó sọ nípa sáyẹ́ǹsì ló jóòótọ́ látòkè délẹ̀. Òótọ́ sì ni gbogbo àsọtẹ́lẹ̀ inú rẹ̀. Bí èèyàn bá ń tẹ̀ lé ohun tó wà nínú rẹ̀, ayé èèyàn á dára. Ó ti mú kí ayé mi dára gan-an. Látìgbà tí mo ti di Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní ọdún 1973 ni mo ti ń fi Bíbélì darí ìgbésí ayé mi. Torí bẹ́ẹ̀, ayé mi ti ládùn ó sì lóyin.