Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

BÍBÉLÌ MÁA Ń YÍ ÌGBÉSÍ AYÉ ÀWỌN ÈÈYÀN PA DÀ

“Mo Máa Ń Tètè Bínú Gan-an”

“Mo Máa Ń Tètè Bínú Gan-an”
  • Ọdún Tí Wọ́n Bí Mi: 1975

  • Orílẹ̀-èdè Mi: Mẹ́síkò

  • Irú Ẹni Tí Mo Jẹ́ Tẹ́lẹ̀: Ìbínú mi máa ń le gan-an; ọ̀daràn ni mí

ÌGBÉSÍ AYÉ MI ÀTẸ̀YÌNWÁ

 Ìlú kékeré kan tó ń jẹ́ San Juan Chancalaito ní ìpínlẹ̀ Chiapas, lórílẹ̀-èdè Mẹ́síkò ni wọ́n bí mi sí. Ẹ̀yà Chol tó ṣẹ̀ wá látọ̀dọ̀ àwọn Maya ni ìdílé mi ti wá. Ọmọ méjìlá [12] làwọn òbí mi bí, èmi ni ọmọ karùn-ún. Nígbà tí mo wà lọ́mọdé, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń kọ́ èmi àtàwọn ẹ̀gbọ́n mi pẹ̀lú àwọn àbúrò mi lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Àmọ́ ó ṣeni láàánú pé mi ò fi ohun tí mò ń kọ́ nínú Bíbélì ṣèwà hù nígbà tí mo wà lọ́dọ̀ọ́.

 Nígbà tí mo pé ọmọ ọdún mẹ́tàlá [13], mo ti bẹ̀rẹ̀ sí í lo oògùn olóró, mo sì ń jalè. Mi ò wá gbélé mọ́, ṣe ni mò ń kó kiri. Nígbà tí mo wà lọ́mọ ọdún mẹ́rìndínlógún [16], mo bẹ̀rẹ̀ sí í ṣiṣẹ́ nínú oko kan tí wọ́n ti ń gbin igbó. Lẹ́yìn nǹkan bí ọdún kan tí mo ti ń ṣiṣẹ́ yẹn, ohun kan ṣẹlẹ̀ lálẹ́ ọjọ́ kan. À ń gbé igbó tó pọ̀ gan-an sọdá nínú ọkọ̀ ojú omi, làwọn ẹgbẹ́ kan táwọn náà ń ta igbó bá wá gbéjà kò wá. Ni wọ́n bá da ìbọn bolẹ̀. Ṣe ni mo bẹ́ sínú odò kí ọta ìbọn má bàa bà mí, mo wá wẹ̀ jáde síbòmíì tó jìnnà sí wọn. Ẹ̀yìn ìyẹn ni mo sá lọ sí Amẹ́ríkà.

 Mo tún bẹ̀rẹ̀ sí í ta oògùn olóró nígbà tí mo dé Amẹ́ríkà, mo sì ń dáràn mọ́ ọ̀ràn. Nígbà tí mo wà lọ́mọ ọdún mọ́kàndínlógún [19], àwọn ọlọ́pàá mú mi, wọ́n ní mo jẹ̀bi ẹ̀sùn olè, pé mo sì gbìyànjú àtipààyàn. Bí wọ́n ṣe rán mi lọ sẹ́wọ̀n nìyẹn. Nígbà tí mo dé ọgbà ẹ̀wọ̀n, mo wọ ẹgbẹ́ ọ̀daràn, mo sì túbọ̀ ń hu ìwà ipá. Ni àwọn aláṣẹ bá gbé mi lọ sí ọgbà ẹ̀wọ̀n míì tó tún le jùyẹn lọ ní àdúgbò Lewisburg, ní Pennsylvania.

 Nígbà tí mo dé ẹ̀wọ̀n Lewisburg, ṣe ni ìwà mi tún burú sí i. Torí pé mo ti fín ara bíi tàwọn tá a jọ wà nínú ẹgbẹ́ tí mo wà tẹ́lẹ̀, àwọn ọmọ ẹgbẹ́ yẹn tó wà nínú ọgbà ẹ̀wọ̀n tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ gbé mi wá tètè dá mi mọ̀, mo sì dara pọ̀ mọ́ wọn. Mo wá di oníwà ipá gbáà, ìjà lónìí, ìjà lọ́la. Ìgbà kan wà tí ẹgbẹ́ wa bá ẹgbẹ́ míì jà nínú ọgbà ẹ̀wọ̀n. Ìjà àjàkú-akátá ni, ṣe là ń fi pákó tí wọ́n fi ń gbá bọ́ọ̀lù àtàwọn irin gbìngbì tí wọ́n fi ń ṣe eré ìmárale lu ara wa. Àfìgbà táwọn ẹ̀ṣọ́ da tajútajú sínú afẹ́fẹ́ ni wọ́n tó rí wa là. Lẹ́yìn ìṣẹ̀lẹ̀ yẹn, ṣe làwọn aláṣẹ ọgbà ẹ̀wọ̀n yà mí sọ́tọ̀, tí wọ́n sì fi mí sí yàrá tí wọ́n ń fi àwọn ẹlẹ́wọ̀n tó léwu sí. Mo máa ń tètè bínú gan-an, ọ̀rọ̀ ẹnu mi ò sì dáa. Ó rọrùn fún mi láti lùùyàn bolẹ̀. Kódà, bíi kí n máa lùùyàn ló máa ń ṣe mí. Mi ò gbà rárá pé ohun tí mò ń ṣe ò dáa.

