Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Wọ́n Lẹ Àmì Onígun Mẹ́ta Aláwọ̀ Pọ́pù Mọ́ Aṣọ Wọn

Wọ́n Lẹ Àmì Onígun Mẹ́ta Aláwọ̀ Pọ́pù Mọ́ Aṣọ Wọn

 Orílẹ̀-èdè Faransé ni Maud ń gbé, ó sì ń ṣiṣẹ́ nílé ìwé kan tó ti ń ran àwọn ọmọ tó jẹ́ aláàbọ̀ ara lọ́wọ́ nígbà tí wọ́n bá ń kẹ́kọ̀ọ́ nínú kíláàsì. Láìpẹ́ yìí, àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tó wà ní kíláàsì kan ń kẹ́kọ̀ọ́ nípa bí wọ́n ṣe pa àwọn èèyàn nípakúpa tí wọ́n sì fi ọ̀pọ̀ èèyàn sí àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ nígbà ìṣàkóso Hitler. Nígbà yẹn lóhùn-ún, wọ́n fún àwọn ẹlẹ́wọ̀n ni aṣọ tí wọ́n lẹ ìrépé aláwọ̀ mèremère mọ́ ara rẹ̀. Àwọ̀ ìrépé aṣọ kọ̀ọ̀kan àti bó ṣe rí ló máa jẹ́ káwọn èèyàn mọ ohun tó gbé ẹni tó wọ̀ aṣọ náà dé ọgbà ẹ̀wọ̀n.

 Nígbà tí olùkọ́ kan ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn tó wọ aṣọ tó ní àmì onígun mẹ́ta aláwọ̀ pọ́pù, ó ni: “Èrò mi ni pé abẹ́yà-kan-náà-lọ̀pọ̀ làwọn èèyàn yẹn ní tiwọn.” Nígbà tí olùkọ́ náà kúrò ní kíláàsì yẹn, Maud lọ bá a, ó sì ṣàlàyé fún un pé Ẹlẹ́rìí Jèhófà làwọn ẹlẹ́wọ̀n tí Ìjọba Násì lẹ àmì yẹn mọ́ ara aṣọ wọn. a Ó ni òun máa fún un láwọn ìsọfúnni tó máa jẹ́ kó mọ bọ́rọ̀ náà ṣe rí lóòótọ́. Olùkọ́ yẹn fara mọ́ ohun tó sọ, ó sì ní kí Maud bá àwọn akẹ́kọ̀ọ́ sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀.

 Nígbà tí olùkọ́ míì tún kọ́ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ nípa àkòrí yìí, ó lo àtẹ kan tí wọ́n ya onírúurú àmì tó wà lára aṣọ àwọn ẹlẹ́wọ̀n yẹn sí. Àtẹ náà jẹ́ kó ṣe kedere pé Ẹlẹ́rìí Jèhófà làwọn tó wọ aṣọ tó ní àmì onígun mẹ́ta aláwọ̀ àlùkò lóòótọ́. Lẹ́yìn tí olùkọ́ yẹn kúrò ní kíláàsì náà, Maud fún un làwọn ìsọfúnni kan lórí àkòrí yìí. Olùkọ́ náà gbà pé òótọ́ lohun tí Maud sọ, ó sì ṣètò pé kó bá àwọn akẹ́kọ̀ọ́ yẹn sọ̀rọ̀.

Maud rèé tó mú ìtẹ̀jáde tó lò dání

 Maud ní i lọ́kàn pé ìṣẹ́jú mẹ́ẹ̀ẹ́dógún péré lòun fi máa ṣàlàyé ọ̀rọ̀ fún kíláàsì àkọ́kọ́, àmọ́ nígbà tó débẹ̀, wọ́n sọ fún un pé: “O lè lo wákàtí kan gbáko.” Torí náà, Maud kọ́kọ́ fi fídíò kan han àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà. Fídíò náà sọ̀rọ̀ nípa bí Ìjọba Násì ṣe ṣenúnibíni sáwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Nígbà tí wọ́n wo fídíò náà débi tó ti ṣàlàyé nípa bí ìjọba Násì ṣe kó ẹgbẹ̀rin [800] àwọn ọmọ kúrò lọ́dọ̀ àwọn òbí wọn, Maud dá fídíò náà dúró ó sì ka ìrírí nípa mẹ́ta lára àwọn ọmọ náà. Lẹ́yìn tí wọ́n wo fídíò náà tán, Maud parí ọ̀rọ̀ rẹ̀, ó sì ka lẹ́tà ọ̀dọ́kùnrin Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan, tó jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Austria tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Gerhard Steinacher. Ọmọ ọdún mọ́kàndínlógún (19) ni ọ̀dọ́kùnrin náà, ọdún 1940 ló kọ lẹ́tà yẹn láti dágbére fáwọn òbí rẹ̀ nígbà tó ku wákàtí díẹ̀ kí ìjọba Násì pa á. b

 Nígbà tí Maud dé kíláàsì kejì, ó tún ṣe àlàyé yìí fún wọn. Ọpẹ́lọpẹ́ bí Maud ṣe jẹ́ onígboyà, àwọn tíṣà méjèèjì yẹn ti wá rí i dájú pé wọ́n ń mẹ́nu ba àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà nígbàkigbà tí wọ́n bá ń kọ́ àwọn ọmọ ilé ẹ̀kọ́ nípa àwọn tí Ìjọba Násì fìyà jẹ ní àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́.

a Nígbà Ogun Àgbáyé Kejì, wọ́n ju àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà lórílẹ̀-èdè Jámánì sẹ́wọ̀n torí pé wọ́n kọ̀ láti kọ́wọ́ ti Ìjọba Násì. Nígbà yẹn, ohun tí ọ̀pọ̀ èèyàn mọ̀ wọ́n sí ni Bibelforscher (ìyẹn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì).

b Wọ́n dájọ́ ikú fún Gerhard Steinacher torí pé ó kọ̀ láti di ọ̀kan lára àwọn ọmọ ogun ilẹ̀ Jámánì. Nínú lẹ́tà ìdágbére tó kọ, ó sọ pé: “Ọmọdé ṣì ni mí. Àfi tí Olúwa bá fún mi lókun nìkan ni mo lè fara dà á, ìyẹn sì ni mò ń bẹ̀bẹ̀ fún.” Àárọ̀ ọjọ́ kejì ni wọ́n pa Gerhard. Àkọlé tí wọ́n kọ síbi sàréè rẹ̀ kà pé: “Ikú rẹ̀ gbé orúkọ Ọlọ́run ga.”