Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

ÌRÀNLỌ́WỌ́ FÚN ÌDÍLÉ | ỌMỌ TÍTỌ́

Ìdí Tó Fi Ṣe Pàtàkì Pé Káwọn Ọmọdé Máa Kàwé —Apá Kìíní: Ìwé Kíkà Tàbí Ìran Wíwò?

Ìdí Tó Fi Ṣe Pàtàkì Pé Káwọn Ọmọdé Máa Kàwé —Apá Kìíní: Ìwé Kíkà Tàbí Ìran Wíwò?

 Tí ọwọ́ àwọn ọmọ rẹ bá dilẹ̀, kí ni wọ́n á fẹ́ ṣe, ṣé wọ́n á fẹ́ wo fídíò ni àbí wọ́n á fẹ́ kàwé? Kí ni wọ́n á fẹ́ nawọ́ gán, ṣé fóònù ni àbí ìwé?

 Láti ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́yìn làwọn nǹkan míì kì í ti í jẹ́ káwọn èèyàn ráyè kàwé, ó bẹ̀rẹ̀ látorí tẹlifíṣọ̀n tó fi dórí onírúurú nǹkan téèyàn lè ṣe lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì. Nínú ìwé Endangered Minds tí Jane Healy kọ lọ́dún 1990, ó sọ pé: “Tó bá yá, àwọn èèyàn tiẹ̀ lè má kàwé mọ́.”

 Nígbà yẹn, ṣe lọ̀rọ̀ ẹ̀ dà bí àsọdùn lásán. Àmọ́, ní báyìí, tí ọ̀pọ̀ ọdún ti kọjá lẹ́yìn tó sọ̀rọ̀ náà, àwọn olùkọ́ kan láwọn orílẹ̀-èdè táwọn èèyàn tí n lo ohun èèlò ìgbàlódé gan-an ti wá kíyè sí i pé ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́ ò lè kàwé dáadáa tó báwọn èèyàn ṣe ń ṣe tẹ́lẹ̀ mọ́.

Nínú àpilẹ̀kọ yìí

 Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé káwọn ọmọdé máa kàwé?

  •   Ìwé kíkà ń mú kéèyàn ronú. Bí àpẹẹrẹ, tó o bá ń ka ìtàn kan, báwo ni ohùn àwọn tó wà nínú ìtàn náà ṣe ń dún? Báwo ni wọ́n ṣe rí? Báwo ni ibi tí wọ́n wà ṣe rí? Òǹkọ̀wé á sọ díẹ̀ níbẹ̀, ṣùgbọ́n ẹni tó ń kàwé ló máa fi òye gbé èyí tó kù.

     Ìyá kan tó ń jẹ́ Laura sọ pé: “Tá a bá ń wo fídíò, ohun tí ẹlòmíì rò là ń rí. Bó ti wù kí ìyẹn gbádùn mọ́ wa tó, ohun kan wà tó ṣàrà ọ̀tọ̀ nípa ìwé kíkà, ó ń jẹ́ ká fojú inú yàwòrán ohun tí ẹlòmíì sọ.”

  •   Ìwé kíkà ń jẹ́ kéèyàn mọ ìwà hù. Bí àwọn ọmọdé ṣe ń kàwé ni wọ́n á máa mọ bí wọ́n ṣe lè máa ronú lórí ìṣòro àti bí wọ́n ṣe lè yanjú àwọn ìṣòro náà. Káwọn ọmọ sì tó lé kàwé, wọ́n gbọ́dọ̀ máa pọkàn pọ̀. Bí wọ́n sì ṣe ń ṣe bẹ́ẹ̀ ni wọ́n á máa ní àwọn ànímọ́ bíi sùúrù, ìkóra-ẹni-níjàánu àti ìgbatẹnirò.

     Ìgbatẹnirò kẹ̀? Bẹ́ẹ̀ ni! Àwọn kan tó ń ṣèwádìí gbà pé báwọn ọmọdé ṣe rọra ń ka ìtàn tí wọ́n sì ń fọkàn bá ìtàn náà lọ máa ń mú kí wọ́n ronú nípa bí nǹkan ṣe rí lára àwọn tó wà nínú ìtàn tí wọ́n ń kà. Ìyẹn sì lè ran àwọn ọmọ lọ́wọ́ láti máa fi ìgbatẹnirò hàn fáwọn èèyàn tí nǹkan bá jọ dà wọ́n pọ̀.

  •   Ìwé kíkà ń mú kéèyàn ronú jinlẹ̀. Àwọn tó ń fara balẹ̀ kàwé kì í kánjú, kódà wọ́n lè tún ibì kan kà tó bá gba pé kí wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀, kí wọ́n lè lóye ohun tí òǹkọ̀wé ń sọ. Bí wọ́n ṣe ń kàwé lọ́nà yẹn lè mú kí wọ́n rántí ohun tí wọ́n kà kó sì ṣe wọ́n láǹfààní.—1 Tímótì 4:15.