BÍ BÍBÉLÌ ṢE YÍ ÌGBÉSÍ AYÉ MI PA DÀ

 Nígbà táwọn aláṣẹ yà mí sọ́tọ̀ nínú ẹ̀wọ̀n, inú yàrá tí wọ́n fi mí sí ni mo sábà máa ń wà látàárọ̀ ṣúlẹ̀, ni mo bá bẹ̀rẹ̀ sí í ka Bíbélì kí ọwọ́ mi má bàa dilẹ̀. Nígbà tó yá, ẹ̀ṣọ́ kan fún mi ní ìwé Iwọ Le Walaaye Titilae ninu Paradise lori Ilẹ Aye. a Bí mo ṣe ń ka ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì yìí, mo bẹ̀rẹ̀ sí í rántí ọ̀pọ̀ nǹkan tí mo ti kọ́ ní kékeré nígbà táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Mo wá bẹ̀rẹ̀ sí í ro ibi tí mo bá ayé ara mi dé torí ìwà jàgídíjàgan tí mò ń hù. Mo tún ronú kan ìdílé mi. Àbúrò mi obìnrin kan àti ẹ̀gbọ́n mi obìnrin kan ti di Ẹlẹ́rìí Jèhófà, mo wá bẹ̀rẹ̀ sí í rò ó pé, ‘Àwọn á mà gbé láyé títí láé.’ Ni mo bá bi ara mi pé, ‘Kí ló dé tí tèmi ò lè rí bẹ́ẹ̀?’ Ìgbà yẹn ni mo pinnu pé àfi kí n yí ìgbésí ayé mi pa dà.

 Àmọ́ mo mọ̀ pé mi ò lè dá a ṣe, mo nílò kẹ́nì kan ràn mí lọ́wọ́. Torí náà, mo kọ́kọ́ gbàdúrà sí Jèhófà Ọlọ́run, mo sì bẹ̀ ẹ́ pé kó ràn mí lọ́wọ́. Ẹ̀yìn ìyẹn ni mo kọ̀wé sí ẹ̀ka ọ́fíìsì àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, tí mo sì ní kí wọ́n jẹ́ kí ẹnì kan wá máa kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ẹ̀ka ọ́fíìsì ṣètò pé kí ìjọ kan tó wà nítòsí kàn sí mi. Nígbà yẹn, àwọn aláṣẹ ọgbà ẹ̀wọ̀n ò gbà kí àwọn tí kì í ṣe mọ̀lẹ́bí mi wá máa kí mi, torí náà, ẹnì kan nínú ìjọ bẹ̀rẹ̀ sí í kọ lẹ́tà ránṣẹ́ sí mi láti fún mi níṣìírí, ó tún máa ń fi àwọn ìwé tó dá lórí Bíbélì ránṣẹ́ sí mi, ìyẹn sì jẹ́ kó túbọ̀ wù mí láti yí ìgbésí ayé mi pa dà.

 Mo gbé ìgbésẹ̀ pàtàkì kan. Mo pinnu pé màá kúrò nínú ẹgbẹ́ tí mo ti wà fún ọ̀pọ̀ ọdún. Ibi tí wọ́n fi mí sí lọ́gbà ẹ̀wọ̀n ni olórí ẹgbẹ́ yẹn náà wà, torí náà, mo lọ bá a nígbà kan tá à ń ṣeré ìdárayá, mo sì sọ fún un pé mo fẹ́ di Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ó yà mí lẹ́nu nígbà tó sọ fún mi pé: “Tó bá jẹ́ pé o fẹ́ di ajẹ́rìí lóòótọ́, kò síṣòro. Mi ò lè bá Ọlọ́run figa gbága. Àmọ́ tó bá jẹ́ pé ṣe lo kàn fẹ́ kúrò nínú ẹgbẹ́ wa, o mohun tó máa tẹ̀yìn ẹ̀ yọ.”

