Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÌFỌ̀RỌ̀WÁNILẸ́NUWÒ | YAN-DER HSUUW

Onímọ̀ Nípa Ọlẹ̀ Ṣàlàyé Ohun Tó Gbà Gbọ́

Onímọ̀ Nípa Ọlẹ̀ Ṣàlàyé Ohun Tó Gbà Gbọ́

Ọ̀JỌ̀GBỌ́N Yan-Der Hsuuw ni olùdarí ẹ̀ka tó ń ṣèwádìí nípa ọlẹ̀ ní yunifásítì kan tí wọ́n ń pè ní Taiwan’s National Pingtung University of Science and Technology. Ó ti fìgbà kan rí gbà gbọ́ nínú ẹ̀kọ́ ẹfolúṣọ̀n, àmọ́ lẹ́yìn tó di onímọ̀ sáyẹ́ǹsì, ó yí èrò rẹ̀ pa dà. Ó ṣàlàyé ohun tó fà á fún àwọn akọ̀ròyìn Jí!

Jọ̀wọ́ sọ fún wa nípa bí wọ́n ṣe tọ́ ẹ dàgbà.

Ọdún 1966 ni wọ́n bí mi, orílẹ̀-èdè Taiwan ni mo sì dàgbà sí. Ẹ̀sìn Tao àti Búdà làwọn òbí mi ń ṣe. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé a máa ń jọ́sìn àwọn baba ńlá wa, a sì máa ń gbàdúrà sáwọn ère, síbẹ̀ a ò gbà pé ẹnì kan wà tó jẹ́ Ẹlẹ́dàá.

Kí nìdí tó o fi kẹ́kọ̀ọ́ nípa àwọn nǹkan ẹlẹ́mìí?

Nígbà tí mo wà ní kékeré, mo fẹ́ràn kí n máa sin ẹran. Ó sì máa ń wù mí láti tọ́jú àwọn ẹranko àtàwọn èèyàn tó bá ń ṣàìsàn. Mo kọ́kọ́ kẹ́kọ̀ọ́ nípa ìtọ́jú àwọn ẹranko, nígbà tó sì yá, mo lọ kẹ́kọ̀ọ́ nípa ọlẹ̀. Mo ronú pé ẹ̀kọ́ yìí máa jẹ́ kí n mọ ibi táwọn ohun alààyè ti ṣẹ̀ wá.

Kí ló mú kó o gba ẹ̀kọ́ ẹfolúṣọ̀n gbọ́ nígbà kan?

Àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n tó wà ní yunifásítì máa ń kọ́ wa lẹ́kọ̀ọ́ ẹfolúṣọ̀n, wọ́n sì sọ pé àwọn ẹ̀rí wà tó fi hàn pé òótọ́ ni ẹ̀kọ́ náà. Lèmi náà bá gbà wọ́n gbọ́.

Kí ló dé tó o fi bẹ̀rẹ̀ sí í ka Bíbélì?

Ohun méjì ló fà á. Lákọ̀ọ́kọ́, mo ronú pé nínú ọ̀pọ̀ ọlọ́run táwọn èèyàn ń sìn, ọ̀kan máa wà tó ju gbogbo àwọn tó kù lọ. Àmọ́, èwo ni? Èkejì, mo gbà pé ìwé táwọn èèyàn kà sí pàtàkì ni Bíbélì. Torí náà, mo sapá láti mọ púpọ̀ sí i nípa Bíbélì.

Nígbà tí mo bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ ní Belgium’s Catholic University tó wà ní ìlú Leuven lọ́dún 1992, mo lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì kan, mo sì sọ fún àlùfáà tó wà níbẹ̀ pé kó kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, àmọ́ ó kọ̀ jálẹ̀.

Báwo lo ṣe wá rí ìdáhùn sáwọn ìbéèrè rẹ?

Lẹ́yìn ọdún méjì, mo pàdé obìnrin Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan láti orílẹ̀-èdè Poland tó ń jẹ́ Ruth. Nígbà yẹn, mo ṣì wà lórílẹ̀-èdè Belgium níbi tí mo ti ń ṣe àwọn ìwádìí nípa iṣẹ́ mi. Ruth ti kọ́ èdè Chinese kó lè ṣèrànwọ́ fún àwọn ọmọ yunifásítì tó fẹ́ kẹ́kọ̀ọ́ nípa Ọlọ́run. Mo ti gbàdúrà fún irú ìrànlọ́wọ́ yìí, torí náà, inú mi dùn nígbà tí mo pàdé Ruth.

