Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

FARA WÉ ÌGBÀGBỌ́ WỌN | MÀRÍÀ MAGIDALÉNÌ

“Mo Ti Rí Olúwa!”

“Mo Ti Rí Olúwa!”

Màríà Magidalénì gbójú sókè, ó sì ń nu omijé tó ń dà lójú rẹ̀. Ìdí sì ni pé ẹni tó nífẹ̀ẹ́ bí ojú ni wọ́n gbé kọ́ sórí igi yìí, ìyẹn Jésù Olúwa. Ìgbà ìrúwé ni, ó sì jẹ́ ní nǹkan bí ọwọ́ ọ̀sán “síbẹ̀ òkùnkùn ṣú bo gbogbo ilẹ̀ náà”! (Lúùkù 23:44, 45) Ó fi aṣọ rẹ̀ kọ́ èjìká, ó sì sún mọ́ àwọn obìnrin tó wà nítòsí rẹ̀. Kò lè jẹ́ ìṣẹ̀lẹ̀ ọ̀sándòru tó kàn máa ń wáyé fún ìṣẹ́jú mélòó kan ló máa fa òkùnkùn tó bolẹ̀ fún wákàtí mẹ́ta. Ó ṣeé ṣe kí Màríà àtàwọn míì tó dúró nítòsí Jésù bẹ̀rẹ̀ sí í gbọ́ ohùn àwọn ẹranko tó máa ń jẹ̀ lóru, tí wọn kì í sábà gbọ́ ní ojúmọmọ. Ẹ̀rù ba àwọn kan lára àwọn tó wà níbẹ̀ gan-an débi tí wọ́n fi sọ pé: “Ó dájú pé, Ọmọ Ọlọ́run nìyí.” (Mátíù 27:54) Ó ṣeé ṣe kí àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù àtàwọn míì rò pé àmì yẹn ń fi hàn pé inú Jèhófà ò dùn sí bí wọ́n ṣe fi ìwà òǹrorò pa Ọmọ Rẹ̀.

Kò rọrùn rárá fún Màríà Magidalénì láti wo ohun tó ń ṣẹlẹ̀ náà, bẹ́ẹ̀ sì rèé, kò lè fibẹ̀ sílẹ̀. (Jòhánù 19:25, 26) Ó dájú pé Jésù ti ń jẹ ìrora tí kò ṣe é fẹnu sọ. Ìyá Jésù náà nílò ẹni tó máa dúró tì í, tó sì máa tù ú nínú.

Pẹ̀lú gbogbo ohun tí Jésù ti ṣe fún Màríà, ó gbà pé ó di dandan kí òun ṣe gbogbo ohun tí òun bá lè ṣe fún Jésù. Ẹni tí nǹkan ti tojú sú téèyàn sì ń káàánú ni Màríà tẹ́lẹ̀, àmọ́ ní báyìí Jésù ti sọ ẹ̀gàn ẹ̀ dògo. Ó ti jẹ́ kí ìgbésí ayé rẹ̀ nítumọ̀ kó sì ládùn. Ó wá di obìnrin tí ìgbàgbọ́ rẹ̀ lágbára. Báwo ló ṣe rí bẹ́ẹ̀? Kí la sì lè rí kọ́ látinú ìgbàgbọ́ tí obìnrin yìí ní?

“Wọ́n Ń Fi Àwọn Ohun Ìní Wọn Ṣe Ìránṣẹ́ fún Wọn”

Ìtàn bí Màríà Magidalénì ṣe fi àwọn ohun ìní rẹ̀ ṣèránṣẹ́ fún Jésù ni Bíbélì kọ́kọ́ sọ nípa ẹ̀. Jésù gbà á sílẹ̀ lọ́wọ́ ìṣòro tó ń pọ́n ọn lójú tó sì mú un lẹ́rú. Láyé ìgbà yẹn, àwọn ẹ̀mí èṣù máa ń ṣe àwọn èèyàn bó ṣe wù wọ́n, wọ́n máa ń gbéjà ko ọ̀pọ̀ èèyàn, kódà wọ́n tiẹ̀ máa ń kó sínú àwọn kan tí wọ́n á sì máa darí wọn. A ò lè sọ bí àwọn ẹ̀mí burúkú yìí ṣe fojú Màríà Magidalénì rí màbo tó, àmọ́ a mọ̀ pé àwọn ẹ̀mí èṣù méje tó rorò gan-an, tó sì ń fòòró rẹ̀ ló wà lára rẹ̀. A dúpẹ́ lọ́wọ́ Jésù Kristi, gbogbo wọn pátá ló lé jáde láìku ẹyọ kan!—Lúùkù 8:2.

Ní báyìí, Màríà ti bọ́, ìtura tó bá a kọjá àfẹnusọ, ó sì ti bẹ̀rẹ̀ ìgbé ayé ọ̀tun. Báwo ló ṣe lè fi hàn pé òun moore? Ṣe ló di ọmọ ẹ̀yìn Jésù, kò sì yẹsẹ̀. Ó tún ṣe ohun kan tó gbàfiyèsí. Jésù àtàwọn àpọ́sítélì rẹ̀ nílò oúnjẹ, aṣọ àti ibi tí wọ́n máa sùn lálẹ́. Wọn kì í ṣe ọlọ́rọ̀, bẹ́ẹ̀ sì ni wọn ò ṣiṣẹ́ tí wọ́n lè fi gbọ́ bùkátà ara wọn nígbà yẹn. Torí náà, wọ́n nílò ìtìlẹ́yìn kí wọ́n lè gbájú mọ́ iṣẹ́ ìwàásù àti kíkọ́ni.

Màríà àtàwọn obìnrin mélòó kan ṣèrànwọ́ láti dí àìní yẹn. Àwọn obìnrin yẹn “ń fi àwọn ohun ìní wọn ṣe ìránṣẹ́ fún wọn.” (Lúùkù 8:1, 3) Ó ṣeé ṣe kí díẹ̀ lára àwọn obìnrin yẹn rí jájẹ. Bíbélì ò sọ bóyá wọ́n máa ń se oúnjẹ, wọ́n máa ń fọ aṣọ tàbí wọ́n máa ń ṣètò ibi tí wọ́n máa dé sí láti abúlé kan sí òmíì. Àmọ́, tinútinú ni wọ́n fi ṣiṣẹ́ láti ti Jésù àtàwọn àpọ́sítélì rẹ̀ lẹ́yìn lẹ́nu ìrìn àjò wọn, àwọn tó ń rìnrìn àjò náà sábà máa ń tó ogún (20). Kò sí àní-àní pé iṣẹ́ takuntakun táwọn obìnrin yẹn ṣe ran Jésù àtàwọn àpọ́sítélì rẹ̀ lọ́wọ́, ó sì mú kí wọ́n pọkàn pọ̀ sórí iṣẹ́ ìwàásù. Ó dájú pé Màríà mọ̀ pé òun ò lè san gbogbo oore tí Jésù ṣe fún òun pa dà láé, àmọ́ ẹ wo bí inú rẹ̀ ṣe máa dùn tó pé gbogbo ohun tó lè ṣe ló ṣe!

Lónìí, ọ̀pọ̀ lè fojú yẹpẹrẹ wo àwọn tó ń ṣe iṣẹ́ tó rẹlẹ̀ fáwọn míì. Àmọ́, ojú tí Ọlọ́run fi ń wò ó kọ́ nìyẹn. Ẹ fojú inú wo bí inú Ọlọ́run ṣe máa dùn tó bó ṣe ń rí Màríà tó ń yọ̀ǹda ara rẹ̀, tó sì ń ṣe gbogbo ohun tó lè ṣe láti ti Jésù àtàwọn àpọ́sítélì rẹ̀ lẹ́yìn! Lónìí pẹ̀lú, ọ̀pọ̀ àwọn Kristẹni olóòótọ́ ń fi tayọ̀tayọ̀ ṣe àwọn iṣẹ́ tó rẹlẹ̀ fún àwọn míì. Nígbà míì, oore tá a ṣe fáwọn míì tàbí ọ̀rọ̀ onínúure kan lè so èso rere, kódà ó lè ju ohun tá a rò lọ. Jèhófà mọ rírì irú àwọn ìtìlẹ́yìn bẹ́ẹ̀.—Òwe 19:17; Hébérù 13:16.