 Ní ọdún méjì tó tẹ̀ lé e, àwọn òṣìṣẹ́ ọgbà ẹ̀wọ̀n rí i pé ìwà mi ti ń yí pa dà. Ìyẹn mú kí wọ́n túbọ̀ máa ṣe mí dáadáa. Bí àpẹẹrẹ, tí àwọn ẹ̀ṣọ́ bá fẹ́ sìn mí jáde lọ wẹ̀, wọn kì í fi ṣẹkẹ́ṣẹkẹ̀ dè mí mọ́. Ọ̀kan nínú àwọn ẹ̀ṣọ́ náà tiẹ̀ wá bá mi, ó sì rọ̀ mí pé kí n máa yíwà mi pa dà bí mo ṣe ń ṣe. Kódà, àwọn aláṣẹ ọgbà ẹ̀wọ̀n gbé mi lọ sí ẹ̀wọ̀n míì tí nǹkan ò ti fi bẹ́ẹ̀ le tó ti tẹ́lẹ̀, tí kò sì jìnnà sí ọgbà ẹ̀wọ̀n gangan. Wọ́n ní kí n lọ lo ọdún tó gbẹ̀yìn tó yẹ kí n lò lẹ́wọ̀n níbẹ̀. Nígbà tó di ọdún 2004, lẹ́yìn tí mo ti lo ọdún mẹ́wàá lẹ́wọ̀n, wọ́n tú mi sílẹ̀, wọ́n sì fi bọ́ọ̀sì ọgbà ẹ̀wọ̀n dá mi pa dà sí Mẹ́síkò.

 Kò pẹ́ tí mo dé Mẹ́síkò tí mo fi rí Gbọ̀ngàn Ìjọba kan táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti ń pàdé. Aṣọ ẹlẹ́wọ̀n ni mo wọ̀ lọ sípàdé àkọ́kọ́ tí mo lọ, torí òun nìkan ni aṣọ tí mo ní. Láìka bí mo ṣe rí sí, ṣe làwọn Ẹlẹ́rìí kí mi káàbọ̀ tọ̀yàyàtọ̀yàyà. Inúure tí wọ́n fi hàn sí mi jẹ́ kí n mọ̀ ọ́n lára pé àárín àwọn Kristeni tòótọ́ ni mo wà. (Jòhánù 13:35) Ní ìpàdé yẹn, àwọn alàgbà ìjọ ṣètò bí ẹnì kan á ṣe máa kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Lẹ́yìn ọdún kan, ní September 3, 2005, mo ṣèrìbomi, mo sì di Ẹlẹ́rìí Jèhófà.

 Ní January 2007, mo bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ alákòókò kíkún, ìyẹn ni pé mo máa ń fi àádọ́rin [70] wákàtí kọ́ àwọn míì lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lóṣooṣù. Lọ́dún 2011, mo kẹ́kọ̀ọ́ yege ní Ilé Ẹ̀kọ́ Bíbélì fún Àwọn Àpọ́n (tí wọ́n ń pè ní Ilé Ẹ̀kọ́ Àwọn Ajíhìnrere Ìjọba Ọlọ́run báyìí). Ilé ẹ̀kọ́ yìí ràn mí lọ́wọ́ gan-an kí n lè máa ṣe ojúṣe mi dáadáa nínú ìjo.

Ó wá ń wù mí báyìí láti máa kọ́ àwọn míì pé kí wọ́n jẹ́ ẹlẹ́mìí àlàáfíà

 Nígbà tó di ọdún 2013, mo fẹ́ Pilar, ìyàwo mi àtàtà. Ó máa ń fi ṣàwàdà pé ó ṣòro fún òun láti gbà pé òótọ́ làwọn ohun tí mo máa ń sọ nípa ìgbésí ayé mi àtẹ̀yìnwá. Mi ò pa dà dédìí àwọn ìwà àtijọ́ yẹn mọ́. Èmi àti ìyàwó mi gbà pé ìwà tí mò ń hù báyìí fi hàn pé òótọ́ ni Bíbélì lágbára láti yí ìgbésí ayé èèyàn pa dà.​—Róòmù 12:2.

ÀǸFÀÀNÍ TÍ MO TI RÍ

 Mo gbà pé ohun tí Jésù sọ nínú Lúùkù 19:10 kàn mí. Jésù sọ pé: “[Mo] wá láti wá kiri àti láti gba ohun tí ó sọnù là.” Mi ò sọ nù mọ́ báyìí. Mi ò sì kí í lu àwọn èèyàn kiri mọ́. Ọpẹ́lọpẹ́ Bíbélì lára mi, ìgbésí ayé mi ti wá nítumọ̀ gan-an, àárín èmi àtàwọn èèyàn gún, èyí tó sì ṣe pàtàkì jù ni pé mo ní àjọṣe tó dáa gan-an pẹ̀lú Ẹlẹ́dàá mi, Jèhófà.

[ÀLÀYÉ ÌSÀLẸ̀ ÌWÉ]

a Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la tẹ ìwé yìí jáde, àmọ́ a ò tẹ̀ ẹ́ mọ́. Lájorí ìwé tí wọ́n fi ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì báyìí ni ìwé Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!