Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

OJÚ ÌWÒYE BÍBÉLÌ

Ìṣẹ̀dá

Ìṣẹ̀dá

Ṣé ọjọ́ oníwákàtí mẹ́rìnlélógún ni ọjọ́ mẹ́fà tí Ọlọ́run fi dá gbogbo nǹkan gẹ́gẹ́ báwọn kan ṣe sọ?

“Ní ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀, Ọlọ́run dá ọ̀run àti ilẹ̀ ayé.”—Jẹ́nẹ́sísì 1:1.

OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ

Ọlọ́run ti dá ọ̀run àti ayé tipẹ́tipẹ́. Jẹ́nẹ́sísì 1:1 tiẹ̀ pè é ní “ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀” tàbí àtètèkọ́ṣe. Àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ òde òní gbà pé àgbàyé wa yìí ní ìbẹ̀rẹ̀. Ìwádìí kan táwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ ṣe lẹ́nu àìpẹ́ yìí sọ pé ó tó bílíọ́nù mẹ́rìnlá ọdún tí àgbáyé yìí ti wà.

Bíbélì náà sọ pé ọjọ́ “mẹ́fà” ni Ọlọ́run fi dá ayé àti ọ̀run. Àmọ́ kò sọ pé ó jẹ́ ọjọ́ oníwákàtí mẹ́rìnlélógún. (Jẹ́nẹ́sísì 1:31) Tí Bíbélì bá lo ọ̀rọ̀ náà “ọjọ́,” ó máa ń tọ́ka sí oríṣiríṣi àkókò tí ó gùn jura lọ. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tó ń sọ̀rọ̀ nípa gbogbo ọjọ́ tí Ọlọ́run fi ṣẹ̀dá àwọn nǹkan, ó sọ pé “ní ọjọ́ tí Jèhófà Ọlọ́run ṣe ilẹ̀ ayé àti ọ̀run.” (Jẹ́nẹ́sísì 2:4) Ó hàn gbangba pé ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọdún ni “ọjọ́” ìṣẹ̀dá tí Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀.—Sáàmù 90:4.

ÌDÍ TÍ Ọ̀RỌ̀ YÌÍ FI ṢE PÀTÀKÌ

Èrò tí kò tọ́ táwọn kan ní pé ọjọ́ oníwákàtí mẹ́rìnlélógún ni ọjọ́ mẹ́fà tí Ọlọ́run fi dá gbogbo nǹkan lè mú kó má wù ẹ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Àmọ́, tó bá jẹ́ òótọ́ ni ìtàn nípa ìṣẹ̀dá tó wà nínú Bíbélì, a jẹ́ pé o máa jàǹfààní látinú ibú “ọgbọ́n tí ó gbéṣẹ́” tó wà nínú rẹ̀.”—Òwe 3:21.

Ṣé ohun kan tí Ọlọ́run dá níbẹ̀rẹ̀ ló para dà di ọ̀pọ̀ ohun alàyè tó wà láyé?

Ọlọ́run sọ pé: “Kí ilẹ̀ ayé mú alààyè ọkàn jáde ní irú tiwọn.”—Jẹ́nẹ́sísì 1:24.

OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ

Kì í ṣe pé Ọlọ́run kọ́kọ́ dá ohun ṣákálá kan, tó sì wá jẹ́ kó máa para dà di oríṣiríṣi àwọn nǹkan mìíràn tó lágbára. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ló dá “irú” àwọn ewéko àti ẹranko pàtó kan tó jẹ́ àgbàyanu. Kálukú wọn sì bẹ̀rẹ̀ sí í mú “irú tiwọn” jáde. (Jẹ́nẹ́sísì 1:11, 21, 24) Ohun tí Ọlọ́run fi lọ́lẹ̀ yìí ló ṣì ń bá a nìṣó títí dòní. Ìyẹn sì ló mú kí ayé kún fún àwọn ohun alààyè ní “irú” tiwọn, gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run ṣe dá wọn ní ìbẹ̀rẹ̀.—Sáàmù 89:11.