Nítòsí Òpó Igi Oró Jésù

Màríà Magidalénì wà lára àwọn obìnrin tó bá Jésù rìn lọ sí Jerúsálẹ́mù nígbà Ìrékọjá ti ọdún 33 S.K. (Mátíù 27:55, 56) Ó dájú pé ó máa banú jẹ́ gan-an nígbà tó gbọ́ pé wọ́n ti fàṣẹ ọba mú Jésù àti pé òru mọ́jú ni wọ́n fi gbọ́ ẹjọ rẹ̀. Àmọ́, kékeré nìyẹn lẹ́gbẹ̀ẹ́ ohun tó ṣì máa ṣẹlẹ̀. Gómìnà Pọ́ńtíù Pílátù gbà nígbà táwọn aṣáájú ìsìn Júù àtàwọn èrò tí wọ́n kó sòdí fúngun mọ́ ọn pé kó pa Jésù lórí òpó igi. Ó ṣeé ṣe kí Màríà ri Olúwa rẹ̀ tí ẹ̀jẹ̀ bò ó, tó sì ti rẹ̀ ẹ́ tẹnutẹnu. Jésù tún ru òpó igi tó gùn tí wọ́n fẹ́ kàn án mọ́, bẹ́ẹ̀ ni òpó igi náà ń fì í síwájú sẹ́yìn, bó ṣe ń wọ́ ọ gba àwọn ojú pópó kọjá.—Jòhánù 19:6, 12, 15-17.

Nǹkan bí ọwọ́ ọ̀sán ni, lẹ́yìn tí òkùnkùn ṣú bolẹ̀, Màríà Magidalénì àtàwọn obìnrin míì dúró “sí tòsí òpó igi oró” Jésù níbi tí wọ́n pa Jésù sí gangan. (Jòhánù 19:25) Màríà wà níbẹ̀ látìbẹ̀rẹ̀ dópin, ó fojú ara rẹ̀ rí i, ó sì gbọ́ nígbà tí Jésù ní kí Jòhánù máa tọ́jú ìyá òun, ó ṣe tán, Jésù nífẹ̀ẹ́ àpọ́sítélì Jòhánù gan-an. Ó gbọ́ bí Jésù ṣe ń joró, tó sì kígbe ẹkún tó korò sí Baba rẹ̀. Ó tún gbọ́ àwọn ọ̀rọ̀ akin tó sọ gbẹ̀yìn kó tó kú, ó ní: “A ti ṣé e parí.” Ìdààmú tó bá Màríà kọjá kékeré. Síbẹ̀, lẹ́yìn tí Jésù kú Màríà ò kúrò níbẹ̀. Kódà, lẹ́yìn tí ọkùnrin ọlọ́rọ̀ kan tó ń jẹ́ Jósẹ́fù ará Arimatíà tẹ́ òkú Jésù sínú ibojì, ṣe ni Màríà lọ jókòó síwájú sàréè náà.—Jòhánù 19:30; Mátíù 27:45, 46, 57-61.

Àpẹẹrẹ Màríà jẹ́ ká mọ ohun tá a lè ṣe nígbà tí àwọn onígbàgbọ́ bíi tiwa bá dojú kọ àdánwò tó le koko. A lè má lè dènà àjálù tàbí ká mú ìrora tí àjálù náà fà fún wọn kúrò. Síbẹ̀, a lè fi àánú hàn sí wọn, ká sì dúró tì wọ́n láìka ohun tó gbà sí. Tá a bá dúró ti ọ̀rẹ́ wa kan nígbà ìṣòro, ṣe ni ara máa tù ú, ó ṣe tán, wọ́n ní ìgbà ìṣòro làá mọ̀rẹ́. Ìyẹn tún máa fi hàn pé a ní ojúlówó ìgbàgbọ́, ó sì máa tu ẹni náà nínú gan-an.—Òwe 17:17.

Ó dájú pé ara máa tu Màríà ìyá Jésù gan-an bí Màríà Magidalénì ṣe dúró tì í

‘Màá Gbé E Lọ’

Lẹ́yìn tí wọ́n gbé òkú Jésù sínú ibojì, Màríà wà lára àwọn obìnrin tí wọ́n mú èròjà tó ń ta sánsán tó pọ̀ wá, kí wọ́n lè fi pa ara Jésù. (Máàkù 16:1, 2; Lúùkù 23:54-56) Lẹ́yìn náà, ó dìde ní àárọ̀ kùtù, lẹ́yìn tí Sábáàtì ti kọjá. Ẹ fojú inú wo bó ṣe ń rìn lọ nínú òkùnkùn pẹ̀lú àwọn obìnrin míì, tí wọ́n sì forí lé ibi tí wọ́n sin Jésù sí. Bí wọ́n ṣe ń lọ ni wọ́n ń ronú bí àwọn ṣe máa yí òkúta ńlá tí wọ́n fi dí ẹnu ọ̀nà ibojì náà kúrò. (Mátíù 28:1; Máàkù 16:1-3) Síbẹ̀, wọn ò torí ìyẹn pa dà sílé. Ìgbàgbọ́ tí wọ́n ní ló mú kí wọ́n ṣe gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe, wọ́n sì fi ìyókù sílẹ̀ fún Jèhófà.

Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé Màríà ló ṣáájú àwọn tó kù débi ibojì náà. Àmọ́, ó dúró lójijì, ẹ̀rù bà á, háà! wọ́n ti yí òkúta náà kúrò, ibojì náà sì ti ṣófo! Akínkanjú obìnrin yìí sáré pa dà lọ ròyìn ohun tó rí fún Pétérù àti Jòhánù. Ẹ fojú inú wo bó ṣe ń mí hẹlẹhẹlẹ, tó sì ń sunkún bó ṣe ń ròyìn ohun tójú rẹ̀ rí, ó sọ pé: “Wọ́n ti gbé Olúwa kúrò nínú ibojì, a ò sì mọ ibi tí wọ́n tẹ́ ẹ sí”! Ni Pétérù àti Jòhánù bá sáré lọ síbi ibojì náà, wọ́n sì rí i pé ó ti ṣófo. Lẹ́yìn náà, wọ́n pa dà sílé wọn.—Jòhánù 20:1-10.

Nígbà tí Màríà pa dà síbi ibojì náà, òun nìkan ló dá dúró síbẹ̀. Ní àárọ̀ kùtù, bí ibojì náà ṣe pa rọ́rọ́ jẹ́ kí ọ̀rọ̀ náà túbọ̀ dùn ún, ó wá bẹ̀rẹ̀ sí í sunkún. Ó bẹ̀rẹ̀ wo inú ibojì náà, síbẹ̀ kò gbà pé Olúwa kò sí níbẹ̀, àmọ́ ohun tó rí yà á lẹ́nu. Àwọn áńgẹ́lì méjì tó wọ aṣọ funfun jókòó síbẹ̀! Wọ́n béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé: “Kí ló dé tó ò ń sunkún?” Ọ̀rọ̀ náà tojú sú u, ó sì sọ ohun kan náà tó sọ fún àwọn àpọ́sítélì pé: “Wọ́n ti gbé Olúwa mi lọ, mi ò sì mọ ibi tí wọ́n tẹ́ ẹ sí.” *Jòhánù 20:11-13.

Bó ṣe yíjú pa dà, ó rí ọkùnrin kan tó dúró sẹ́yìn rẹ̀. Kò mọ ẹni tí ọkùnrin náà jẹ́, ó rò pé ẹni tó ń tọ́jú ọgbà ni. Ọkùnrin náà fi ohùn pẹ̀lẹ́ béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé: “Obìnrin yìí, kí ló dé tí ó fi ń sunkún? Ta lò ń wá?” Màríà dá a lóhùn pé, “Ọ̀gá, tó bá jẹ́ ìwọ lo gbé e kúrò, sọ ibi tí o tẹ́ ẹ sí fún mi, màá sì gbé e lọ.” (Jòhánù 20:14-15) Ronú nípa ohun tí Màríà sọ yẹn ná. Ṣé òun nìkan lè dá gbé òkú Jésù, ẹni tó lágbára tó sì lókun? Màríà kò tiẹ̀ ronú lọ síbẹ̀ rárá. Ohun tó ṣáà wà lọ́kàn rẹ̀ ni pé kóun ṣe gbogbo ohun tí òun bá lè ṣe.

‘Màá gbé e lọ’

Ṣé a lè fara wé Màríà Magidalénì tá a bá kojú ìṣòro tàbí àwọn ohun tó dà bíi pé ó kọjá agbára wa? Tó bá jẹ́ pé àwọn ibi tá a kù sí àti ibi tágbára wa mọ la gbájú mọ́, ìbẹ̀rù àti iyèméjì lè sọ wá dìdàkudà. Àmọ́ tá a bá pinnu láti ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe, tá a sì fi ìyókù sọ́wọ́ Ọlọ́run, àṣeyọrí tá a máa ṣe máa ju ohun tá a lérò lọ. (2 Kọ́ríńtì 12:10; Fílípì 4:13) Èyí tó wá ṣe pàtàkì jù ni pé, a máa múnú Jèhófà dùn. Ohun tí Màríà ṣe nìyẹn, ọ̀nà àrà ni Jèhófà sì gbà san án lẹ́san.

“Mo Ti Rí Olúwa!”

