Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Ìtùnú àti Ojúlówó Ìrànlọ́wọ́ fún Àwọn Aláìsàn

Ìtùnú àti Ojúlówó Ìrànlọ́wọ́ fún Àwọn Aláìsàn

Àwọn tó ń ṣàìsàn tó le kìí pẹ́ ṣàníyàn, tó bá wá gba pé kí wọ́n lọ gbàtọ́jú nílé ìwòsàn, ńṣe ni ìdààmú ọkàn tí wọ́n ní sábà máa ń pọ̀ sí i. Ọ̀rọ̀ yìí ò yàtọ̀ sóhun tí ìwé ìròyìn àtìgbàdégbà kan sọ, àwọn tó ń tọ́jú aláìsàn ló wà fún, ó sọ pé, “ìwádìí ti fi hàn pé àwọn ohun tó máa ń dá aláìsàn lára yá àtèyí tá á mú kí àjọṣe rẹ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run túbọ̀ dára sí i máa ń jẹ́ kí ara wọn tètè kọ́fẹ.” *

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń fi Bíbélì tu àwọn ará wọn tó wà nílé ìwòsàn nínú, wọ́n sì máa ń fún wọn ní ojúlówó ìrànlọ́wọ́, kí wọ́n lè dá wọn lára yá, kí àjọṣe wọn pẹ̀lú Ọlọ́run sì lè túbọ̀ dára sí i. Bí ẹnì kan nínú ìjọ bá ń ṣàìsàn, àwọn alàgbà ìjọ máa ń dìídì lọ sọ́dọ̀ ẹni yẹn. Tó bá wá jẹ́ pé ilé ìwòsàn kan tó jìnnà sílé ni wọ́n ti ń tójú aláìsàn kan tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà ńkọ́? Ní àwọn ìlú ńláńlá kárí ayé, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti ṣètò Ẹgbẹ́ Tó N Bẹ Àwọn Aláìsàn Wò (PVG). Àwọn alàgbà ìjọ tó wà nínú ẹgbẹ́ yìí máa ń lọ déédéé sí àwọn ilé ìwòsàn kí wọ́n lè ṣèrànwọ́ fún àwọn Ẹlẹ́rìí tó wà nílé ìwòsàn àtàwọn ìdílé wọn tó wá láti apá ibòmíì lórílẹ̀-èdè náà tàbí láti ilẹ̀ míì. Ó lé ní ẹgbẹ̀rún méjìdínlọ́gbọ̀n (28,000) àwọn tó yọ̀ǹda ara wọn láti ṣiṣẹ́ yìí, wọ́n sì wà nínú ẹgbẹ̀rún kan ó lé ọgọ́rùn-ún mẹ́sàn-án (1,900) Ẹgbẹ́ Tó Ń Bẹ Àwọn Aláìsàn Wò ní ilẹ̀ mẹ́fà ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀. *

Ìtùnú tẹ̀mí wo ni Ẹgbẹ́ Tó Ń Bẹ Àwọn Aláìsàn Wò ń fúnni?

Arákùnrin kan tó ń jẹ́ William, tó wà lára Ẹgbẹ́ Tó Ń Bẹ Àwọn Aláìsàn Wò sọ pé: “Ti pé mo kàn tiẹ̀ wà pẹ̀lú àwọn ará láti bá wọn sọ̀rọ̀ kí n sì tẹ́tí sí wọn ti mú kó ṣeé ṣe fún mi láti tu àwọn àtàwọn ará ilé wọn tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí nínú. Mo máa ń mú un dá wọn lójú pé Jèhófà Ọlọ́run mọ ohun tó ń ṣẹlẹ̀ sí wọn, ọ̀rọ̀ wọn sì jẹ ẹ́ lógún. Àwọn aláìsàn àti ìdílé wọn máa ń mọyì rẹ̀ téèyàn bá gbàdúrà nítorí wọn.”

Ọ̀pọ̀ ti sọ̀rọ̀ ìdúpẹ́ torí ìṣírí tí wọ́n rí gbà látinú ìbẹ̀wò tí Ẹgbẹ́ Tó Ń Bẹ Àwọn Aláìsàn Wò ṣe sọ́dọ̀ wọn. Ní orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, Ẹgbẹ́ Tó Ń Bẹ Àwọn Aláìsàn Wò tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ẹgbẹ̀rún méje (7,000) ló wà níbẹ̀, díẹ̀ lára ohun táwọn tí wọ́n bẹ̀ wò sọ rèé.

  • Priscilla sọ pé: “Ẹ ṣeun tẹ́ ẹ wá wo bàbá mi nílé ìwòsàn nígbà tẹ́ ẹ gbọ́ pó ní àrùn rọpárọsẹ̀. Inú wọn dùn gan-an torí bẹ́ ẹ ṣe ń bẹ̀ wọ́n wò! Ó yà wọ́n lẹ́nu pé irú ètò bẹ́ẹ̀ wà. Mo lérò pé bẹ́ ẹ ṣe wá ń bẹ̀ wọ́n wò ló mú kára wọn tètè yá.”

