Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Tí Ọkọ Tàbí Aya Kan Bá Ń Wo Àwòrán Ìṣekúṣe

Tí Ọkọ Tàbí Aya Kan Bá Ń Wo Àwòrán Ìṣekúṣe
  • “Ó dà bíi pé ọkọ mi ti ṣe àgbèrè léraléra.”

  • “Ojú tì mí, ó dà bíi pé mi ò lẹ́wà, mi ò sì já mọ́ nǹkan kan.”

  • “Mi ò sọ ohun tó ń ṣẹlẹ̀ fún ẹnì kankan, ńṣe ni mò ń pa á mọ́ra.”

  • “Ó dà bíi pé Jèhófà ò rí tèmi rò.”

Àwọn ọ̀rọ̀ tó wà lókè yìí jẹ́ ká rí bí ẹ̀dùn ọkàn tí ìyàwó kan máa ń ní ṣe pọ̀ tó, tọ́kọ ẹ̀ bá wo àwòrán tàbí fíìmù ìṣekúṣe. Tó bá sì jẹ́ pé ọkọ náà ti ń ṣe bẹ́ẹ̀ níkọ̀kọ̀ fún ọ̀pọ̀ oṣù tàbí ọ̀pọ̀ ọdún, ó lè máa rò pé òun ò ní lè fọkàn tán ọkọ òun mọ́. Ìyàwó kan sọ pé: “Àṣé mi ò mọ ọkọ mi dáadáa. Àbí àwọn nǹkan míì wà tó ń fi pa mọ́ fún mi ni?”

A dìídì ṣe àpilẹ̀kọ yìí fún ìyàwó tí ọkọ ẹ̀ máa ń wo àwòrán tàbí fíìmù ìṣekúṣe. a A máa sọ̀rọ̀ nípa àwọn ìlànà Bíbélì tó máa jẹ́ kára tu obìnrin náà, tó máa jẹ́ kó dá a lójú pé Jèhófà máa ran òun lọ́wọ́, táá jẹ́ kọ́kàn ẹ̀ balẹ̀, tí ò sì ní jẹ́ kó fi Jèhófà sílẹ̀. b

OHUN TÓ O LÈ ṢE TÍ ẸNÌ KEJÌ Ẹ BÁ Ń WO ÀWÒRÁN ÌṢEKÚṢE

Bó tiẹ̀ jẹ́ pé o ò lè darí gbogbo nǹkan tí ọkọ ẹ bá ń ṣe, àwọn nǹkan kan wà tó o lè ṣe táá jẹ́ kọ́kàn ẹ túbọ̀ balẹ̀. Jẹ́ ká wo àwọn nǹkan náà.

Má ṣe máa dá ara ẹ lẹ́bi. Tí ọkọ kan bá ń wo àwòrán ìṣekúṣe, ìyàwó ẹ̀ lè rò pé ẹ̀bi òun ni. Alice c ní tiẹ̀ rò pé òun ò rẹwà tó lójú ọkọ òun. Ó sọ pé: ‘Kí ló dé tí ọkọ mi fi máa ń wo àwọn obìnrin míì dípò mi?’ Àwọn ìyàwó kan máa ń dá ara wọn lẹ́bi torí wọ́n rò pé àwọn ló ń jẹ́ kí ìṣòro náà burú sí i. Danielle sọ pé, “Torí pé ọkọ mi ṣì máa ń wo àwòrán ìṣekúṣe, inú máa ń bí mi gan-an, ìyẹn sì jẹ́ kí n máa rò pé èmi ni mo fẹ́ fọwọ́ ara mi da ìgbéyàwó wa rú.”

