Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Ìròyìn

 

2016-05-19

SOUTH KOREA

Ìwà Ìrẹ́jẹ tí Ìjọba Ilẹ̀ South Korea Ń Hù Kò Tẹ́ Àwọn Èèyàn Kárí Ayé Lọ́rùn

Ìwé kan táwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣẹ̀ṣẹ̀ gbé jáde ṣàlàyé ìwà ìrẹ́jẹ tó mú kí wọ́n fí ọgọ́rọ̀ọ̀rún àwọn ọ̀dọ́kùnrin sẹ́wọ̀n torí wọ́n kọ̀ láti ṣiṣẹ́ ológun, bẹ́ẹ̀ ẹ̀rí ọkàn wọn ni kò jẹ́ kí wọ́n ṣe é.

2016-05-20

ORÍLẸ̀-ÈDÈ AMẸ́RÍKÀ

Fídíò Kékeré: Wọ́n Tún Ilé Ìwòran Stanley Ṣe

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó lé ní ẹgbẹ̀rún méjì yọ̀ǹda ara wọn láti ṣàtúnṣe tó kàmàmà sí Ilé Ìwòran Stanley tó jẹ́ ibi pàtàkì nílùú Jersey ní New Jersey.

2016-05-04

SOUTH KOREA

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Ṣe Àjọyọ̀ Ọgọ́rùn-ún Ọdún ní Korea

SEOUL, Korea—Oṣù pàtàkì ni November ọdún 2012 jẹ́ fún àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó lé ní ọ̀kẹ́ márùn-ún [100,000] ní orílẹ̀-èdè South Korea, torí oṣù náà ló pé ọgọ́rùn-ún ọdún tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti wà lórílẹ̀-èdè náà.

2016-05-04

Ilé Ẹjọ́ Ní Kí ìjọba Austria San Owó Máà-Bínú fún Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Ní September 25, ọdún 2012, Ilé Ẹjọ́ Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn ti Ilẹ̀ Yúróòpù tó wà ní ìlú Strasbourg, ní orílẹ̀-èdè Faransé dájọ́ pé ìjọba Austria jẹ̀bi ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn án pé ó ṣe ẹ̀tanú sí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà.

2016-05-04

UKRAINE

Ìdájọ́ Òdodo Borí Nílẹ̀ Ukraine

Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ Nílẹ̀ Ukraine fagi lé ìgbìyànjú àwọn kan tí wọ́n fẹ́ gba ilẹ̀ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà.