Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

ÀLÀYÉ ÀWỌN ẸSẸ BÍBÉLÌ

Gálátíà 6:9—“Kí Á Má Ṣe Jẹ́ Kí Ó Sú Wa Láti Ṣe Rere”

Gálátíà 6:9—“Kí Á Má Ṣe Jẹ́ Kí Ó Sú Wa Láti Ṣe Rere”

 “Ẹ má ṣe jẹ́ kí a jáwọ́ nínú ṣíṣe rere, torí tí àkókò bá tó, a máa kórè rẹ̀ tí a ò bá jẹ́ kó rẹ̀ wá.”​—Gálátíà 6:9, Ìtumọ̀ Ayé Tuntun.

 “Kí á má ṣe jẹ́ kí ó sú wa láti ṣe rere, nítorí nígbà tí ó bá yá, a óo kórè rẹ̀, bí a kò bá jẹ́ kí ó rẹ̀ wá.”​—Gálátíà 6:9, Yoruba Bible.

Ìtumọ̀ Gálátíà 6:9

 Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù gba àwọn Kristẹni níyànjú pé kí wọ́n má jẹ́ kó sú wọn láti máa ṣe ohun tó dáa lójú Ọlọ́run. Tí wọ́n bá ṣe bẹ́ẹ̀, ó dájú pé Jèhófà máa san wọ́n lẹ́san.

 “Ẹ má ṣe jẹ́ kí a jáwọ́.” A tún lè túmọ̀ ọ̀rọ̀ yìí sí “kí á ma ṣe jẹ́ kí ó sú wa.” Ọ̀rọ̀ Gíríìkì tí Pọ́ọ̀lù lò nínú ẹsẹ Bíbélì yìí tún lè túmọ̀ sí kéèyàn má rẹ̀wẹ̀sì tàbí kó má jẹ́ kí ìtara ẹ̀ dín kù. Bí Pọ́ọ̀lù ṣe pe ọ̀rọ̀ yìí mọ́ ara ẹ̀ jẹ́ ká rí i pé àwọn ìgbà kan wà tí òun náa ní láti jà fitafita kó má bàa rẹ̀wẹ̀sì.​—Róòmù 7:21-24.

 “Ṣíṣe rere,” tàbí ṣíṣe ohun tó dáa kan gbogbo ohun tó yẹ kí Kristẹni kan ṣe nínú ìjọsìn Ọlọ́run. Lára irú nǹkan bẹ́ẹ̀ ni àwọn ohun téèyàn bá ṣe láti ran àwọn Kristẹni àtàwọn mìí lówọ́.​—Gálátíà 6:10.

 “Tí àkókò bá tó, a máa kórè rẹ̀ tí a ò bá jẹ́ kó rẹ̀ wá.” Pọ́ọ̀lù rán àwọn tó ń gbórọ̀ ẹ̀ létí pé bó ṣe máa ń gba àkókò kí ohun tí àgbẹ̀ kan gbìn tó méso jáde bẹ́ẹ̀ náà ló ṣe máa ń gba àkókò kéèyan tó rí àǹfààní tó wà nínú ṣíṣe rere. Bí Pọ́ọ̀lù ṣe sọ̀rọ̀ nípa ohun tá a máa kórè, ṣe ló ń fìdí ohun tó sọ ní ẹsẹ 7 múlẹ̀ pé: “Ohun tí èèyàn bá gbìn, òun ló máa ká.” Lédè míì tí Kristẹni kan bá ń ṣe ohun tó dáa lójú Ọlọ́run, ọ̀pọ̀ nǹkan ni Ọlọ́run fi máa san án lẹ́san, á sì fún un ní ìyè àìnípẹ̀kun.​—Róòmù 2:6, 7; Gálátíà 6:8.

Àwọn Ẹsẹ Tó Ṣáájú Àtèyí Tó Tẹ̀ Lé Gálátíà 6:9

 Nńkan bí ọdún 50 sí 52 Sànmánì Kristẹni ní Pọ́ọ̀lù kọ lẹ́tà yìí sí àwọn Kristẹni tó ń gbé nílùú Gálátíà. Ó kọ lẹ́tà yìí kó lè kìlọ̀ nípa àwọn kan tó ń pera wọn ní Kristẹni àmọ́ tí wọ́n ń sọ ohun tí kì í ṣòótọ́ nípa Jésù. (Gálátíà 1:6, 7) Àwọn olùkọ́ èké yìí ń kọ́ni pé ó pọn dandan káwọn Kristẹni máa ṣègboràn sí Òfin Mósè tí Ọlọ́run fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì. (Gálátíà 2:15, 16) Pọ́ọ̀lù wá ṣàlàyé pé òfin náà ti parí iṣẹ́ ẹ̀ àti pé àwọn Kristẹ́ni ò sí lábẹ́ òfin yìí mọ́.​—Róòmù 10:4; Gálátíà 3:23-25.

 Kì í ṣe ọ̀rọ̀ pípa Òfin Mósè mọ́ ni Pọ́ọ̀lù ní lọ́kàn nígbà tó rọ àwọn Kristẹni pé kí wọ́n má ṣe “jáwọ́ nínú ṣíṣe rere.” Ohun tó ń rọ̀ wọ́n pé kí wọ́n ṣe ni pé kí wọ́n “mú òfin Kristi ṣẹ.” Ìyẹn sì gba pé kí wọ́n máa ṣègbọràn sí gbogbo ohun tí Jésù sọ nípa bá a ṣe lè máa ṣe rere fáwọn èèyàn.​—Gálátíà 6:2; Mátíù 7:12; Jòhánù 13:34.

 Wo fídíò yìí kó o lè mọ ohun tó wà nínú ìwé Gálátíà.