Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Àwọn Èèyàn Orílẹ̀-Èdè Estonia Mọyì “Iṣẹ́ Ńlá” Tá A Ṣe

Àwọn Èèyàn Orílẹ̀-Èdè Estonia Mọyì “Iṣẹ́ Ńlá” Tá A Ṣe

Bíbélì Ìwé Mímọ́ ní Ìtúmọ̀ Ayé Tuntun wà lára àwọn ìwé tó fakọ yọ jù lọ tí wọ́n mú, tí wọ́n sì fún ní Àmì Ẹ̀yẹ Ìwé Tó Dára Jù Lọ ní Orílẹ̀-Èdè Estonia lọ́dún 2014. Òun ló ṣe ipò kẹta nínú àwọn ìwé méjìdínlógún [18] tí wọ́n mú.

Obìnrin kan tó ń jẹ́ Kristiina Ross tó jẹ́ onímọ̀ èdè ní Institute of the Estonian Language ló fa Bíbélì tuntun yìí kalẹ̀ fún àmì ẹ̀yẹ náà. Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà mú Bíbélì tuntun yìí jáde ní August 8, 2014. Kristiina sọ pé Bíbélì Ìtúmọ̀ Ayé Tuntun yìí “rọrùn láti kà, ó sì gbádùn mọ́ni. Iṣẹ́ takuntakun tí àwọn tó túmọ̀ rẹ̀ ṣe ti ràn wá lọ́wọ́ gan-an nínú iṣẹ́ ìtumọ̀ èdè lórílẹ̀-èdè Estonia.” Ọ̀jọ̀gbọ́n kan nípa ìwé àti àṣà ní orílẹ̀-èdè Estonia tó ń jẹ́ Rein Veidemann sọ pé “iṣẹ́ ńlá” ni ìtumọ̀ Bíbélì tuntun tá a ṣe yìí.

Ọdún 1739 ni wọ́n kọ́kọ́ tẹ Bíbélì jáde lódindi ní èdè Estonia. Látìgbà yẹn ni wọ́n ti ń mú àwọn ìtumọ̀ Bíbélì míì jáde. Àmọ́, kí nìdí tí Bíbélì Ìtúmọ̀ Ayé Tuntun fi jẹ́ “iṣẹ́ ńlá”?

Ó péye. Nínú ẹ̀dá Bíbélì kan tó gbajúmọ̀ tí wọ́n tẹ̀ jáde ní èdè Estonia lọ́dún 1988, ó ju ìgbà ẹgbẹ̀rún mẹ́fà àti ọgọ́rùn-ún mẹ́jọ [6,800] lọ tí wọ́n túmọ̀ orúkọ Ọlọ́run, ìyẹn “Jehoova” (Jèhófà) nínú Ìwé Mímọ́ lédè Hébérù (Májẹ̀mú Láéláé). * Àmọ́, iye ìgbà tó fara hàn nínú Bíbélì Ìtúmọ̀ Ayé Tuntun ju ti Bíbélì yẹn lọ fíìfíì. Bíbélì Ìtúmọ̀ Ayé Tuntun lo orúkọ Ọlọ́run láwọn ibi tó yẹ bẹ́ẹ̀ nínú Ìwé Mímọ́ Kristẹni lédè Gíríìkì (Májẹ̀mú Tuntun).

Ó rọrùn láti lóye. Ǹjẹ́ a lè sọ pé Bíbélì Ìtúmọ̀ Ayé Tuntun péye, tó sì tún rọrùn láti kà? Olùtumọ̀ Bíbélì kan táwọn èèyàn bọ̀wọ̀ fún tó ń jẹ́ Toomas Paul sọ nínú ìwé ìròyìn Eesti Kirik (Ṣọ́ọ̀ṣì Orílẹ̀-èdè Estonia) pé: “Àṣeyọrí ńlá ni iṣẹ́ ìtumọ̀ Bíbélì Ìtúmọ̀ Ayé Tuntun, wọ́n túmọ̀ rẹ̀ lọ́nà tó rọrùn láti kà ní èdè Estonia. Ìgbà àkọ́kọ́ rèé tí wọ́n túmọ̀ Bíbélì lọ́nà yìí.”

Wọ́n ń jàǹfààní nínú iṣẹ́ ìtumọ̀ èdè Estonia

Ohun tó ṣàrà ọ̀tọ̀ ni àwọn èèyàn Estonia ṣe láti fi hàn pé wọ́n mọyì Bíbélì Ìtúmọ̀ Ayé Tuntun gan-an. Ilé iṣẹ́ rédíò ìjọba àpapọ̀ lórílẹ̀-èdè Estonia gbé ètò kan jáde lórí afẹ́fẹ́ nípa Bíbélì tuntun yìí, ogójì ìṣẹ́jú ni wọ́n fi ṣe ètò yìí. Kódà àwọn pásítọ̀ àtàwọn tó ń lọ ṣọ́ọ̀ṣì ní kí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà fún àwọn ní ẹ̀dà Bíbélì tuntun yìí. Ilé ẹ̀kọ́ pàtàkì kan ní Tallinn béèrè fún ogún [20] ẹ̀dà Bíbélì Ìtúmọ̀ Ayé Tuntun kí wọ́n lè máa lò ó nínú ọ̀kan lára àwọn kílásàsì wọn. Àwọn èèyàn lórílẹ̀-èdè Estonia fẹ́ràn ìwé kíkà gan-an, inú àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà náà sì dùn pé a fún wọn ní ìtumọ̀ Bíbélì tó péye tó sì rọrùn láti lóye. Òun ni ìwé tó dára jù lọ.

^ ìpínrọ̀ 5 Lẹ́yìn tí ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Ain Riistan tó jẹ́ ọ̀mọ̀wé ní Yunifásítì Tartu, ìyẹn New Testament Studies University of Tartu ti sọ bí àwọn èèyàn Estonia ṣe wá ń pe orúkọ Ọlọ́run, “Jehoova,” ó parí ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé: “Ohun tí mo rò ni pé orúkọ náà Jehoova bá a mu wẹ́kú lóde òní. Láìka ibi tí orúkọ náà ti ṣẹ̀ wá sí, ó ní . . . ìtumọ̀ pàtàkì tó máa wà láti ìran dé ìran. Jehoova ni orúkọ Ọlọ́run tó rán Ọmọ rẹ̀ wá sáyé láti wá rà wá pa dà.”