Ruth jẹ́ kí n mọ̀ pé bó tilẹ̀ jẹ́ pé Bíbélì kì í ṣe ìwé ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì, síbẹ̀ ohun tó wà nínú rẹ̀ bá ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì mu. Bí àpẹẹrẹ, Dáfídì tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn tó kọ Bíbélì sọ nínú àdúrà tó gbà sí Ọlọ́run pé: “Àní ojú rẹ rí ọlẹ̀ mi, inú ìwé rẹ sì ni gbogbo àwọn ẹ̀yà rẹ̀ wà ní àkọsílẹ̀, ní ti àwọn ọjọ́ tí a ṣẹ̀dá wọn, tí ìkankan lára wọn kò sì tíì sí.” (Sáàmù 139:16) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀nà ewì ni Dáfídì gbà sọ̀rọ̀, síbẹ̀ òótọ́ pọ́ńbélé lohun tó sọ! Ṣáájú kí àwọn ẹ̀yà ara tó fara hàn, ìlànà bó ṣe máa rí tí wà nínú ọlẹ̀. Bí Bíbélì ṣe péye jẹ́ kó da mi lójú pé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ni. Èyí sì jẹ́ kí n gbà pé Ọlọ́run tòótọ́ kan ṣoṣo ló wà, ìyẹn Jèhófà. 1

Kí ló jẹ́ kó o gbà pé Ọlọrun ló dá ẹ̀mí?

Àfojúsùn àwọn tó ń ṣe ìwádìí ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì ni pé kí wọ́n ṣèwádìí tó máa jẹ́ kí wọ́n rí òkodoro òtítọ́, kì í ṣe kí wọ́n kàn wá ohun tó máa ti èrò wọn lẹ́yìn. Ìwádìí tí mo ṣe nípa bí ọlẹ̀ ṣe ń dàgbà ló jẹ́ kí n yí èrò mi pa dà, tí mo fi wá gbà pé Ẹlẹ́dàá wà. Bí àpẹẹrẹ, àwọn ẹnjiníà ṣètò ìlà tí wọ́n ti ń to ẹ̀rọ pa pọ̀ ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀lé. Bí ọlẹ̀ náà ṣe ń tò pa pọ̀ ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀lé nìyẹn, àmọ́ ní ọ̀nà tó túbọ̀ díjú ju ti ẹ̀rọ lọ.

Ṣebí orí sẹ́ẹ̀lì kan tó fẹ́ra kù ló ti máa ń bẹ̀rẹ̀, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́?

Bẹ́ẹ̀ ni. Sẹ́ẹ̀lì bíńtín náà á wá bẹ̀rẹ̀ sí í pín ara rẹ̀ sí kéékèèké. Fúngbà díẹ̀, àwọn sẹ́ẹ̀lì náà máa ń di ìlọ́po-ìlọ́po láàárín wákàtí méjìlá sí mẹ́rìnlélógún. Nígbà tí àwọn àyípadà yìí bá ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀, sẹ́ẹ̀lì kan tí wọ́n ń pè ní stem cells máa fara hàn. 2 Sẹ́ẹ̀lì yìí lè mú nǹkan bí igba [200] onírúurú sẹ́ẹ̀lì míì jáde tó máa wá para pọ̀ di odindi ọmọ jòjòló. Lára irú àwọn sẹ́ẹ̀lì tó máa ń mú jáde ni sẹ́ẹ̀lì ẹ̀jẹ̀, sẹ́ẹ̀lì eegun, sẹ́ẹ̀lì iṣan, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.

Ìwádìí tí mo ṣe nípa ọlẹ̀ jẹ́ kí n gbà pé Ọlọ́run ló dá àwọn ohun alààyè

Àwọn sẹ́ẹ̀lì yìí gbọ́dọ̀ fara hàn níbi tó yẹ àti lásìkò tó yẹ. Àwọn sẹ́ẹ̀lì yìí máa kóra jọ, wọ́n á sì para pọ̀ di àwọn ẹ̀yà ara bí ẹ̀dọ̀, ọkàn, ọpọlọ, apá àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Ẹnjiníà wo ló lè ṣe irú iṣẹ́ tó díjú bẹ́ẹ̀? Síbẹ̀, gbogbo ìlànà yìí ló ti wà níbì kan nínú ọlẹ̀ náà tí wọ́n ń pè DNA. Gbogbo èyí ló jẹ́ kí n gbà pé Ọlọ́run ló dá àwọn ohun alààyè.

Kí ló dé tó o fi di ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà?

Lọ́rọ̀ kan, ìfẹ́ ni. Jésù Kristi sọ pé: “Nípa èyí ni gbogbo ènìyàn yóò fi mọ̀ pé ọmọ ẹ̀yìn mi ni yín, bí ẹ bá ní ìfẹ́ láàárín ara yín.” (Jòhánù 13:35) Kò sí ojúsàájú nínú ìfẹ́ yìí. Àwọn tó bá ní irú ìfẹ́ bẹ́ẹ̀ kì í wo ìlú téèyàn ti wá, àṣà tàbí àwọ̀ téèyàn ní. Irú ìfẹ́ yìí gan-an ni mo rí láàárín àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà nígbà tí mo bẹ̀rẹ̀ sí í dara pọ̀ mọ́ wọn.

^ 2. Ọ̀jọ̀gbọ́n Yan-Der Hsuuw kì í fi ọlẹ̀ èèyàn ṣe ìwádìí torí pé gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni, ẹ̀rí ọkàn rẹ̀ kò gbé e.