Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Ìgbà Wo Ni Ọlọ́run Bẹ̀rẹ̀ Sí Í Dá Àgbáálá Ayé?

Ìgbà Wo Ni Ọlọ́run Bẹ̀rẹ̀ Sí Í Dá Àgbáálá Ayé?

Ohun tí Bíbélì sọ

Bíbélì ò sọ ìgbà tí Ọlọ́run bẹ̀rẹ̀ sí í dá àgbáálá ayé wa yìí tàbí bó ṣe pẹ́ tó. Ohun tó sọ ni pé: “Ní ìbẹ̀rẹ̀, Ọlọ́run dá ọ̀run àti ayé.” (Jẹ́nẹ́sísì 1:1) Bíbélì ò sọ ìgbà tí “ìbẹ̀rẹ̀” yẹn jẹ́ gan-an. Ṣùgbọ́n, bí Ọlọ́run ṣe dá àwọn nǹkan ní ṣíṣẹ̀-n-tẹ̀lé nínú Jẹ́nẹ́sísì jẹ́ ká mọ̀ pé ó ti bẹ̀rẹ̀ ṣáájú àkókò tàbí “àwọn ọjọ́” ìṣẹ̀dá mẹ́fà náà.

 Ṣé ọjọ́ oníwákàtí mẹ́rìnlélógún ni àwọn ọjọ́ ìṣẹ̀dá mẹ́fà náà?

Rárá o. Tí Bíbélì bá lo ọ̀rọ̀ náà “ọjọ́,” ó lè túmọ̀ sí àwọn àkókò tí gígùn wọn yàtọ̀ síra. Ọ̀rọ̀ tó bá sọ débẹ̀ la máa fi mọ bó ṣe gùn tó. Bí àpẹẹrẹ, ibì kan nínú àkọsílẹ̀ náà pe gbogbo ọjọ́ ìṣẹ̀dá mẹ́fà náà ní ọjọ́ kan.​—Jẹ́nẹ́sísì 2:4.

 Kí ló ṣẹlẹ̀ ní ọjọ́ ìṣẹ̀dá mẹ́fà náà?

Ọlọ́run sọ ayé tó ‘wà ní bọrọgidi tó sì ṣófo’ di ibi tí àwọn ohun alààyè á máa gbé. (Jẹ́nẹ́sísì 1:2) Lẹ́yìn náà ló dá àwọn ohun alààyè sórí ilẹ̀ ayé. Bíbélì ṣàlàyé àpapọ̀ àwọn ohun tó ṣẹlẹ̀ láwọn ọjọ́ kọ̀ọ̀kan nínú ọjọ́ mẹ́fà tí Ọlọ́run fi dá àwọn nǹkan:

  • Ọjọ́ 1: Ọlọ́run mú kí ìmọ́lẹ̀ tàn dé ayé, àtìgbà yẹn la ti bẹ̀rẹ̀ sí í ni ọ̀sán àti òru.​—Jẹ́nẹ́sísì 1:3-5..

  • Ọjọ́ 2: Ọlọ́run ṣe òfúrufú, ó pààlà sáàárín omi tó wà lókè òfúrufú àti omi tó wà ní ìsàlẹ̀ rẹ̀.​—Jẹ́nẹ́sísì 1:6-8.

  • Ọjọ́ 3: Ọlọ́run mú kí ilẹ̀ fara hàn. Ó sì tún dá ewéko.​—Jẹ́nẹ́sísì 1:9-13.

  • Ọjọ́ 4: Ọlọ́run dá oòrùn, òṣùpá àti àwọn ìràwọ̀ gẹ́gẹ́ bí orísun ìmọ́lẹ̀, ó sì mú kí wọ́n ṣeé fojú rí látorí ilẹ̀ ayé.​—Jẹ́nẹ́sísì 1:14-19.

