Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ìlera Tó Dáa

Ìlera Tó Dáa

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Bíbélì kì í ṣe ìwé ìṣègùn, síbẹ̀, ó fún wa ní àwọn ìmọ̀ràn tó lè jẹ́ kí ìlera wa dáa sí i. Wo díẹ̀ lára àwọn ìlànà Bíbélì tó lè jẹ́ kí ìlera rẹ dáa sí i.

TỌ́JÚ ARA RẸ

ÌLÀNÀ BÍBÉLÌ: “Kò sí èèyàn kankan tó jẹ́ kórìíra ara rẹ̀, àmọ́ á máa bọ́ ara rẹ̀, á sì máa ṣìkẹ́ rẹ̀.”​—Éfésù 5:29.

OHUN TÓ TÚMỌ̀ SÍ: Ẹsẹ Bíbélì yìí ń gbà wá níyànjú láti ṣe gbogbo ohun tó bá yẹ ká ṣe láti bójú tó ìlera wa. Ìwádìí kan fi hàn pé bí àwọn èèyàn ṣe ń gbé ìgbé ayé wọn ló sábà máa ń pinnu bí ìlera wọn ṣe máa rí. Torí náà, téèyàn bá ń gbé ìgbé ayé tó dáa, ìlera rẹ̀ á máa dáa sí i.

OHUN TÓ O LÈ ṢE:

  • Oúnjẹ. Máa jẹ oúnjẹ aṣaralóore, kó o sì máa mu omi dáadáa.

  • Eré Ìmárale. Bóyá ọmọdé ni ẹ́ tàbí àgbàlagbà, tó o bá ń ṣe eré ìmárale déédéé, ìlera rẹ á máa dáa sí i. Kódà tó o bá jẹ́ aláàbọ̀ ara tàbí tó ò ń ṣàìsàn tó le, o ṣì lè ṣe eré ìmárale. Òótọ́ ni pé àwọn tó sún mọ́ wa tàbí àwọn dókítà lè dábàá pé ká máa ṣe eré ìmáralé, àmọ́ ọwọ́ wa ló kù sí láti ṣe é!

  • Oorun. Tẹ́nì kan bá ń fi oorun du ara rẹ̀, ó lè mú kó ṣàìsàn tó lágbára. Ìwọ̀nba oorun làwọn míì máa ń sùn torí pé àkókò tó yẹ kí wọ́n sùn ni wọ́n fi ń ṣe àwọn nǹkan míì. Àmọ́, tó o bá ń sùn dáadáa, ìlera rẹ á máa sunwọ̀n sí i.

JÁWỌ́ NÍNÚ ÀṢÀ TÍ KÒ DÁA

ÌLÀNÀ BÍBÉLÌ: “Ẹ jẹ́ kí a wẹ ara wa mọ́ kúrò nínú gbogbo ẹ̀gbin ti ara àti ti ẹ̀mí.”​—2 Kọ́ríńtì 7:1.

OHUN TÓ TÚMỌ̀ SÍ: A máa ṣe ara wa láǹfààní tó pọ̀ tá a bá ń sá fún àwọn nǹkan tó lè kó ẹ̀gbin bá ara wa, bíi sìgá, igbó àti tábà, torí pé wọ́n máa ń fa oríṣiríṣi àìsàn tó lè yọrí sí ikú.

OHUN TÓ O LÈ ṢE: Yan ọjọ́ kan tó o máa jáwọ́ nínú rẹ̀, kó o sì lẹ déètì náà mọ́ ibi tí wàá ti máa rí i. Kó tó di ọjọ́ yẹn, kó gbogbo sìgá tàbí igbó tó wà lọ́wọ́ rẹ dà nù, àtàwọn ohun míì tó lè mú kí ọkàn ẹ máa fà sí àṣà burúkú yìí. Má sì lọ síbi táwọn èèyàn ti ń mu sìgá tàbí igbó. O tún lè sọ fún tẹbí-tọ̀rẹ́ pé o ti pinnu láti jáwọ́ nínú àṣà yìí, kí wọ́n lè tì ẹ́ lẹ́yìn.

ÀWỌN ÌLÀNÀ BÍBÉLÌ MÍÌ

O lè gba Bíbélì kan lọ́wọ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ládùúgbò rẹ

MÁA SÁ FÚN EWU.

“Tí o bá kọ́ ilé tuntun, kí o ṣe ìgbátí sí òrùlé rẹ, kí o má bàa mú kí ilé rẹ jẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ torí pé ẹnì kan já bọ́ látorí rẹ̀.”​—DIUTARÓNÓMÌ 22:8.

MÁ ṢE MÁA BÍNÚ JÙ.

“Ẹni tí kì í tètè bínú ní ìjìnlẹ̀ òye, Àmọ́ ẹni tí kò ní sùúrù ń fi ìwà òmùgọ̀ rẹ̀ hàn.”​—ÒWE 14:29.

MÁ ṢE MÁA JẸUN JÙ.

‘Má ṣe wà lára àwọn tó ń jẹ àjẹkì.’​—ÒWE 23:20.