Tó bá jẹ́ pé bọ́rọ̀ tìẹ náà ṣe rí nìyẹn, mọ̀ pé Jèhófà ò ní sọ pé ìwọ lo fà á tí ọkọ ẹ fi ń wo àwòrán ìṣekúṣe. Jémíìsì 1:14 sọ pé: “Àdánwò máa ń dé bá kálukú nígbà tí ìfẹ́ ọkàn rẹ̀ bá fà á mọ́ra, tó sì tàn án jẹ.” (Róòmù 14:12; Fílí. 2:12) Kàkà kí Jèhófà dá ẹ lẹ́bi pé ìwọ lo fà á, ó máa mọyì bó o ṣe jẹ́ adúróṣinṣin sí òun.​—2 Kíró. 16:9.

Yàtọ̀ síyẹn, ọkàn ẹ máa balẹ̀ tó o bá mọ̀ pé kì í ṣe torí pé o ò rẹwà lọkọ ẹ ṣe ń wo àwòrán ìṣekúṣe. Àwọn tó ń ṣàlàyé nípa àwòrán ìṣekúṣe sọ pé, kò sí obìnrin kankan tó lè tẹ́ àwọn tó ń wo àwòrán ìṣekúṣe lọ́rùn.

Má da ara ẹ láàmú jù. Catherine sọ pé ohun tóun máa ń rò ní gbogbo ìgbà ni pé ọkọ òun máa ń wo àwòrán ìṣekúṣe. Frances sọ pé: “Ara mi kì í balẹ̀ tí mi ò bá mọ ibi tí ọkọ mi wà. Ńṣe lọkàn mi máa ń kó sókè jálẹ̀ ọjọ́ yẹn.” Àwọn ìyàwó kan sọ pé ojú máa ń ti àwọn táwọn bá wà lọ́dọ̀ àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin tó mọ ìṣòro tọ́kọ àwọn ní. Àwọn ìyàwó míì sì sọ pé ó ń ṣe àwọn bíi pé àwọn dá wà torí wọ́n rò pé kò sẹ́ni tọ́rọ̀ àwọn yé.

Kò burú tó o bá nírú èrò yìí. Àmọ́ tó o bá ń ronú nípa ẹ̀ ṣáá, inú ẹ á túbọ̀ máa bà jẹ́. Kàkà bẹ́ẹ̀, máa ṣe ohun táá jẹ́ kó o túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà. Tó o bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, á jẹ́ kó o lè fara dà á.​—Sm. 62:2; Éfé. 6:10.

Wàá rí i pé ó máa ṣe ẹ́ láǹfààní tó o bá kẹ́kọ̀ọ́ jinlẹ̀ nípa àwọn obìnrin inú Bíbélì tí wọ́n ní ẹ̀dùn ọkàn, àmọ́ tí Jèhófà tù nínú nígbà tí wọ́n gbàdúrà sí i. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé kì í ṣe gbogbo ìgbà ni Jèhófà máa ń mú ìṣòro náà kúrò, ó máa ń jẹ́ kọ́kàn wọn balẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, Bíbélì sọ pé inú Hánà “bà jẹ́ gan-an” nítorí ìṣòro tó ní. Síbẹ̀, lẹ́yìn tó fi ‘ọ̀pọ̀ àkókò gbàdúrà níwájú Jèhófà,’ ọkàn ẹ̀ balẹ̀ pẹ̀sẹ̀, bó tiẹ̀ jẹ́ pé kò mọ ibi tí ọ̀rọ̀ náà máa já sí.​—1 Sám. 1:10, 12, 18; 2 Kọ́r. 1:3, 4.

Tó bá pọn dandan, tọkọtaya kan lè ní káwọn alàgbà ran àwọn lọ́wọ́

Ní káwọn alàgbà ràn ẹ́ lọ́wọ́. Bíbélì sọ pé wọ́n dà bí “ibi ààbò kúrò lọ́wọ́ ẹ̀fúùfù, ibi ìlùmọ́ kúrò lọ́wọ́ ìjì òjò.” (Àìsá. 32:2, àlàyé ìsàlẹ̀) Kódà, wọ́n tiẹ̀ lè mọ arábìnrin kan tó o lè sọ bọ́rọ̀ ṣe rí lára ẹ fún, tó sì máa tù ẹ́ nínú.​—Òwe 17:17.

