Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

TA LÓ ṢIṢẸ́ ÀRÀ YÌÍ?

Àwọ̀ Ẹja Sea Cucumber

Àwọ̀ Ẹja Sea Cucumber

 Inú òkìtì iyùn abẹ́ omi àti ìsàlẹ̀ òkun ni ẹja sea cucumber ń gbé. Ara ẹja náà lè le gbagidi, ó lè rí gbágungbàgun tàbí kó tiẹ̀ rí ṣákaṣàka. Kò síbi tí wọn ò lè yíra sí, kódà láàárín ìṣẹ́jú díẹ̀ tàbí ìṣẹ́jú àáyá, ara wọn lè rọ̀ kó sì tún dédé le gbagidi. Bí ara ẹja sea cucumber ṣe rí yìí ló jẹ́ kó lè gba ojú ihò tóóró kọjá, lẹ́yìn náà wọ́n lè mú kára wọn le gbagidi káwọn ẹranko tó fẹ́ pa wọ́n máa bàa lè fà wọ́n jáde. Àwọ̀ ẹja sea cucumber tó ṣàrà ọ̀tọ̀ yìí ló jẹ́ kó lè ṣe bẹ́ẹ̀.

 Rò ó wò ná: Àwọ̀ ẹja sea cucumber lè le gbagidi, ó lè le díẹ̀, ó sì lè rọ̀. Ẹja sea cucumber máa ń fa okùn tẹ́ẹ́rẹ́ tó wà nínú àwọ̀ rẹ̀ kára ẹ̀ lè le gbagidi, ó máa ń rọra dẹ̀ ẹ́ kára ẹ̀ lè le díẹ̀, ó sì máa ń dẹ̀ ẹ́ pátápátá kára ẹ̀ lè rọ̀ pẹ̀tẹ̀pẹ̀tẹ̀. Ó máa ń lo onírúurú èròjà purotéènì kára ẹ̀ lè le gbagidi tàbí kó rọ̀.

 Èròjà purotéènì tó ń jẹ́ kí ara rẹ̀ le yìí máa ń mú kí okùn tẹ́ẹ́rẹ́ tó wà nínú àwọ̀ ẹ̀ so pọ̀ mọ́ra, òun ló sì ń jẹ́ kára ẹ̀ túbọ̀ le gbagidi. Tí èròjà purotéènì tó ń mára rọ̀ bá ti mú kí okùn tẹ́ẹ́rẹ́ náà dẹ̀ tán, ara rẹ̀ á wá rọ̀ sí i. Ara ẹja Sea-cucumber lè rọ̀ débi pé á fẹ́ máa yòrò.

 Àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ ti ń ṣe àwọn ohun èlò tó máa lè ṣe gẹ́lẹ́ bí i ti àwọ̀ ẹja sea-cucumber. Ọ̀kan lára àfojúsùn wọn ni pé kí wọ́n ṣe ohun èlò pàtàkì kan tí wọ́n fi ń ṣiṣẹ́ abẹ inú ọpọlọ, táá mú kíṣẹ́ abẹ náà rọrùn kó sì gbéṣẹ́. Ọgbọ́n pàtàkì tí wọ́n kọ́ lára ẹja sea cucumber yìí máa mú kí ohun èlò náà lè ṣiṣẹ́ nínú ara.

 Kí lèrò rẹ? Ṣé àwọ̀ ẹja sea cucumber kan ṣàdédé wà ni? Àbí ẹnì kan ló ṣiṣẹ́ àrà yìí?