Ọkùnrin tó dúró lẹ́gbẹ̀ẹ́ Màríà kì í ṣe ẹni tó ń tọ́jú ọgbà. Káfíńtà ni tẹ́lẹ̀, ó tún jẹ́ olùkọ́, ó sì tún jẹ́ Olúwa tí Màríà nífẹ̀ẹ́ gan-an. Àmọ́ kò dá a mọ̀, ó sì yíjú pa dà, ó bẹ̀rẹ̀ sí í lọ. Màríà kò lè gbà pé òótọ́ lohun tó ń ṣẹlẹ̀ báyìí. Ọlọ́run ti jí Jésù dìde, ó sì ti di ẹ̀dá ẹ̀mí alágbára. Ìyẹn ló mú kó lè gbé ara èèyàn wọ̀, ṣùgbọ́n kì í ṣe irú ara tó ní kó tó fi ara rẹ̀ rúbọ. Lẹ́yìn tó jíǹde, àwọn èèyàn ò dá a mọ̀, kódà àwọn tó ti mọ̀ ọn dáadáa tẹ́lẹ̀ gan-an ò mọ̀ pé òun ni.—Lúùkù 24:13-16; Jòhánù 21:4.

Báwo ni Jésù ṣe jẹ́ kí Màríà mọ̀ pé òun ni? Ó pè é bó ṣe máa ń pè é tẹ́lẹ̀, ó ní: “Màríà!” Ló bá yíjú pa dà, ó sì ké jáde pẹ̀lú èdè Hébérù tó ti sábà máa ń pè é tẹ́lẹ̀, ó ní “Rábónì!” Bó ṣe di olùkọ́ rẹ̀ ọ̀wọ́n nìyẹn o! Ayọ̀ ẹ̀ kún àkúnwọ́sílẹ̀. Ó rọ̀ mọ́ ọn, kò sì fẹ́ kó lọ.—Jòhánù 20:16.

Jésù mọ ohun tó ń rò, ló bá sọ fún un pé: “Má rọ̀ mọ́ mi mọ́.” A lè fojú inú wo bí Jésù ṣe ń sọ àwọn ọ̀rọ̀ yẹn tìfẹ́tìfẹ́, bóyá pẹ̀lú ẹ̀rín músẹ́ pàápàá, tó sì rọra ń já ara rẹ̀ gbà lọ́wọ́ rẹ̀, bẹ́ẹ̀ náà ló ń fi ìdánilójú sọ fún un pé: “Mi ò tíì gòkè lọ sọ́dọ̀ Baba.” Kò tíì tó àkókò fún un láti lọ sọ́run. Ó ṣì ní iṣẹ́ láti ṣe láyé, ó sì fẹ́ kí Màríà ran òun lọ́wọ́. Ṣe ni Màríà fara balẹ̀ gbọ́ gbogbo ohun tó sọ. Jésù wá sọ fún un pé: “Lọ bá àwọn arákùnrin mi, kí o sì sọ fún wọn pé, ‘Mo ń gòkè lọ sọ́dọ̀ Baba mi àti Baba yin àti sọ́dọ̀ Ọlọ́run mi àti Ọlọ́run yin.’ ”—Jòhánù 20:17.

Ẹ wo iṣẹ́ ńlá tí Olúwa rẹ̀ gbé fún un! Màríà wà lára àwọn tó kọ́kọ́ rí Jésù nígbà tó jí dìde. Òun ni Jésù tún rán báyìí pé kó lọ sọ ìròyìn ayọ̀ náà fáwọn míì. Fojú inú wo bí inú ẹ̀ ṣe máa dùn tó bó ṣe lọ wá àwọn ọmọ ẹ̀yìn, tó sì sọ ìròyìn náà fún wọn. Bó ṣe ń mí hẹlẹhẹlẹ, ó sọ fún wọn pé: “Mo ti rí Olúwa!” Gbogbo ohun tí Jésù sọ fún un ló ròyìn fún wọn láìku ẹyọ kan, ìdùnnú ló sì fi ń sọ ọ́. (Jòhánù 20:18) Ìròyìn táwọn ọmọ ẹ̀yìn gbọ́ yìí pa pọ̀ pẹ̀lú ohun tí wọ́n ti gbọ́ lẹ́nu àwọn obìnrin tó lọ síbi ibojì tó ṣófo náà jẹ́ kí wọ́n mọ ohun tó ń ṣẹlẹ̀ gan-an.—Lúùkù 24:1-3, 10.

“Mo ti rí Olúwa!”