Bíbélì kò sọ bí oríṣi àwọn ohun alàyè tó lè ti ara irú ohun alàyè pàtó kan jáde ṣe pọ̀ tó. Irú bí ìgbà tí ẹranko kan bá gun ẹ̀yà ẹranko míì, tó sì wá bí ọmọ tó jẹ́ apá kan ẹ̀yà tirẹ̀ àti apá kan ẹ̀yà tó gùn ún, tí gbogbo wọn sì jọ dàgbà pa pọ̀. Èrò àwọn kan ni pé ẹfolúṣọ̀n ló mú kírú nǹkan bẹ́ẹ̀ ṣeé ṣe. Àmọ́ irú nǹkan báyìí kì í mú ẹ̀dá alààyè tuntun míì jáde. Ìwádìí táwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ ń ṣe lóde òní fi hàn pé ìwọ̀nba díẹ̀ ni ohun tó yàtọ̀ lára àwọn ìṣẹ̀dà bí ewéko àtàwọn ẹranko látayébáyé tí wọ́n ti wà.

ÌDÍ TÍ Ọ̀RỌ̀ YÌÍ FI ṢE PÀTÀKÌ

Bí ohun tí Bíbélì sọ nípa “irú” àwọn ohun alààyè ṣe bá ohun táwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ ṣàwárí mú fi hàn pé àwọn ohun tó sọ nípa àwọn nǹkan míì bí ìtàn àti àsọtẹ́lẹ̀ ṣeé gbára lé.

Ibo ni Ọlọ́run ti rí àwọn ohun tó fi dá àgbáyé yìí?

“Ọwọ́ mi ni ó na ọ̀run.”—Aísáyà 45:12.

OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ

Ọlọ́run ní agbára tàbí okun tó kà màmà. (Jóòbù 37:23) Ọ̀rọ̀ yìí gbàfiyèsí gan-an, torí pé àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ ti rí i pé èèyàn lè fi ohun àmúṣagbára gbé ìwàláàyè ró. Bíbélì sọ pé Ọlọ́run fúnra rẹ̀ ni Orísun “ọ̀pọ̀ yanturu okun” tó fi dá àgbáyé yìí. (Aísáyà 40:26) Ọlọ́run ṣèlérí pé òun máa lo agbára òun láti mú kí àwọn ohun alààyè tó ṣẹ̀dá máa wà nìṣó. Nígbà tí Bíbélì ń sọ̀rọ̀ nípa oòrùn, òṣùpá àtàwọn ìràwọ̀, ó ní: “[Ọlọ́run] mú kí wọ́n dúró títí láé, àní fún àkókò tí ó lọ kánrin.”—Sáàmù 148:3-6.

ÌDÍ TÍ Ọ̀RỌ̀ YÌÍ FI ṢE PÀTÀKÌ

Onímọ̀ ìjìnlẹ̀ nípa sánmà kan tó ń jẹ́ Allan Sandage sọ nígbà kan pé: “Ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ kò lè dáhùn àwọn ìbéèrè tó jinlẹ̀ gan-an. Tó bá ti di ọ̀rọ̀ pé èèyàn ń béèrè ìdí tí nǹkan kan fi wà níbi tí kò ti yẹ kó wà, ìyẹn ti kọjá ohun tí ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ lè dáhùn.” Yàtọ̀ sí pé Bíbélì ṣàlàyé ọ̀rọ̀ nípa ìṣẹ̀dá lọ́nà tó bá ohun tí ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ ṣàwárí mu, ó tún dáhùn àwọn ìbéèrè tí ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ kò lè dáhùn, títí kan ìbéèrè bíi, kí nìdí tí Ọlọrun fi dá ayé àti àwa èèyàn? a

a Fún ìsọfúnni síwájú sí i, ka orí 3 nínú ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe é.