Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

TA LÓ ṢIṢẸ́ ÀRÀ YÌÍ?

Èso Pollia

Èso Pollia

ÈSO kékeré kan wà tó ń jẹ́ Pollia, ọ̀pọ̀ ibi ni èso yìí wà káàkari ilẹ̀ Áfíríkà. Kò sí ewéko tàbí èso kan táwọn èèyan mọ̀ tó ní àwọ̀ búlúù tó ń tàn yanran tó èso yìí. Síbẹ̀, kò sí èròjà olómi aró kankan lára rẹ̀. Kí ló mú kí àwọ̀ rẹ̀ máa tàn yanran tó bẹ́ẹ̀?

Rò ó wò ná: Àwọn okùn tẹ́ẹ́rẹ́ kan wà nínú èèpo èso yìí tó dà bí ìgbà tí wọ́n to àwọn igi ìṣáná sẹ́gbẹ̀ẹ́ ara wọn. Àwọn okùn yìí wà ní ìpele-ìpele lórí ara wọn, ìpele kọ̀ọ̀kan máa ń dagun díẹ̀ tó bá wà lórí òmíràn, tí èèyàn bá wá wo gbogbo ìpele yẹn lápapọ̀, ńṣe lo máa ń dà bíi pé ó fa ilà kọ́lọkọ̀lọ. Bẹ́ẹ̀ sì rèé, okùn yẹn kò ní àwọ̀ búlúù. Àmọ́ bí àwọn okùn yẹn ṣe wà lórí ara wọn ló gbé àwọ̀ yẹn jáde. Torí náà, bí inú èso yìí ṣe rí ló jẹ́ kó ní àwọ̀ tó ń bì tó sì ń tàn yanran bẹ́ẹ̀, kì í ṣe pé èròjà olómi aró kankan wà nínú rẹ̀. Àwọ̀ búlúù ni èyí tó pọ̀ jù lára àwọn èso yìí máa ń ní. Àmọ́ téèyàn bá ń wò ó láti apá ibi tó yà tọ̀, àwọn kan lè gbé àwọ̀ ewé, àwọ̀ osùn tàbí àwọ̀ yẹ́lò jáde, èyí sì jẹ́ nítorí àwọn àyípadà fẹ́ẹ́rẹ́fẹ́ tó máa ń ṣẹlẹ̀ lára èèpo àwọn èso náà. Ohun míì ni pé, tá a bá wò ó dáadáa, a máa rí i pé àwọ̀ rẹ̀ kò dọ́gba dẹ́lẹ̀, ńṣe ló rí bí àwòràn ojú kọ̀ǹpútà.

Torí pé kò sí èròjà olómi aró kankan nínú èso Pollia, àwọ̀ wọn ṣì máa ń wà digbí kódà tí wọ́n bá já bọ́ lára igi. Àwọn èso Pollia kan tiẹ̀ wà tí wọ́n ti tọ́jú pa mọ́ láti ohun tó lé ní ọgọ́rùn-ún [100] ọdún sẹ́yìn, àmọ́ ńṣe ni àwọ̀ wọn ṣì wà digbí, bíi pé wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ ká wọn ni! Àwọn kan tó ṣèwádìí sọ pé pẹ̀lú bó ṣe jẹ́ pé kò sí ibì kan tó rọ̀ tó sì ṣeé bù jẹ lára èso yìí, síbẹ̀ àwọn ẹyẹ tó wà nítòsí kì í yéé pààrà ìdí rẹ̀.

Àwọn onímọ̀ sáyẹ́ńsì gbà pé bó ṣe jẹ́ pé kò sí èròjà olómi aró nínú èso Pollia, àmọ́ tó ní àwọ̀ búlúù tó ń tàn yanran yìí, àwọn lè wò ó láti ṣe àwọn aró tí kò ní ṣá àti àwọn bébà tí ayédèrú rẹ̀ máa ṣòro gan-an láti ṣe.

Kí Lèrò Rẹ? Ṣé àwọ̀ búlùù tó ń tàn yanran tí èso Pollia ní ṣàdédé rí bẹ́ẹ̀ ni? Àbí ẹnì kan ló ṣiṣẹ́ àrà yìí?