Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àǹfààní Tí Ikú Jésù Ṣe Wá

Àǹfààní Tí Ikú Jésù Ṣe Wá

 Lẹ́ẹ̀kan lọ́dún, àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà àti ọ̀pọ̀ àwọn tó bá dara pọ̀ mọ́ wa kárí ayé máa ń ṣe Ìrántí Ikú Jésù bó ṣe pa á láṣẹ. (Lúùkù 22:19) Bá a ṣe ń wá síbi ìṣẹ̀lẹ̀ pàtàkì yìí fi hàn pé a mọrírì ohun ribiribi tí Jésù ṣe bó ṣe fi ẹ̀mí rẹ̀ lélẹ̀ fún aráyé. Bákan náà, ó máa jẹ́ ká mọ àǹfààní tí ikú Jésù lè ṣe wá ní báyìí àti ní ọjọ́ iwájú.​—Jòhánù 3:16.

 Kí la lè ṣe ká lè jàǹfààní nínú ikú ìrúbọ Jésù, bóyá a wá síbi ìrántí ikú rẹ̀ àbí a ò ṣe bẹ́ẹ̀? Jésù jẹ́ ká mọ ohun méjì tá a lè ṣe.

  1.  1. Kẹ́kọ́ọ̀ nípa Ọlórun àti Jésù. Nígbà tí Jésù ń gbàdúrà sí Bàbá rẹ̀ ọ̀run, ó sọ pé: “Èyí túmọ̀ sí ìyè àìnípẹ̀kun, pé kí wọ́n wá mọ ìwọ Ọlọ́run tòótọ́ kan ṣoṣo àti Jésù Kristi, ẹni tí o rán.”​—Jòhánù 17:3.

  2.  2. Fi ohun tí ò ń kọ́ sílò. Jésù jẹ́ ká mọ̀ pé ó ṣe pàtàkì ká fi ohun tí à ń kọ́ sílò láyé wa. Bí àpẹẹrẹ, bí Jésù ṣe ń parí Ìwàásù Orí Òkè, ó gbóríyìn fún gbogbo ẹni “tó ń gbọ́ àwọn ọ̀rọ̀ [rẹ̀], tó sì ń ṣe é.” (Lúùkù 6:46-48) Ó tún sọ níbòmíì pé: “Tí ẹ bá mọ àwọn nǹkan yìí, aláyọ̀ ni yín tí ẹ bá ń ṣe wọ́n.”​—Jòhánù 13:17.

 Ṣé wàá fẹ́ kẹ́kọ̀ọ́ sí i nípa Ọlọ́run àti Jésù? Ṣé wàá fẹ́ mọ bó o ṣe lè fi ohun tí ò ń kọ́ sílò? Wo àwọn ohun tó lè ràn ẹ́ lọ́wọ́.

Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì

 Bá a ṣe ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́fẹ̀ẹ́ ti ran ọ̀pọ̀ lọ́wọ́ láti lóye ohun tó wà nínú Bíbélì, wọ́n sì ń fi ohun tí wọ́n ń kọ́ sílò láyé wọn.

Ìpàdé àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

 Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń ṣe ìpàdé lẹ́ẹ̀mejì lọ́sẹ̀ ní àwọn ilé ìpàdé wa. Láwọn ìpàdé yìí, a máa ń jíròrò àwọn ẹ̀kọ́ Bíbélì àti bá a ṣe lè fi wọ́n sílò nígbèésí ayé wa.

 Gbogbo èèyàn ló lè wá sáwọn ìpàdé yìí títí kan àwọn tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Tó o bá fẹ́, o lè dara pọ̀ mọ́ wọn lójúkojú tàbí lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì.

  •   Tó o bá fẹ́ mọ ohun tó o máa gbádùn láwọn ìpàdé wa, wo fídíò náà Kí Ló Máa Ń Ṣẹlẹ̀ Nínú Gbọ̀ngàn Ìjọba?

Àpilẹ̀kọ orí ìkànnì àti fídíò

 Ọ̀pọ̀ àpilẹ̀kọ àti fídíò tó wà lórí ìkànnì yìí máa jẹ́ kó o mọ̀ sí i nípa àwọn ẹ̀kọ́ Jésù àti bí ikú rẹ̀ ṣe lè ṣe ẹ́ láǹfààní.

 Bí àpẹẹrẹ, tó o bá fẹ́ mọ bí ikú ọkùnrin kan ṣe lè ṣe ọ̀pọ̀ èèyàn láǹfààní, ka àpilẹ̀kọ náà “Báwo Ni Jésù Ṣe Ń Gbani Là?” àti “Kí Nìdí Tí Jésù Fi Jìyà Tó sì Kú?” tàbí kó o wo fídíò náà Kí Nìdí Tí Jésù Fi Kú?