Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Ó Ń Tu Àwọn Míì Nínú Láìka Àìlera Ẹ̀ Sí

Ó Ń Tu Àwọn Míì Nínú Láìka Àìlera Ẹ̀ Sí

 Wọ́n gbé Clodean tó jẹ́ ọ̀kan lára àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní South Africa lọ sílé ìwòsàn fún iṣẹ́ abẹ kan tó díjú. Oríṣiríṣi àìsàn ló ń ṣe é, ó sì tún ní láti ronú lórí onírúurú ìtọ́jú ìṣègùn kó lè pinnu èyí tó máa gbà. Kó tó ṣiṣẹ́ abẹ náà, ó sábà máa ń rẹ̀ ẹ́, ara sì máa ń ro ó. Bí nǹkan sì ṣe rí fún un náà nìyẹn lẹ́yìn tó ṣiṣẹ́ abẹ náà. Kódà, kò lè jókòó dáadáa fún nǹkan bí oṣù méjì ààbọ̀ lẹ́yìn tó pa dà sílé. Ohun tó tún wá jẹ́ kọ́rọ̀ náà le ni pé àrùn Corona ò jẹ́ káwọn èèyàn lè wá kí i.

 Síbẹ̀, Clodean ò ro ara ẹ̀ pin, kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe ló bẹ Ọlọ́run pé kó fún òun lókun kóun lè máa tu àwọn míì nínú. Nígbà tí ara ẹ̀ le díẹ̀, ó pe àbúrò aládùúgbò ẹ̀ kan tó ti fìgbà kan rí kẹ́kọ̀ọ́ lọ́dọ̀ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Clodean bá a sọ̀rọ̀ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, ìyẹn sì mú kí obìnrin náà bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pa dà. Ó tún jẹ́ kí obìnrin náà mọ̀ pé ó máa jàǹfààní gan-an tó bá ń wá sí ìpàdé wa. Bákan náà, ó ṣètò bí obìnrin náà ṣe máa ṣèpàdé látorí fóònù. Ó yani lẹ́nu pé obìnrin náà wá sípàdé ìpàdé kódà ó dáhun nípàdé tó wá.

 Clodean tún bá àbúrò obìnrin yìí sọ̀rọ̀ torí pé òun náà fẹ́ kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Kódà, àbúrò obìnrin yẹn sọ fún Clodean nípa àwọn míì tó ṣeé ṣe kí wọ́n fẹ́ kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀, Clodean bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ àwọn obìnrin mẹ́rin míì lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Àmọ́ kò tán síbẹ̀ o!

Clodean

 Torí pé ọ̀rọ̀ àwọn míì jẹ Clodean lógún, àwọn obìnrin mẹ́rìndínlógún (16) ló bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ lásìkò àjàkálẹ̀ àrùn Corona! Ọ̀pọ̀ nínú wọn ló sì ń wá sípàdé wa látorí fóònù. Ohun tí Clodean ń ṣe yìí kì í jẹ́ kó máa ronú lórí ìṣòro tó ní. Ó gbà pé bí Jèhófà tó jẹ́ “Ọlọ́run ìtùnú gbogbo” ṣe ń tu òun nínú ló jẹ́ kòun náà lè máa tu àwọn míì nínú.​—2 Kọ́ríńtì 1:​3, 4.

 Báwo ni ohun tí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Clodean ń kọ́ ṣe rí lára wọn? Ọ̀kan nínú wọn sọ pé: “Mo ti jàǹfààní lónírúurú ọ̀nà. Àmọ́ èyí tó ṣe pàtàkì jù ni bí mo ṣe mọ orúkọ Ọlọ́run ìyẹn sì ti ràn mí lọ́wọ́ láti sún mọ́ Jèhófà.” Àmọ́ obìnrin tí Clodean kọ́kọ́ bá sọ̀rọ̀ ńkọ́? Ǹjẹ́ ẹ jẹ́ mọ̀ pé ó ti ń fojú sọ́nà láti ṣèrìbọmi! Àwọn ohun tó ṣẹlẹ̀ mú kí inú Clodean dùn gan-an. Ìlera ẹ̀ sì ti dáa sí i.