Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Ṣé Èèyàn Rere Nìkan Ni Jésù?

Ṣé Èèyàn Rere Nìkan Ni Jésù?

Ohun Tí Bíbélì Sọ

 Jésù kì í ṣe èèyàn rere nìkan. Ó ṣe tàn, òun ló ṣì nípa lórí ìgbésí ayé àwọn èèyàn jù lọ nínú ìtàn aráyé. Wo ohun tí àwọn òpìtàn àtàwọn òǹkọ̀wé tó gbajúmọ̀ gan-an sọ nípa rẹ̀:

 Òpìtàn ọmọ ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì náà, H. G. Wells, sọ pé: “Jésù ará Násárétì . . . ló ṣe pàtàkì jù lọ nínú ìtàn aráyé.”

 Òpìtàn àti òǹkọ̀wé ọmọ ilẹ̀ Amẹ́ríkà náà, Kenneth Scott Latourette sọ pé: “Nínú gbogbo àwọn tó o ti gbé láyé rí, Jésù ló ṣì nípa lórí ìgbésí ayé àwọn èèyàn jù lọ, ipa tó ní sì ń pọ̀ sí i.”

 Bíbélì sọ ìdí tí Jésù fi nípa lórí aráyé ju gbogbo àwọn èèyàn rere tó ti gbé ayé lọ. Nígbà tí Jésù bi àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ tó sún mọ́ ọn jù lọ nípa ẹni tí wọ́n rò pé òun jẹ́, ọ̀kan lára wọn dáhùn lọ́nà tó tọ́ pé: “Ìwọ ni Kristi náà, Ọmọ Ọlọ́run alààyè.”—Mátíù 16:16.