ṢÉ WÀÁ RAN ỌKỌ Ẹ LỌ́WỌ́?

Ṣé o lè ran ọkọ ẹ lọ́wọ́ kó lè jáwọ́ nínú wíwo àwòrán tàbí fíìmù ìṣekúṣe tó ti mọ́ ọn lára? O lè ṣe bẹ́ẹ̀. Bíbélì sọ pé “ẹni méjì sàn ju ẹnì kan lọ” tá a bá fẹ́ yanjú ìṣòro kan tàbí tá a bá fẹ́ borí ọ̀tá kan tó lágbára jù wá lọ. (Oníw. 4:9-12) Ìwádìí fi hàn pé tí tọkọtaya bá jọ ṣiṣẹ́ pa pọ̀ kí ọkọ lè jáwọ́ nínú wíwo àwòrán ìṣekúṣe tó ti mọ́ ọn lára, àbájáde ẹ̀ máa ń dáa, wọ́n á sì tún pa dà fọkàn tán ara wọn.

Àmọ́, ọwọ́ ọkọ ẹ ló wà bóyá ó ti pinnu láti jáwọ́ nínú ìwà burúkú yìí. Ṣé ó ti bẹ Jèhófà pé kó jẹ́ kóun jáwọ́, ṣé ó sì ti sọ fáwọn alàgbà pé kí wọ́n ran òun lọ́wọ́? (2 Kọ́r. 4:7; Jém. 5:14, 15) Ṣé ó ti mọ bó ṣe máa yẹra fáwọn nǹkan tó tún lè mú kó wo àwòrán ìṣekúṣe, irú bíi kó má máa lo àkókò tó pọ̀ lórí fóònù àtàwọn nǹkan míì tó lè mú kó fẹ́ wò ó? (Òwe 27:12) Ṣé ọkọ ẹ ṣe tán láti gba ìmọ̀ràn tó o fún un, ṣé kì í sì í fi nǹkan kan pa mọ́ fún ẹ? Tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, wàá lè ràn án lọ́wọ́.

Báwo lo ṣe máa ràn án lọ́wọ́? Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ kan. Tọkọtaya ni Felicia àti Ethan, Ethan ti ń wo àwòrán ìṣekúṣe láti kékeré, ó sì ti mọ́ ọn lára. Felicia kì í kan ọkọ ẹ̀ lábùkù nítorí ẹ̀, ìyẹn jẹ́ kó rọrùn fún ọkọ ẹ̀ láti sọ fún un tó bá ti ń wù ú kó wo àwòrán ìṣekúṣe. Ethan sọ pé: “Mi ò kì í fi nǹkan kan pa mọ́ fún ìyàwó mi. Ó gbà mí nímọ̀ràn kí n lè mọ ohun tí màá ṣe kí n má bàa pa dà wo àwòrán ìṣekúṣe, ó sì máa ń bi mí pé báwo ni mo ṣe ń ṣe sí. Ó tún ràn mí lọ́wọ́ kí n lè dín iye àkókò tí mò ń lò lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì kù àti pé ibi táwọn èèyàn bá wà ni kí n ti máa lò ó.” Ó dun Felicia gan-an nígbà tó mọ̀ pé ó máa ń wu ọkọ òun láti wo àwòrán ìṣekúṣe. Àmọ́, ó sọ pé: “Bí mo ṣe máa ń bínú sí i, tó sì máa ń dùn mí ò jẹ́ kó lè jáwọ́ nínú ìwà burúkú náà. Lẹ́yìn tá a ti sọ̀rọ̀ nípa ohun tó lè ṣe, òun náà wá ń ṣe ohun tí ò ní jẹ́ kí inú bí mi mọ́.”

Yàtọ̀ sí pé irú ìjíròrò yìí máa ran ọkọ yẹn lọ́wọ́ láti jáwọ́ nínú wíwo àwòrán ìṣekúṣe, ó tún máa jẹ́ kí ìyàwó ẹ̀ pa dà fọkàn tán an. Òótọ́ kan ni pé tí ọkọ kan bá sọ fún ìyàwó ẹ̀ pé ó ń wu òun láti wo ohun tí ò dáa, tó sì máa ń sọ ibi tó ń lọ àtohun tó ń ṣe, ìyàwó ẹ̀ máa fọkàn tán an torí pé kò fi ohunkóhun pa mọ̀ fún un.

