Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ṣé Ẹ̀sìn Ti Wá Di Òwò Tó Ń Mówó Rẹpẹtẹ Wọlé?

Ṣé Ẹ̀sìn Ti Wá Di Òwò Tó Ń Mówó Rẹpẹtẹ Wọlé?

 Ṣé o ti kíyè sí i pé dípò kí ọ̀pọ̀ ẹ̀sìn máa kọ́ àwọn èèyàn bí wọ́n á ṣe sin Ọlọ́run, ṣe ló jọ pé owó ni wọ́n ń kó jọ? Wọ́n ń polówó ọjà, wọ́n ń tajà, wọ́n sì ń fi ẹ̀sìn pawó. Ọ̀pọ̀ lára àwọn olórí ẹ̀sìn ló ń gba owó gọbọi, wọ́n sì ń ra àwọn nǹkan olówó ńlá láti fi gbádùn ara wọn. Àpẹẹrẹ mélòó kan rèé:

  •   Ìwádìí kan tí wọ́n ṣe fi hàn pé láàárín ọdún mẹ́tàlá bíṣọ́ọ̀bù kan ní Kátólíìkì fi owó ṣọ́ọ̀ṣì rẹ̀ sanwó fún ọkọ̀ òfúrufú àdáni tó fi rìnrìn àjò ní nǹkan bí àádọ́jọ [150] ìgbà àti ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ bọ̀gìnnì tó gùn ní ọgọ́rùn-ún méjì [200] ìgbà. Ó tún fi owó tó lé ní mílíọ̀nù mẹ́rin dọ́là [ìyẹn ohun tó lé ní bílíọ̀nù kan ààbọ̀ Náírà] ṣe àtúnṣe ilé tí ìjọ kọ́ fún un.

  •   Oníwàásù kan wà lórílẹ̀-èdè kan nílẹ̀ Áfíríkà tó ní àwọn ọmọ ìjọ tó pọ̀ gan-an. Ọ̀pọ̀ nǹkan ni wọ́n máa ń tà nínú ọgbà ṣọ́ọ̀ṣì ńlá tó kọ́, irú bí “òróró ìyanu,” aṣọ ìnura àti àwọn ṣẹ́ẹ̀tì tí wọ́n ya fọ́tò rẹ̀ sí. Ó ní ọrọ̀ rẹpẹtẹ bó tiẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ lára àwọn tó ń lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì rẹ̀ jẹ́ tálákà.

  •   Méjì lára orí òkè mímọ́ mẹ́rin tó jẹ́ tàwọn ẹlẹ́sìn Búdà lórílẹ̀-èdè Ṣáínà wà lára ibi táwọn èèyàn kà sí ilé iṣẹ́ ńlá. Oríṣiríṣi òwò tó ń mówó wọlé ni Tẹ́ńpìlì Shaolin tó gbajúmọ̀ jù lọ lórí àwọn òkè náà máa ń lọ́wọ́ sí, kódà “ọ̀gá oníṣòwò” ni ọ̀pọ̀ èèyàn máa ń pe olórí Tẹ́ńpìlì Shaolin yẹn.

  •   Ní báyìí, àwọn woṣẹ́woṣẹ́ ti wà lára àwọn oníṣòwò tó ń rí tajé ṣe lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà. Ìwádìí kan fi hàn pé wọ́n mú lára ààtò àwọn ẹlẹ́sìn láti gbé àwọn ètùtù kan kalẹ̀, wọ́n máa ń ṣe àwọn ètùtù yìí fáwọn tó bá wá ìrànlọ́wọ́ wá sọ́dọ̀ wọn.

 Kí lèrò rẹ nípa àwọn ẹ̀sìn tó ti tara bọ ìṣòwò? Ṣé o ti ronú rí nípa ojú tí Ọlọ́run fi ń wo àwọn tó ń fi ẹ̀sìn bojú kí wọ́n lè máa pawó?

