Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

TA LÓ ṢIṢẸ́ ÀRÀ YÌÍ?

Bí Awọ Ẹja Àbùùbùtán Ṣe Máa Ń Fọ Ara Ẹ̀

Bí Awọ Ẹja Àbùùbùtán Ṣe Máa Ń Fọ Ara Ẹ̀

 Ìṣòro ńlá làwọn ẹjá kéékèèké àtàwọn ohun alààyè míì tó ń gbé lábẹ́ omi tó máa ń lẹ̀ mọ́ ara àwọn ọkọ̀ òkun máa ń dá sílẹ̀ fáwọn tó ń wà á. Wọn kì í jẹ́ kí ọkọ̀ òkun ráyè sáré dáadáa, wọ́n máa ń jẹ́ kó jepo, ó sì máa ń gba pé kí wọ́n máa gbé irú ọkọ̀ òkun bẹ́ẹ̀ lọ síbi tí wọ́n á ti tún un ṣe léraléra, bí ọdún mélòó kan síra wọn. Ara ohun alààyè míì ni àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ti wá ń kọ́ ọgbọ́n tí wọ́n lè ta sí i báyìí.

 Rò ó wò ná: Ìwádìí jẹ́ ká rí ohun tí oríṣi ẹja àbùùbùtán alápá gígùn kan tí wọ́n ń pè ní pilot whale (ìyẹn Globicephala melas) máa ń ṣe. Àwọ̀ ẹja yìí lè dá ara rẹ̀ fọ̀. Ihò kéékèèké pọ̀ lára àwọ̀ ẹja náà, àmọ́ àwọn ihò ọ̀hún kéré gan-an débi pé àwọn ẹja kéékèèké ò lè rí ibẹ̀ lẹ̀ mọ́. Omi kan tó ki bí ògì wà nínú àwọn ihò yìí tí kì í jẹ́ kí àwọn kòkòrò tín-tìn-tín bí algae àti bacteria ráyè dúró lára ẹja náà. Gbogbo ìgbà tí ẹja àbùùbùtán yìí bá ti ń pàwọ̀ dà ló máa ń yí omi kíki tó wà nínú àwọn ihò àwọ̀ rẹ̀ pa dà.

 Àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì fẹ́ ṣe irú ohun tí ẹja àbùùbùtán yìí máa ń ṣe sára àwọn ọkọ̀ òkun. Tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀, ṣe ni wọ́n máa ń fi oríṣi ọ̀dà kan kun ara àwọn ọkọ̀ òkun káwọn ẹja kéékèèké yẹn má bàa máa lẹ̀ mọ́ ọn. Àmọ́ ẹnu àìpẹ́ yìí làwọn aláṣẹ fòfin de irú ọ̀dà tí wọ́n sábà máa ń lò pé wọn ò gbọ́dọ̀ lò ó mọ́, torí ó ń ṣàkóbá fún àwọn ohun alààyè tó ń gbénú omi. Ibi táwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì wá parí èrò sí ni pé àwọn máa fi irin oníhò wínníwínní bo ara àwọn ọkọ̀ òkun, kẹ́míkà kan tí kò ní ṣàkóbá fáwọn ohun tó ń gbénú omi sì máa wà nínú àwọn ihò náà. Tí kẹ́míkà ọ̀hún bá ti lè kan omi báyìí, ṣe ló máa ki bí ògì, á sì wá bo gbogbo ara ọkọ̀ òkun náà. Torí pé kò fi bẹ́ẹ̀ nípọn, tó bá yá, ó máa ṣí kúrò lára ọkọ̀ náà, gbogbo ohun alààyè tó bá sì ti lẹ̀ mọ́ ọn lára ló máa bá a lọ tó bá ti ṣí. Kẹ́míkà míì á wá tú jáde, á tún ki tó bá ti kan omi, á sì tún bo ara ọkọ̀ náà.

Àwọn ẹja kéékèèké tó máa ń lẹ̀ mọ́ ọkọ̀ òkun lára kì í jẹ́ kó ráyè sáré, wọ́n sì máa ń ṣòroó yọ

 Ìwádìí táwọn iléeṣẹ́ tó ń po kẹ́míkà pọ̀ ṣe fi hàn pé tí wọ́n bá ṣe irú nǹkan yìí sára ọkọ̀ òkun, kò ní sí ohun tó ń jẹ́ pé àwọn ohun tó ń gbénú omi ń lẹ̀ mọ́ ọkọ̀ òkun lára débi tí wọ́n máa bà á jẹ́. Àǹfààní ńlá nìyẹn á sì ṣe àwọn iléeṣẹ́ tó ń fi ọkọ̀ òkun kẹ́rù, torí kì í ṣe owó kékeré ni wọ́n máa ń ná tí wọ́n bá fẹ́ lọ tún ara ọkọ̀ òkun wọn ṣe.

 Kí lèrò ẹ? Bí àwọ̀ ẹja àbùùbùtán ṣe lè dá ara rẹ̀ fọ̀ yìí, ṣé ó kàn ṣàdédé wà ni? Àbí ẹnì kan ló dá a?