Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

OHUN TÓ Ń FÚNNI LÁYỌ̀

Ara Líle àti Ìfaradà

Ara Líle àti Ìfaradà

ÀÌSÀN TÓ LE KOKO TÀBÍ ÀÀBỌ̀ ARA MÁA Ń FAYÉ SÚNI. Ọkùnrin kan wà tó ń jẹ́ Ulf, koko ni ara rẹ̀ le tẹ́lẹ̀, àmọ́ ṣàdédé ló dùbúlẹ̀ àìsàn, kò sì lè rìn mọ́. Ó sọ pé: ‘Ìbànújẹ́ dorí mi kodò. Mi ò lokun mọ́, mi ò sì ní ìgboyà mọ́, ńṣe ló dà bíi pé mo ti kú.’

Ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Ulf jẹ́ ká rí i pé kò sẹ́nì kankan tó lè sọ pé òun lágbára lórí ìlera òun. Síbẹ̀, a lè ṣe àwọn nǹkan kan tó lè dín àìsàn kù. Àmọ́ tá a bá pàpà wá ṣàìsàn ńkọ́? Ṣé ìyẹn wá túmọ̀ sí pé a kò lè láyọ̀ mọ́? Rárá o. A máa rí ìdí tá a fi sọ bẹ́ẹ̀. Àmọ́, ẹ jẹ́ ká kọ́kọ́ gbé àwọn ìlànà kan yẹ̀ wò, tó máa jẹ́ ká ní ìlera tó dára.

JẸ́ “ONÍWỌ̀NTÚNWỌ̀NSÌ NÍNÚ ÌWÀ.” (1 Tímótì 3:​2, 11) Kéèyàn máá jẹun lájẹjù tàbí kó máa mutí lámujù máa ń ṣàkóbá fún ìlera ẹni, kódà ó máa ń dáni ní gbèsè! “Má ṣe wá wà lára àwọn tí ń mu wáìnì ní àmuyó kẹ́ri, lára àwọn tí ń jẹ ẹran ní àjẹkì. Nítorí ọ̀mùtípara àti alájẹkì yóò di òtòṣì.”​—Òwe 23:​20, 21.

MÁ ṢE SỌ ARA RẸ DI ẸLẸ́GBIN. “Ẹ jẹ́ kí a wẹ ara wa mọ́ kúrò nínú gbogbo ẹ̀gbin ti ẹran ara àti ti ẹ̀mí.” (2 Kọ́ríńtì 7:1) Àwọn tó ń fín tábà, tó ń fa sìgá, tó ń mutí lámujù tàbí tó ń lo oògùn nílòkulò ń sọ ara wọn di ẹlẹ́gbin. Bí àpẹẹrẹ, àjọ kan lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà tó ń rí sí béèyàn ṣe lè ṣèkáwọ́ àrùn àti béèyàn ṣe lè dènà rẹ̀ (U.S. Centers for Disease Control and Prevention) sọ pé sìgá mímu máa ń “fa àrùn, ó sì lè sọni di aláàbọ̀ ara, ṣàṣà sì ni ẹ̀yà ara tí kì í ṣàkóbá fún.”

MÁA WO ARA RẸ ÀTI Ẹ̀MÍ RẸ BÍ Ẹ̀BÙN TÓ ṢEYEBÍYE. “Nípasẹ̀ [Ọlọ́run] ni àwa ní ìwàláàyè, tí a ń rìn, tí a sì wà.” (Ìṣe 17:28) Tó o bá mọyì ohun tí Bíbélì sọ yìí, o kò ní máa fi ẹ̀mí ara rẹ wewu yálà níbi iṣẹ́, tó o bá ń wa mọ́tò, tàbí tó o bá ń ṣe eré ìnàjú. Kò yẹ kéèyàn torí ìgbádùn ráńpẹ́ sọ ara rẹ̀ di aláàbọ̀ ara!

GBÉ ÈRÒ ÒDÌ KÚRÒ LỌ́KÀN. Ohun tá a bá gbé sọ́kàn la sábà máa ń hù níwà. Torí náà, má ṣe fi àníyàn ṣe ara rẹ léṣe, yẹra fún ìbínú òdì, ìlara àtàwọn èrò òdì míì. Sáàmù 37:8 sọ pé: “Jáwọ́ nínú ìbínú, kí o sì fi ìhónú sílẹ̀.” Mátíù 6:34 náà tún sọ pé: “Ẹ má ṣàníyàn láé nípa ọ̀la, nítorí ọ̀la yóò ní àwọn àníyàn tirẹ̀.”