Ṣé o gbà pé ìwọ náà lè ran ọkọ ẹ lọ́wọ́ bíi ti obìnrin tá a sọ yìí? Tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, ẹ ò ṣe jíròrò àpilẹ̀kọ yìí pa pọ̀? Wàá rí i pé á ṣe gbogbo ohun tó lè ṣe kó lè jáwọ́ nínú wíwo àwòrán ìṣekúṣe, á sì máa ṣe àwọn nǹkan tó máa jẹ́ kó o fọkàn tán an. Dípò kó bínú tó o bá gbà á nímọ̀ràn lórí ìṣòro náà, ńṣe ló yẹ kó gbìyànjú kó lè mọ bí ọ̀rọ̀ náà ṣe rí lára ẹ. Má jẹ́ kó sú ẹ láti máa ran ọkọ ẹ lọ́wọ́ bó ṣe ń sapá láti jáwọ́ nínú wíwo ìwòkuwò. Ìyẹn á jẹ́ kí ọkọ ẹ rí i pé o ṣì lè fọkàn tán òun. Torí náà, ó yẹ kẹ́yin méjèèjì mọ ohun tó máa ń mú káwọn èèyàn wo àwòrán ìṣekúṣe àti bí ẹ ṣe lè borí ìṣòro náà. d

Tí ẹ̀rù bá ń bà ẹ́ pé kí ọ̀rọ̀ náà má lọ di ariwo láàárín ìwọ àti ọkọ ẹ, o lè ní kí alàgbà kan tẹ́ ẹ fọkàn tán wà lọ́dọ̀ yín nígbà tẹ́ ẹ bá fẹ́ jíròrò ọ̀rọ̀ náà. Rántí pé tí ọkọ ẹ bá tiẹ̀ ti jáwọ́ nínú wíwo àwòrán ìṣekúṣe, ó lè gba àkókò díẹ̀ kó o tó lè fọkàn tán an. Torí náà, má jẹ́ kó sú ẹ. Máa wo àwọn àyípadà kéékèèké tí ọkọ ẹ ń ṣe kí àárín yín lè gún régé. Tẹ́ ẹ bá ní sùúrù, ẹ̀ẹ́ rí i pé díẹ̀díẹ̀, àjọṣe yín á túbọ̀ máa lágbára.​—Oníw. 7:8; 1 Kọ́r. 13:4.

TÍ ỌKỌ Ẹ Ò BÁ JÁWỌ́ ŃKỌ́?

Tí ọkọ ẹ bá tún wo àwòrán ìṣekúṣe lẹ́yìn tó ti jáwọ́ fún àkókò kan, ṣé ìyẹn wá túmọ̀ sí pé kò ronú pìwà dà tàbí pé ọ̀rọ̀ ẹ̀ ò látùnṣe? Ó lè má jẹ́ bẹ́ẹ̀, pàápàá tó bá jẹ́ pé ó ti mọ́ ọn lára. Ó lè má lè jáwọ́ mọ́, kó sì máa bá a yí títí lọ. Ó tún lè wò ó lẹ́yìn tó ti jáwọ́ nínú ẹ̀ fún ọ̀pọ̀ ọdún. Tí kò bá tún fẹ́ wò ó lọ́jọ́ iwájú, ó gbọ́dọ̀ máa kíyè sára gan-an, kó sì máa ṣe gbogbo ohun tó lè ṣe láti dènà ìwà náà, kódà tó bá rò pé òun ti borí ẹ̀. (Òwe 28:14; Mát. 5:29; 1 Kọ́r. 10:12) Ó máa gba pé kó di tuntun nínú “agbára tó ń darí ìrònú” ẹ̀, kó sì mọ bóun ṣe máa “kórìíra ohun tó burú,” ìyẹn sì kan wíwo àwòrán ìṣekúṣe àtàwọn nǹkan míì tó jọ ọ́, irú bíi fífi ọwọ́ pa nǹkan ọmọkùnrin ẹ̀. (Éfé. 4:23; Sm. 97:10; Róòmù 12:9) Ṣé ó ṣe tán láti ṣe àwọn nǹkan yìí? Tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, ọ̀rọ̀ ẹ̀ ò kọjá àtúnṣe, ó ṣì lè jáwọ́ pátápátá. e