     Bàbá kan tó ń jẹ́ Joseph sọ pé: “Tó o bá ń kàwé, wàá lè ronú lórí ìtumọ̀ ohun tó o kà, wàá lè fi wé ohun tó o mọ̀, wàá sì ronú lórí ẹ̀kọ́ tó o lè rí kọ́ níbẹ̀. Fídíò kì í sábà mú kéèyàn ronú jinlẹ̀ lọ́nà yẹn.”

 Ohun tó yẹ kó o fi sọ́kàn: Bó tilẹ̀ jẹ́ pé fídíò àtàwọn nǹkan míì bíi tẹlifíṣọ̀n náà wúlò, àwọn ọmọ rẹ lè máa pàdánù ohun tó ṣe pàtàkì bí wọ́n kì í bá wáyè kàwé.

 Bó o ṣe lè mú káwọn ọmọ máa kàwé

  •   Tètè bẹ̀rẹ̀. Ìyá kan tó ń jẹ́ Chloe tó láwọn ọmọkùnrin méjì sọ pé: “Látìgbà tí mo bá ti lóyún àwọn ọmọ wa sínú la ti ń kàwé fún wọn, àá sì tún máa ṣe bẹ́ẹ̀ nìṣó lẹ́yìn tá a bá ti bí wọn. Inú wa dùn pé a ò dáwọ́ dúró. Bí àkókò ti ń lọ, wọ́n wá ń kàwé déédéé, ì báà tiẹ̀ jẹ́ àkàgbádùn lásán.”

     Ìlànà Bíbélì: “Láti kékeré jòjòló lo ti mọ ìwé mímọ́.”—2 Tímótì 3:15.

  •   Jẹ́ kí ìwé tí wọ́n lè kà máa wà nínú ilé. Kó lè rọrùn fún ọmọ rẹ láti máa kàwé, jẹ́ kí ìwé tó lè kà máa wà nínú ilé. Ìyá ọlọ́mọ mẹ́rin kan tó ń jẹ́ Tamara, sọ pé: “Bá ọmọ rẹ wá ìwé táá gbádùn mọ́ ọn kó o sì fi ìwé náà sí ẹ̀gbẹ́ ibùsùn rẹ̀.”

     Ìlànà Bíbélì: “Tọ́ ọmọdé ní ọ̀nà tó yẹ kó tọ̀. Kódà tó bá dàgbà, kò ní kúrò nínú rẹ̀.”—Òwe 22:6.

  •   Dín lílo Íńtánẹ́ẹ̀tì kù. Bàbá kan tó ń jẹ́ Daniel dámọ̀ràn pé kí ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ kan wà ti ẹnikẹ́ni ò ní máa lo fóònù tàbí ẹ̀rọ ìgbàlódé. Ó sọ pé: “Bí ò tiẹ̀ ju ẹ̀ẹ̀kan lọ lọ́sẹ̀, ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ kan wà tí a kì í wo tẹlifíṣọ̀n rárá. Gbogbo wa jọ ń fi àkókò yẹn kàwé tàbí kí oníkálùkù ka tiẹ̀.”

     Ìlànà Bíbélì: “Máa wádìí dájú àwọn ohun tó ṣe pàtàkì jù.”—Fílípì 1:10.

  •   Fi àpẹẹrẹ lélẹ̀. Ìyá àwọn ọmọbìnrin méjì kan tó ń jẹ́ Karina dámọ̀ràn pé: “Jẹ́ kí ọ̀nà tó o gbà ń kàwé àti bó o ṣe ń fi ìdùnnú hàn torí ohun tó ò ń kà mú kí ìtàn náà yé àwọn ọmọ rẹ kedere. Tó o bá nífẹ̀ẹ́ àtimáa kàwé, àwọn ọmọ rẹ lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rẹ.”

     Ìlànà Bíbélì: “Máa tẹra mọ́ kíkàwé fún ìjọ.”—1 Tímótì 4:13.

 Gbogbo ọmọ kọ́ ló máa fẹ́ràn ìwé kíkà. Ṣùgbọ́n ìṣírí tó o bá fún àwọn ọmọ rẹ lè mú kó wù wọ́n láti máa kàwé. Bàbá àwọn ọmọbìnrin méjì kan tó ń jẹ́ David, tún ṣe ohun kan tó yàtọ̀. Ó sọ pé: “Mo máa ń ka ohun tí mo bá rí pé àwọn ọmọ mi ń kà, ìyẹn ń jẹ́ kí n mọ ohun tí wọ́n fẹ́, ó sì ń jẹ́ ká rí nǹkan sọ̀rọ̀ lé lórí. Ṣe ló dà bí ìgbà tá a dá ẹgbẹ́ òǹkàwé kékeré tiwa sílẹ̀ nínú ilé. A máa ń gbádùn ẹ̀ gan-an ni!”