OHUN TÓ DÁRA NI KÓ O MÁA RÒ. Òwe 14:30 sọ pé: “Ọkàn-àyà píparọ́rọ́ ni ìwàláàyè ẹ̀dá alààyè ẹlẹ́ran ara.” Bíbélì tún sọ pé: “Ọkàn-àyà tí ó kún fún ìdùnnú ń ṣe rere gẹ́gẹ́ bí awonisàn.” (Òwe 17:22) Ọ̀rọ̀ yẹn sì bá ẹ̀kọ́ sáyẹ́ǹsì mu torí pé dókítà kan ní orílẹ̀-èdè Scotland sọ pé: “Tó o bá ń láyọ̀, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé lọ́jọ́ iwájú, o kò ní fi bẹ́ẹ̀ máa ṣàìsàn bíi tàwọn tí kì í láyọ̀.”

NÍ Ẹ̀MÍ ÌFARADÀ. Bíi ti Ulf tá a dárúkọ rẹ̀ lẹ́ẹ̀kan, ìṣòro tó ń bá wa fínra lè jẹ́ èyí tó gba pé ká máa fara rọ́ ọ nìṣó. Síbẹ̀ a lè pinnu pé a máa fara dà á. Àwọn kan ti jẹ́ kí ìrẹ̀wẹ̀sì bo àwọn mọ́lẹ̀, ìyẹn sì mú kí ìṣòro wọn burú sí i. Òwe 24:10 sọ pé: “Ìwọ ha ti jẹ́ kí ìrẹ̀wẹ̀sì bá ọ ní ọjọ́ wàhálà bí? Agbára rẹ yóò kéré jọjọ.”

Àmọ́ ní ti àwọn míì, wọ́n kọ́kọ́ sorí kọ́, nígbà tó yá wọ́n ṣọkàn akin, wọ́n sì gbé ara wọn ró. Wọ́n gba ipò tí wọ́n wà, wọ́n tún wá bí wọ́n ṣe máa fara dà á. Ohun tí Ulf ṣe nìyẹn. Ó sọ pé, lẹ́yìn ọ̀pọ̀ àdúrà àti ạ̀sàrò lórí àwọn ọ̀rọ̀ ìṣírí tó wà nínú Bíbélì, òun “bẹ̀rẹ̀ sí í rí àwọn àǹfààní tí òun ní dípò àwọn ìṣòro òun.” Àti pé bíi ti àwọn míì tó ní ìṣòro tó lágbára, ipò òun jẹ́ kí òun túbọ̀ kọ́ láti jẹ́ oníyọ̀ọ́nú àti aláàánú, èyí ló mú kí òun máa wàásù ọ̀rọ̀ ìtùnú tó wà nínú Bíbélì fún àwọn míì.

Ẹlòmíì tó tún kojú ìṣòro tó burú jáì ni ọkunrin kan tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Steve. Nígbà tó wà ní ọmọ ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún [15], ó fara pa nínú jàǹbá ọkọ̀, ó sì yarọ láti ọrùn dé ẹsẹ̀. Nígbà tó fi máa pé ọmọ ọdún méjìdínlógún [18], ọwọ́ rẹ̀ méjèèjì ti ṣeé gbé. Lẹ́yìn náà, ó lọ sí yunifásítì, ibẹ̀ ló ti bẹ̀rẹ̀ sí í gbé ìgbé ayé tí kò dára, ó ń lo oògùn olóró, ó ń mutí, ó sì ń ṣe ìṣekúṣe. Ó ti ro ara rẹ̀ pin pátápátá. Àmọ́ lọ́jọ́ kan, ó bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, èyí tún ayé rẹ̀ ṣe, ó sì jáwọ́ nínú àwọn ìwà burúkú tó ń hù. Ó sọ pé: “Ìgbésí ayé tí kò nítumọ̀ ni mò ń gbé tẹ́lẹ̀, àmọ́ ní báyìí, ayé mi ti dára. Mo ní àlàáfíà àti ayọ̀, ọkàn mi sì balẹ̀.”

Ohun tí Steve àti Ulf sọ rán wa létí ọ̀rọ̀ tó wà nínú Sáàmù 19:​7, 8 tó sọ pé: “Òfin Jèhófà pé, ó ń mú ọkàn padà wá. . . . Àwọn àṣẹ ìtọ́ni láti ọ̀dọ̀ Jèhófà dúró ṣánṣán, wọ́n ń mú ọkàn-àyà yọ̀; àṣẹ Jèhófà mọ́, ó ń mú kí ojú mọ́lẹ̀.”