Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Kí Nìdí Tí Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Fi Máa Ń Pa Dà Lọ Sọ́dọ̀ Àwọn Tó Ti Sọ Pé “Mi Ò Fẹ́ Gbọ́”?

Kí Nìdí Tí Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Fi Máa Ń Pa Dà Lọ Sọ́dọ̀ Àwọn Tó Ti Sọ Pé “Mi Ò Fẹ́ Gbọ́”?

 Ìfẹ́ táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní sí Ọlọ́run àtàwọn aládùúgbò wọn ló ń mú kí wọ́n máa sọ ohun tó wà nínú Bíbélì fún gbogbo èèyàn, títí kan àwọn tó ti sọ pé àwọn ò fẹ́ gbọ́. (Mátíù 22:37-​39) Torí pé a nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run la ṣe ń tẹ̀ lé àṣẹ tí Ọmọ rẹ̀ pa pé ká “jẹ́rìí kúnnákúnná.” (Ìṣe 10:42; 1 Jòhánù 5:3) Ká lè ṣe èyí, a máa ń rí i pé a pa dà lọ sọ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fáwọn èèyàn, bó bá tiẹ̀ jẹ́ pé a ti lọ sọ́dọ̀ wọn tẹ́lẹ̀. Ohun táwọn wòlíì Ọlọ́run ṣe láyé àtijọ́ náà nìyẹn. (Jeremáyà 25:4) Ìfẹ́ tá a ní sáwọn aládùúgbò wa ló ń mú ká sọ “ìhìn rere ìjọba” Ọlọ́run fún gbogbo èèyàn kí wọ́n lè rígbàlà, títí kan àwọn tí ò kọ́kọ́ fẹ́ gbọ́.​—Mátíù 24:14.

 Tá a bá pa dà lọ síbi táwọn kan ti sọ tẹ́lẹ̀ pé àwọn ò fẹ́ gbọ́, ó sábà máa ń ṣẹlẹ̀ pé ká ráwọn tó máa fẹ́ gbọ́rọ̀ wa. Wo ohun mẹ́ta tó máa ń fà á:

  •   Àwọn tó wà níbẹ̀ tẹ́lẹ̀ lè ti kó kúrò.

  •   Àwọn míì níbẹ̀ lè fẹ́ gbọ́rọ̀ wa.

  •   Àwọn èèyàn máa ń pèrò dà. Ohun tó ń ṣẹlẹ̀ láyé tàbí ohun tó ṣẹlẹ̀ sí ẹnì kan lè mú kí ‘àìní rẹ̀ nípa tẹ̀mí’ bẹ̀rẹ̀ sí í jẹ onítọ̀hún lọ́kàn, ìyẹn ni pé kó fẹ́ túbọ̀ sún mọ́ Ọlọ́run, ó sì lè gbọ́ tá a bá bá a sọ ohun tó wà nínú Bíbélì. (Mátíù 5:3) Kódà, àwọn tó jẹ́ alátakò gan-an lè yí pa dà, bó ṣe ṣẹlẹ̀ sí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù.​—1 Tímótì 1:​13.

 Síbẹ̀, a kì í fipá mú ẹnikẹ́ni gbọ́rọ̀ wa. (1 Pétérù 3:​15) A gbà pé ẹnì kọ̀ọ̀kan ló máa pinnu ohun tó fẹ́ ṣe tó bá dọ̀rọ̀ ìjọsìn.​—Diutarónómì 30:19, 20.