Túbọ̀ máa sún mọ́ Jèhófà

Tó bá jẹ́ pé kò wu ọkọ ẹ láti borí ìṣòro yìí ńkọ́? Ó lè jẹ́ kó o máa kanra, kó o máa rò pé ọkọ ẹ dalẹ̀ ẹ, ó sì dójú tì ẹ́. Fi gbogbo ọ̀rọ̀ náà lé Jèhófà lọ́wọ́, ìyẹn máa jẹ́ kọ́kàn ẹ balẹ̀. (1 Pét. 5:7) Túbọ̀ máa ṣe ohun tó máa jẹ́ kó o sún mọ́ Jèhófà, máa dá kẹ́kọ̀ọ́, máa gbàdúrà, kó o sì máa ṣàṣàrò. Tó o bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, mọ̀ dájú pé Jèhófà náà máa sún mọ́ ẹ. Àìsáyà 57:15 sọ pé, Jèhófà ń gbé pẹ̀lú àwọn “tí a tẹ̀ rẹ́, tí wọ́n sì rẹ̀wẹ̀sì,” kó lè ràn wọ́n lọ́wọ́, kí wọ́n sì pa dà máa láyọ̀. Máa ṣe gbogbo ohun tó o lè ṣe láti máa jẹ́ olóòótọ́ nìṣó, ní kí àwọn alàgbà ràn ẹ́ lọ́wọ́, kó o sì máa retí pé lọ́jọ́ iwájú, ọkọ ẹ máa ṣe àyípadà tó yẹ.​—Róòmù 2:4; 2 Pét. 3:9.

a Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa sọ pé ọkọ ló ń wo àwòrán ìṣekúṣe. Àmọ́, ọ̀pọ̀ lára ìlànà Bíbélì tá a sọ nínú àpilẹ̀kọ yìí máa ṣèrànwọ́ fún ọkọ kan tí ìyàwó ẹ̀ ń wo àwòrán ìṣekúṣe.

b Tí ọkọ tàbí ìyàwó kan bá ń wo àwòrán ìṣekúṣe, ìlànà Ìwé Mímọ́ ò sọ pé kí wọ́n kọ ara wọn sílẹ̀ nítorí ẹ̀.​—Mát. 19:9.

c A ti yí àwọn orúkọ náà pa dà.

d Ẹ máa rí àwọn àpilẹ̀kọ tó máa ràn yín lọ́wọ́ lórí ìkànnì jw.org àti nínú àwọn ìwé wa. Bí àpẹẹrẹ, wo àwọn àpilẹ̀kọ yìí “Wíwo Àwòrán Ìṣekúṣe Lè Tú Ìgbéyàwó Rẹ Ká” lórí jw.org; “O Lè Borí Ìdẹwò!” nínú Ilé Ìṣọ́, April 1, 2014, ojú ìwé 10-12 àti “Àwòrán Oníhòòhò​—Ó Léwu Àbí Kò Léwu?” nínú Ilé Ìṣọ́, August 1, 2013, ojú ìwé 3-7.

e Torí pé kì í rọrùn fún àwọn tó ń wo àwòrán ìṣekúṣe láti tètè jáwọ́, àwọn tọkọtaya kan ti pinnu láti lọ gba ìtọ́jú lọ́dọ̀ dókítà yàtọ̀ sí ìrànlọ́wọ́ tí wọ́n gbà lọ́dọ̀ àwọn alàgbà.