  • Ọjọ́ 5: Ọlọ́run dá àwọn ohun alààyè tó ń gbé inú omi àti àwọn ẹ̀dá tó ń fò.​—Jẹ́nẹ́sísì 1:20-23.

  • Ọjọ́ 6: Ọlọ́run dá àwọn ẹran orí ilẹ̀ àti èèyàn.​—Jẹ́nẹ́sísì 1:24-31.

Ní òpin ọjọ́ kẹfà, Ọlọ́run sinmi iṣẹ́ tó ti ṣe, kò sì dá ohunkóhun mọ́.​—Jẹ́nẹ́sísì 2:1, 2.

 Ṣé ohun tó wà nínú Jẹ́nẹ́sísì bá ìwádìí ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì mu?

Bíbélì ò ṣe àlàyé kúlẹ̀kúlẹ̀ nípa bí Ọlọ́run ṣe dá ayé bíi èyí táwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì máa ń ṣe. Ńṣe ló sọ bí Ọlọ́run ṣe dá àwọn nǹkan lọ́nà táá fi rọrùn fún àwọn tó ń ka Bíbélì láti lóye bó ṣe dá wọn ní ṣíṣẹ̀-n-tẹ̀lé. Kódà, ó rọrùn fáwọn tó ń kà á láyé ìgbà tí wọ́n kọ Bíbélì láti lóye rẹ̀. Ohun tí Bíbélì sọ nípa bí Ọlọ́run ṣe dá àwọn nǹkan ò ta ko ìwádìí ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì tó ṣeé gbára lé. Robert Jastrow tó jẹ́ onímọ̀ nípa sánmà sọ pé: “Àlàyé tí Bíbélì ṣe nípa ìṣẹ̀dá àtèyí táwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ṣe kò bára mu, ṣùgbọ́n ohun tí wọ́n sọ nípa bí ìṣẹ̀dá ṣe bẹ̀rẹ̀ bára mu; ìgbà kan pàtó ni ìṣẹ̀dá bẹ̀rẹ̀, ó sì ṣẹlẹ̀ ní kánmọ́, kó tó wá di pé èèyàn dé ayé yìí.”

 Ìgbà wo ni Ọlọ́run dá oòrùn, òṣùpá àti àwọn ìràwọ̀?

Oòrùn, òṣùpá àti àwọn ìràwọ̀ ti wà tẹ́lẹ̀ lára “ọ̀run” tí Ọlọ́run dá ní “ìbẹ̀rẹ̀.” (Jẹ́nẹ́sísì 1:1) Ṣùgbọ́n, ó dájú pé ìmọ́lẹ̀ wọn kò tàn dé ayé torí pé kùrukùru bo ojú ọ̀run. (Jẹ́nẹ́sísì 1:2) Torí náà, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìmọ́lẹ̀ tàn yàn-àn ní ọjọ́ kìíní, kò ṣeé ṣe láti mọ ibi tí ìmọ́lẹ̀ náà ti wá. Ní ọjọ́ kẹrin, ojú ọ̀run ti mọ́ kedere. Bíbélì sọ pé oòrùn, òṣùpá àti àwọn ìràwọ̀ wá bẹ̀rẹ̀ sí í “tàn sórí ayé,” bó ṣe máa rí lójú ẹni tó bá ń wò ó láti ayé níbí.​—Jẹ́nẹ́sísì 1:17.

 Kí ni Bíbélì sọ nípa bó ṣe pẹ́ tó tí ayé ti wà?

Bíbélì ò sọ bó ṣe pẹ́ tó tí ayé ti wà. Ohun tí Jẹ́nẹ́sísì 1:1 sọ ò ju pé àgbáálá ayé yìí àti ilẹ̀ ayé tá a wà yìí ní ìbẹ̀rẹ̀. Gbólóhùn yìí ò ta ko ìlànà ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì èyíkéyìí tó ṣeé gbára lé, kò sì ta ko iye ọdún táwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì fojú bù ú pé ayé ti wà.