Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Àwọn Eré Ojú Pátákó

Àwọn eré bèbí ojú pátákó yìí sọ̀rọ̀ nípa àwọn ohun tó ṣe pàtàkì, àmọ́ wọ́n tuni lára, wọ́n sì rọrùn lóye!

 

Kí Ló Túmọ̀ Sí Láti Ní Ẹ̀tanú?

Ọjọ́ pẹ́ táwọn èèyàn ti ń ṣe ẹ̀tanú sí àwọn míì. Bíbélì sọ ohun tá a lè ṣe tá ò fi ní fàyè gba ẹ̀mí burúkú yìí nínú ọkàn wa.

Sìgá Mímu Lè Ba Ayé Èèyàn Jẹ́

Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ èèyàn ló ń mu sìgá, àwọn míì ti jáwọ́, àmọ́ àwọn kan ṣì ń tiraka láti jáwọ́. Kí nìdí? Ṣé bẹ́ẹ̀ náà ni sìgá mímu burú tó ni?

Kí Ni Géèmù Tó Ò Ń Gbá Ń Sọ Nípa Ẹ?

Géèmù máa ń dùn ún gbá, àmọ́ kò ṣàìní ìpalára tó lè ṣe fúnni. Báwo lo ṣe lè yẹra fún ewu tó wà níbẹ̀ kó o sì máa gbádùn géèmù tó ò ń gbá?

O Lè Pa Dà Ní Ayọ̀

Kí lo lè ṣe tí ìbànújẹ́ bá ń gbà ẹ́ lọ́kàn ní gbogbo ìgbà?

Ohun Tó Yẹ Kó O Mọ̀ Nípa Eré Ìdárayá

Eré ìdárayá lè jẹ́ kó o kọ́ bó o ṣe lè máa fọwọ́ sowọ́ pọ̀ àti bó o ṣe lè máa bá àwọn míì sọ̀rọ̀. Ṣé ó yẹ kí eré ìdárayá wà lára àwọn nǹkan tó ṣe pàtàkì jù láyé rẹ?

Ma Ṣe Jẹ́ Kí Ọtí Di Ìdẹkùn fún Ẹ

Tí ọ̀pọ̀ èèyàn bá ti mutí yó, wọ́n máa ń sọ̀rọ̀ tàbí kí wọ́n hùwà tí wọ́n máa pa dà kábàámọ̀. Kí lo lè ṣe kí ọtí àmujù má bàa ṣàkóbá fún ẹ?

Báwo Ni Mo Ṣe Lè Máa Sọ Tinú Mi Fáwọn Òbí Mi?

Báwo lo ṣe lè sọ tinú ẹ fáwọn òbí ẹ tó bá tiẹ̀ ń ṣe ẹ́ bíi pé kó o máà bá ẹnì kankan sọ̀rọ̀?

Ṣé Fóònù Tàbí Tablet Ò Tíì Di Bárakú fún Ẹ?

Ayé ti di ayé íńtánẹ́ẹ̀tì, àmọ́ kò yẹ kó di bárakú fún ẹ. Báwo lo ṣe lè mọ̀ tí fóònù tàbí tablet bá ti di bárakú fún ẹ? Ká sọ pé ó ti di bárakú fún ẹ, kí lo lè ṣe sí i?

Kí Ni Mo Lè Ṣe Kí N Lè Túbọ̀ Lómìnira?

O lè máa rò ó pé o kì í ṣe ọmọdé mọ́, àmọ́ àwọn òbí ẹ lè má gbà bẹ́ẹ̀. Kí lo lè máa ṣe kí wọ́n lè fọkàn tán ẹ?

Báwo Ni Mo Ṣe Lè Yẹra fún Òfófó?

Tí wọ́n bá ti ń sọ̀rọ̀ ẹnìkan láì dáa, ṣe ni kó o tètè gbégbèésẹ̀!

Ṣé Ìfẹ́ Tòótọ́ Ni àbí Ìfẹ́ Ojú Lásán?

Mọ ìyàtọ̀ tó wà láàárín ìfẹ́ ojú lásán àti ìfẹ́ tòótọ́.

Máa Fọgbọ́n Lo Ìkànnì Àjọlò

Máa ṣọ́ra fún ewu lórí ìkànnì tó o bá ń bá àwọn ọ̀rẹ́ rẹ ṣeré níbẹ̀.

Ta Ni Ọ̀rẹ́ Tòótọ́?

Kò ṣòro rárá láti ní ọ̀rẹ́ burúkú, àmọ́ báwo ni o ṣe lè rí ọ̀rẹ́ tòótọ́

Bó O Ṣe Lè Borí Ẹni Tó Ń Halẹ̀ Mọ́ Ẹ Láì Bá A Jà

Kọ́ nípa ohun tó ń mú kí àwọn ọmọ kan máa halẹ̀ mọ́ àwọn ọmọ míì àti bí o ṣe lè borí wọn.