Ojú wo ni Ọlọ́run fi ń wo dída ẹ̀sìn pọ̀ mọ́ ìṣòwò?

 Ọlọ́run ò fẹ́ ká máa da ẹ̀sìn pọ̀ mọ́ ìṣòwò. Bíbélì fi hàn pé nígbà àtijọ́, inú Ọlọ́run ò dùn sí àwọn àlùfáà tó sọ pé Ọlọ́run làwọn ń ṣojú fún ṣùgbọ́n tí wọ́n ń “gba owó” kí wọ́n tó kọ́ni. (Míkà 3:11) Ọlọ́run ò fọwọ́ sí bí àwọn oníwọra tó ń ṣòwò ní ibi ìjọsìn rẹ̀ ṣe sọ ibẹ̀ di “ihò tí àwọn olè ń fara pa mọ́ sí.”​—Jeremáyà 7:11.

 Bí Ọlọ́run ṣe kórìíra àwọn tó ń fi ẹ̀sìn pawó ni Jésù náà kórìíra wọn. Nígbà tí Jésù wà láyé, àwọn olórí ẹ̀sìn máa ń jèrè lára àwọn olójúkòkòrò tí wọ́n fàyè gbà láti máa ṣòwò nínú tẹ́ńpìlì tó wà ní Jerúsálẹ́mù. Wọ́n ń rẹ́ àwọn olóòótọ́ èèyàn tó wá jọ́sìn Ọlọ́run níbẹ̀ jẹ. Jésù fìgboyà lé àwọn oníṣòwò tó ń rẹ́ni jẹ yìí kúrò nínú tẹ́ńpìlì àti àyíká rẹ̀, ó sì sọ fún wọn pé: “Ẹ yéé sọ ilé Baba mi di ilé ìtajà!”​—Jòhánù 2:​14-16.

 Àwọn ohun tí Jésù ṣe nígbà iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ jẹ́ ká mọ ojú tí Ọlọ́run fi ń wo nǹkan. (Jòhánù 8:​28, 29) Kì í gbowó lọ́wọ́ àwọn èèyàn tó bá kọ́ wọn ní ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Kò gbowó nígbà tó ṣiṣẹ́ ìyanu, irú bí ìgbà tó bọ́ àwọn tí ebi ń pa, tó mú àwọn aláìsàn lára dá tó sì jí àwọn òkú dìde. Jésù ò lo ìwàásù rẹ̀ láti kó ọrọ̀ jọ, kódà kò nílé tara rẹ̀.​—Lúùkù 9:58.

Ṣé àwọn tó kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ ẹ̀sìn Kristẹni da ẹ̀sìn pọ̀ mọ́ ìṣòwò?

 Jésù sọ fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé kí wọ́n má ṣe fi ẹ̀sìn kó owó jọ. Ó sọ pé: “Ọ̀fẹ́ ni ẹ gbà á, ọ̀fẹ́ ni kí ẹ fúnni.” (Mátíù 10:8) Àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù nígbà yẹn, tá a wá mọ̀ sí Kristẹni, tẹ̀ lé ìtọ́ni tí Jésù fún wọn. Àpẹẹrẹ mélòó kan rèé:

  •   Ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Símónì fún àpọ́sítélì Pétérù, tó jẹ́ ọmọlẹ́yìn Jésù, ni owó, torí pé ó ń fẹ́ ipò àṣẹ àti agbára. Ojú ẹsẹ̀ ni Pétérù kọ ohun tí Símónì fi lọ̀ ọ́, ó bá a wì gidigidi, ó sì sọ fún un pé: “Kí fàdákà rẹ ṣègbé pẹ̀lú rẹ, torí o rò pé o lè fi owó ra ẹ̀bùn ọ̀fẹ́ Ọlọ́run.”​—Ìṣe 8:​18-20.