  • Ophilia, ọmọbìnrin aláìsàn kan tó kú, sọ fún aṣojú kan lára Ẹgbẹ́ Tó Ń Bẹ Àwọn Aláìsàn Wò pé: “Màmá mi ò jẹ́ gbàgbé bẹ́ ẹ ṣe ń bẹ̀ wọ́n wò! Wọ́n mọ̀ pé Jèhófà ló rán yín wá. Ẹ ṣeun torí bẹ́ ẹ ṣe fìfẹ́ bójú tó wọn.”

  • Lẹ́yìn tí aláìsàn kan gbọ́ pé ọjọ́ díẹ̀ ló kù kí òun lò láyé, ọkàn rẹ̀ dà rú, ìdààmú sì bá a. James, ọ̀kan lára Ẹgbẹ́ Tó Ń Bẹ Àwọn Aláìsàn Wò, dúró tì í, ó sì fi ọ̀rọ̀ Bíbélì tó wà nínú Fílípì 4:​6, 7 tù ú nínú. James sọ pé: “Nígbà tí mo lọ wò ó lọ́jọ́ kejì, bó ṣe ń ṣe ti yàtọ̀ pátápátá sí ti tẹ́lẹ̀. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àyẹ̀wò fi hàn pé àìsàn náà máa la ẹ̀mí lọ, ó dá a lójú pé Jèhófà máa ran òun lọ́wọ́, ìyẹn sì fún èmi gan-an níṣìírí!”

Ojúlówó ìrànlọ́wọ́ wo ni Ẹgbẹ́ Tó Ń Bẹ Àwọn Aláìsàn Wò máa ń ṣe fúnni?

Obìnrin kan tó ń jẹ́ Pauline, tí ọkọ rẹ̀ kú sí ilé ìwòsàn kan tó jìnnà sílé, sọ nínú lẹ́tà tó kọ pé: “Ẹ ṣeun gan-an fún ìrànlọ́wọ́ tẹ́ ẹ ṣe fún wa nígbà tí nǹkan tíì nira jù lọ nínú ìdílé wa. Mímọ̀ tá a mọ̀ pé ẹ máa wá bá wa nílé ìwòsàn ní ọ̀gànjọ́ òru, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ ní láti lọ síbi iṣẹ́ lọ́jọ́ kejì, tù wá nínú. Ẹ ṣeun tẹ́ ẹ ṣètò ibi tí gbogbo àwa mọ́kànlá sùn sí àti bẹ́ ò ṣe fi wá sílẹ̀ lẹ́sẹ̀ kan. Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà àti ètò rẹ̀ fún bí wọ́n ṣe pèsè irú ìrànlọ́wọ́ bẹ́ẹ̀ láti tù wá nínú.”

Jàǹbá mọ́tò ṣẹlẹ̀ sí Nicki, Gayle àti Robin ní nǹkan bí ọgọ́rùn-ún mẹ́ta (300) kìlómítà (ìyẹn máìlì 200) sí ilé wọn. Wọ́n fi ọ̀rọ̀ náà tó Carlos létí, ó wà lára Ẹgbẹ́ Tó Ń Bẹ Àwọn Aláìsàn Wò, ó sì lọ pàdé wọn nílé ìwòsàn nígbà tí wọ́n débẹ̀. Carlos sọ pé, “Mo bá wọn ṣe gbogbo ohun tó yẹ kí wọ́n ṣe, mo sì tún bá Nicki gbé ajá rẹ̀ kékeré dání kó lè wọlé lọ bá dókítà tó máa tọ́jú rẹ̀.” Lẹ́yìn náà, Curtis, tóun náà wà lára Ẹgbẹ́ Tó Ń Bẹ Àwọn Aláìsàn Wò, dé tòun ti ìyàwó rẹ̀. Wọ́n dúró sí ilé ìwòsàn náà títí tí àwọn ará ilé àwọn aláìsàn yìí fi dé ní wákàtí mélòó kan lẹ́yìn náà. Ẹnì kan tó kíyè sí wọn sọ pé: “Ara tu àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta torí àbójútó tí wọ́n rí gbà. Àmọ́ ńṣe ni gbogbo ìrànlọ́wọ́ tí Ẹgbẹ́ Tó Ń Bẹ Àwọn Aláìsàn Wò náà ṣe ya Robin, arábìnrin Nicki tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà lẹ́nu.”

^ ìpínrọ̀ 2 “Ohun Tá A Lè Ṣe Nípa Ìmọ̀lára Aláìsàn àti Àjọṣe Rẹ̀ Pẹ̀lú Ọlọ́run,” tá a tẹ̀ jáde nínú ìwé The Joint Commission Journal on Quality and Patient Safety, December 2003, Apá 29, No. 12, ojú ìwé 661.

^ ìpínrọ̀ 3 Bíi tàwọn alàgbà yòókù tí wọ́n jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà, àwọn tó ń bá Ẹgbẹ́ Tó Ń Bẹ Àwọn Aláìsàn Wò ṣiṣẹ́ tún máa ń ran ìjọ wọn lọ́wọ́ gẹ́gẹ́ bí olùṣọ́ àgùntàn tẹ̀mí, olùkọ́ àti oníwàásù. Wọn kì í gbowó torí gbogbo iṣẹ́ tí wọ́n ń ṣe yìí, àmọ́ wọ́n ń ṣe é tinútinú àti pẹ̀lú ìmúratán.​—1 Pétérù 5:2.