‘Wọn Ò Gba Àwọn Obìnrin Náà Gbọ́’

Kí làwọn ọkùnrin náà ṣe nígbà tí wọ́n gbọ́? Wọn ò kọ́kọ́ dáhùn dáadáa. Bíbélì sọ pé: “Àwọn ọ̀rọ̀ yìí dà bí ìsọkúsọ létí wọn, wọn ò sì gba àwọn obìnrin náà gbọ́.” (Lúùkù 24:11) Àwọn ọkùnrin tó lọ́kàn tó dáa yìí dàgbà ní agbègbè tí wọn ò ti fi bẹ́ẹ̀ gba àwọn obìnrin gbọ́. Kódà, nínú àṣà wọn, wọn kì í jẹ́ káwọn obìnrin ṣe ẹlẹ́rìí nílé ẹjọ́. Ó ṣeé ṣe kí àṣà ìbílẹ̀ àwọn àpọ́sítélì náà ti nípa lórí wọn láìmọ̀. Àmọ́ Jésù àti Baba rẹ̀ ò lẹ́mìí kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà bó ti wù kó kéré mọ. Ẹ wo àǹfààní tí Jésù àti Baba rẹ̀ fún obìnrin olóòótọ́ yìí.

Kò sí àní-àní pé Màríà kò jẹ́ kí ìwà àwọn ọkùnrin yẹn múnú bí òun. Ó mọ̀ pé Olúwa òun fọkàn tán òun, ìyẹn ló sì jà jù. Bíi ti Màríà, gbogbo àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù ló ní iṣẹ́ kan láti jẹ́. Bíbélì pe iṣẹ́ náà ní “ìhìn rere ìjọba Ọlọ́run.” (Lúùkù 8:1) Jésù ò sọ fáwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé gbogbo èèyàn ló máa gbà wọ́n gbọ́ tàbí mọ rírì iṣẹ́ wọn. Kàkà bẹ́ẹ̀, òdìkejì lohun tó máa ṣẹlẹ̀. (Jòhánù 15:20, 21) Torí náà, á dáa káwa Kristẹni máa rántí Màríà Magidalénì. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn arákùnrin rẹ̀ ń ṣiyè méjì, ìyẹn ò ní kó má sọ ìhìn rere nípa àjíǹde Jésù fún wọn!

Nígbà tó yá, Jésù fara han àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ àti ọ̀pọ̀ lára àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀. Ìgbà kan tiẹ̀ wà tó fara han àwọn tó ju ọgọ́rùn-ún márùn-ún (500) lọ lẹ́ẹ̀kan. (1 Kọ́ríńtì 15:3-8) Bí Jésù ṣe ń fara han àwọn èèyàn, bẹ́ẹ̀ ni ìgbàgbọ́ Màríà á túbọ̀ máa lágbára sí i yálà ó rí i tàbí ṣe ló gbọ́ nípa ẹ̀. Ó ṣeé ṣe kí Màríà Magidalénì wà lára àwọn obìnrin tó wà níbi ìpàdé kan ní Jerúsálẹ́mù lọ́jọ́ Pẹ́ńtíkọ́sì, nígbà tí Ọlọ́run tú ẹ̀mí mímọ́ sórí àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù tí wọ́n pé jọ.—Ìṣe 1:14, 15; 2:1-4.

Ju gbogbo rẹ̀ lọ, ohun kan dájú. Ìyẹn sì ni pé Màríà Magidalénì di ìgbàgbọ́ rẹ̀ mú títí dópin. Torí náà, ẹ jẹ́ kí gbogbo wa pinnu pé ohun táwa náà máa ṣe nìyẹn. Ńṣe là ń fara wé ìgbàgbọ́ Màríà Magidalénì tá a bá ń fi ìmọrírì hàn fún gbogbo ohun tí Jésù ṣe fún wa, tá a sì ń fayọ̀ ṣiṣẹ́ sin àwọn míì bá a ṣe ń gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà.

^ ìpínrọ̀ 13 Ó dájú pé Màríà ti fi ibojì náà sílẹ̀ kí àwọn obìnrin tí wọ́n jọ rìn náà tó pàdé áńgẹ́lì tó sọ fún wọn pé Jésù ti jíǹde. Ká sọ pé ó rí i ni, ó dájú pé kò bá ti sọ fún Pétérù àti Jòhánù pé òun rí áńgẹ́lì kan tó ṣàlàyé bó ṣe jẹ́ fún òun.—Mátíù 28:2-4; Máàkù 16:1-8.