  •   Òjíṣẹ́ arìnrìn-àjò táwọn èèyàn mọ̀ dáadáa ni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ ọdún ló fi siṣẹ́ kára nínú ọ̀pọ̀ ìjọ Kristẹni, kò fi iṣẹ́ tó ṣe kó owó jọ. Òun àti àwọn tí wọ́n jọ jẹ́ Kristẹni kì í ṣe “akirità ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.” (2 Kọ́ríńtì 2:17) Kàkà bẹ́ẹ̀, Pọ́ọ̀lù sọ pé: “A ṣiṣẹ́ tọ̀sántòru ká má bàa di ẹrù wọ ìkankan nínú yín lọ́rùn, nígbà tí a wàásù ìhìn rere Ọlọ́run fún yín.”​—1 Tẹsalóníkà 2:9.

 Òótọ́ ni pé àwọn Kristẹni yẹn nílò owó tí wọ́n á ná sórí iṣẹ́ ìwàásù tí wọ́n ṣe káàkiri àti bí wọ́n ṣe ń ran àwọn èèyàn lọ́wọ́. Síbẹ̀ wọn kì í ní káwọn èèyàn sanwó fáwọn torí iṣẹ́ Ọlọ́run táwọn ń ṣe. Àmọ́ ẹni tó bá fẹ́ lè fi owó ṣètọrẹ, tí wọ́n bá ṣáà ti tẹ̀ lé àwọn ìlànà yìí:

  •   2 Kọ́ríńtì 8:12: “Nítorí tó bá ti jẹ́ pé ó yá èèyàn lára, á túbọ̀ ṣe ìtẹ́wọ́gbà, ìyẹn tó bá jẹ́ ohun tí èèyàn ní ló fi ṣe é, kì í ṣe ohun tí èèyàn kò ní.”

     Ìtumọ̀: Ìdí téèyàn fi fúnni ṣe pàtàkì ju iye tó fúnni lọ.

  •   2 Kọ́ríńtì 9:7: “Kí kálukú ṣe gẹ́gẹ́ bí ó ti pinnu nínú ọkàn rẹ̀, kì í ṣe pẹ̀lú lílọ́ra tàbí lábẹ́ àfipáṣe, nítorí Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ ẹni tó ń fúnni pẹ̀lú ìdùnnú.”

     Ìtumọ̀: Ọlọ́run ò fẹ́ kí ẹnikẹ́ni fúnni ní ohun tí kò ti ọkàn rẹ̀ wá. Ohun tó fẹ́ ni pé kéèyàn fúnni torí pé ó wù ú pé kó ṣe bẹ́ẹ̀.

Kí ló máa tó ṣẹlẹ̀ sí ẹ̀sìn tó ń fi ìwọra kówó jọ?

 Bíbélì sọ ní kedere pé kì í ṣe gbogbo ẹ̀sìn ni Ọlọ́run tẹ́wọ́ gbà. (Mátíù 7:​21-23) Nínú ìran kan tó kàmàmà, Bíbélì fi gbogbo ẹ̀sìn èké wé aṣẹ́wó torí pé wọ́n ń ṣe wọlé wọ̀de pẹ̀lú ìjọba torí owó tàbí torí àtirí ojúure, wọ́n sì ń gba tọwọ́ àwọn èèyàn. (Ìfihàn 17:​1-3; 18:3) Àsọtẹ́lẹ̀ yẹn tún fi hàn pé Ọlọ́run máa tó pa ìsìn èké run.​—Ìfihàn 17:​15-17; 18:7.

 Ṣùgbọ́n, ní báyìí, Ọlọ́run ò fẹ́ kí ẹ̀sìn èké máa fi ìwà àìtọ́ rẹ̀ tan àwọn èèyàn jẹ tàbí kó mú kó ṣòro fún wọn láti sún mọ́ òun. (Mátíù 24:​11, 12) Ó rọ gbogbo àwọn olóòótọ́ ọkàn pé kí wọ́n kọ́ bí wọ́n ṣe lè sin òun lọ́nà tó ṣètẹ́wọ́gbà kí wọ́n sì jáde kúró nínú ìsìn èké.​—2 Kọ́ríńtì 6:​16, 17.