Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Kí Ni Bíbélì Sọ Nípa Ìgbéyàwó Àwọn Tí Kì í Ṣe Ẹ̀yà Kan Náà?

Kí Ni Bíbélì Sọ Nípa Ìgbéyàwó Àwọn Tí Kì í Ṣe Ẹ̀yà Kan Náà?

Ohun tí Bíbélì sọ

 Ọlọ́run fọwọ́ sí ìgbéyàwó láàárín ọkùnrin àti obìnrin ti kì í ṣe ẹ̀yà kan náà torí pé bákan náà ni gbogbo ẹ̀yà rí lójú rẹ̀. Bíbélì sọ pé: “Ọlọ́run kì í ṣe ojúsàájú . . . , láìbeere orílẹ̀-èdè tí ó jẹ́.”—Ìṣe 10:34, 35, Bíbélì Ìròhìn Ayọ̀.

 Tún wo àwọn ìlànà Bíbélì míì tó ní í ṣe pẹ̀lú ọ̀rọ̀ ẹ̀yà àti ìgbéyàwó.

Ọ̀dọ̀ ẹnì kan náà ní gbogbo ẹ̀yà pátá ti wá

 Ọ̀dọ̀ ọkùnrin tí Ọlọ́run kọ́kọ́ dá tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Ádámù àti Éfà ìyàwó rẹ̀ tí Bíbélì pè ní “ìyá gbogbo ẹni tí ń bẹ láàyè,” ni gbogbo èèyàn ti wá. (Jẹ́nẹ́sísì 3:20) Torí ìdí èyí, Bíbélì sọ nípa Ọlọ́run pé: “Láti ara ọkùnrin kan ni ó sì ti dá gbogbo orílẹ̀-èdè àwọn ènìyàn.” (Ìṣe 17:26) Ẹ̀yà yòówù kí ẹnì kan jẹ́, ọmọ ìyá kan náà ni gbogbo wa pátá. Àmọ́, kí ló yẹ kó o ṣe tí ẹ̀tanú tàbí ìwà kẹ́lẹ́gbẹ́mẹgbẹ́ bá gbilẹ̀ gan-an ní àdúgbò rẹ?

Àwọn tó gbọ́n máa “ń fikùn lukùn”

 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Ọlọ́run fọwọ́ sí ìgbéyàwó àwọn tí kì í ṣe ẹ̀yà kan náà, kì í ṣe gbogbo èèyàn ló fara mọ́ èrò Ọlọ́run. (Aísáyà 55:8, 9) Tó bá wù ọ́ kó o fẹ́ ẹ̀yà míì, kí ìwọ àti ẹni tó o fẹ́ fi ṣe ọkọ tàbí aya jọ jíròrò àwọn ìbéèrè yìí:

  •   Kí lẹ máa ṣe tí àwọn tó wà ní àdúgbò yín tàbí àwọn ẹbí yín bá ń yọ yín lẹ́nu lórí ọ̀rọ̀ ẹ̀yà?

  •   Báwo lẹ ṣe máa ran àwọn ọmọ yín lọ́wọ́ láti kojú ìwà ẹ̀tanú tí wọ́n bá hù sí wọn?

 Tí ẹ bá “fikùn lukùn” lọ́nà yìí, ìgbéyàwó yìn á yọrí sí rere.—Òwe 13:10; 21:5.