Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Báwo Ni Àwọn Òbí Ṣe Lè Kọ́ Àwọn Ọmọ Wọn Nípa Ìbálòpọ̀?

Báwo Ni Àwọn Òbí Ṣe Lè Kọ́ Àwọn Ọmọ Wọn Nípa Ìbálòpọ̀?

Ohun tí Bíbélì sọ

 Ta ló yẹ kó kọ́ àwọn ọmọ nípa ìbálòpọ̀? Àwọn òbí ni Bíbélì gbé iṣẹ́ yìí lé lọ́wọ́. Ọ̀pọ̀ obí ti rí i pé àwọn àbá tó wà nísàlẹ̀ yìí wúlò gan-an:

  •   Má ṣe jẹ́ kójú tì ẹ́. Bíbélì kò fọ̀rọ̀ sábẹ́ ahọ́n sọ nípa ìbálòpọ̀ takọtabo àti àwọn ẹ̀ya ìbímọ, torí Ọlọ́run sọ fún orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì pé wọ́n gbọ́dọ̀ kọ́ “àwọn ọmọ kéékèèké” nípa àwọn nǹkan wọ̀nyí. (Diutarónómì 31:12; Léfítíkù 15:2, 16-​19) O lè lo àwọn èdè tó ń fi ọ̀wọ̀ hàn fún ìbálòpọ̀ tàbí tí kò sọ àwọn ẹ̀yà ara ìkọ̀kọ̀ di ohun ìtìjú.

  •   Máa kọ́ ọmọ rẹ díẹ̀díẹ̀. Dípò tí wàá fi sọ gbogbo ọ̀rọ̀ nípa ìbálòpọ̀ fún ọmọ rẹ lọ́jọ́ kan ṣoṣo, ńṣe ni kó o máa bá ọmọ rẹ̀ sọ ọ́ díẹ̀díẹ̀ bí wọ́n ṣe ń bàlágà, bí ọmọ rẹ bá ṣe lè lóye rẹ̀ tó ni kó o ṣe ṣàlàyé fún un tó nípa rẹ̀.​—1 Kọ́ríńtì 13:11.

  •   Kọ́ wọn ní ìwà ọmọlúwàbí. Àwọn ọmọ lè kẹ́kọ̀ọ́ nípa ìbálòpọ̀ ní ilé ẹ̀kọ́. Àmọ́, Bíbélì rọ àwọn òbí pé kí wọ́n kọ́ àwọn ọmọ wọn nípa àwọn ẹ̀yà ara tó wà fún ìbálòpọ̀, ojú tó yẹ kí wọ́n máa fi wo ìbálòpọ̀ àti bó ṣe yẹ kí wọ́n hùwà tó bá di ọ̀ràn ìbálòpọ̀.​—Òwe 5:1-​23.

  •   Tẹ́tí sí ohun tí ọmọ rẹ fẹ́ sọ. Má ṣe bínú sódì tàbí kó o yára parí èrò sí pé ọmọ rẹ ti ń ṣèṣekúṣe tó bá bi ọ́ ní ìbéèrè èyíkéyìí nípa ìbálòpọ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, “yára nípa ọ̀rọ̀ gbígbọ́, lọ́ra nípa ọ̀rọ̀ sísọ.”​—Jákọ́bù 1:19.

Bí o ṣe lè dáàbò bo ọmọ rẹ lọ́wọ́ àwọn tó ń bá ọmọdé ṣèṣekúṣe

Kọ́ ọmọ rẹ ọkùnrin tàbí obìnrin bó ṣe máa dènà ẹni tó bá fẹ́ fipá bá a ṣèṣekúṣe

  •   Túbọ̀ kẹ́kọ̀ọ́ sí i. Mọ ọgbọ́n táwọn tó ń bọ́mọdé ṣèṣekúṣe ń dá.​—Òwe 18:15; wo orí 32 nínú ìwé náà, Àwọn Ìbéèrè Tí Àwọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè—Àwọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́, Apá Kìíní.

  •   Má ṣe dá ọmọ rẹ dá ọ̀rọ̀ ara rẹ̀. Kìkì àwọn tó o bá fọkàn tan ni kó o máa jẹ́ kó bá ọ bójú tó ọmọ rẹ, má sì ṣe “jọ̀wọ́ [ọmọ rẹ] sílẹ̀ fàlàlà.”​—Òwe 29:15.

  •   Kọ́ ọmọ rẹ kó lè mọ ìgbà tó tọ́ láti ṣègbọràn àti ìgbà tí kò tọ́. Àwọn ọmọ ní láti gbọ́rọ̀ sí àwọn òbí wọn lẹ́nu. (Kólósè 3:20) Síbẹ̀, bí o bá kọ́ ọmọ rẹ pé ó gbọ́dọ̀ máa ṣègbọràn sí àgbàlagbà èyíkéyìígbogbo ìgbà, ó lè kó sọ́wọ́ àwọn tó ń bá ọmọdé ṣèṣekúṣe. Àwọn òbí ní láti sọ fún àwọn ọmọ wọn pé, “Bí ẹnikẹ́ni bá sọ fún ẹ pé kó o ṣe ohun tí Ọlọ́run sọ pé kò dáa, o kò gbọ́dọ̀ ṣe é.”​—Ìṣe 5:29.

  •   Ẹ jọ ṣè ìdánrawò bí ó ṣe lè dáàbò bo ara rẹ̀. Kọ́ ọmọ rẹ ní àwọn nǹkan tó lè ṣe bí ẹnikẹ́ni bá fi ìṣekúṣe lọ̀ ọ́ nígbà tí o kò sí níbẹ̀. Jẹ́ kí ọmọ rẹ fi bó ṣe máa dènà ẹni tó fẹ́ bá a ṣèṣekúṣe hàn ọ́. Èyí á jẹ́ kó lè ní ìgboyà láti sọ pé “Rárá o! Màá fẹjọ́ yín sùn!” Tí yóò sì tètè sá kúrò níbẹ̀. O lè gba pé kó o máa “fi ìtẹnumọ́ gbìn [ọ̀rọ̀ náà] sínú ọmọ rẹ,” torí ó lè tètè gbàgbé rẹ̀.​—Diutarónómì 6:7.