Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ẹ̀KỌ́ 25

Kí Nìdí Tá A Fi Ń Kọ́ Àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba, Báwo La sì Ṣe Ń Kọ́ Wọn?

Kí Nìdí Tá A Fi Ń Kọ́ Àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba, Báwo La sì Ṣe Ń Kọ́ Wọn?

Orílẹ̀-èdè Bolivia

Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, bó ṣe rí tẹ́lẹ̀ àti bó ṣe rí báyìí

Orílẹ̀-èdè Tahiti

Bí orúkọ Gbọ̀ngàn Ìjọba ṣe fi hàn, ohun tí à ń jíròrò níbẹ̀ ni ẹ̀kọ́ pàtàkì látinú Bíbélì nípa Ìjọba Ọlọ́run, èyí sì ni ẹ̀kọ́ Jésù dá lé.​—Lúùkù 8:1.

Wọ́n jẹ́ ibi tá a ti ń jọ́sìn Ọlọ́run tòótọ́ ní àdúgbò wa. A máa ń ṣètò iṣẹ́ ìwàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run láwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba wa. (Mátíù 24:14) Àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba máa ń tóbi ju ara wọn lọ, wọ́n yàtọ̀ síra, wọ́n sì máa ń mọ níwọ̀n. Ìjọ tó ń lo ọ̀pọ̀ Gbọ̀ngàn Ìjọba máa ń ju ẹyọ kan lọ. Láwọn ọdún àìpẹ́ yìí, a ti kọ́ ẹgbẹẹgbẹ̀rún Gbọ̀ngàn Ìjọba (tá a bá pín in lọ́gbọọgba, márùn-ún là ń kọ́ lójúmọ́) ká lè rí àyè fún àwọn ìjọ wa tó ń pọ̀ sí i. Kí ló mú kí èyí ṣeé ṣe?​—Mátíù 19:26.

Ọrẹ tí gbogbo wa ń mú wá la fi ń kọ́ wọn. A máa ń fi ọrẹ yìí ránṣẹ́ sí ẹ̀ka ọ́fíìsì wa kí wọ́n lè fi owó ránṣẹ́ sí àwọn ìjọ tó fẹ́ kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba tàbí tí wọ́n fẹ́ tún un ṣe.

Onírúurú èèyàn tó yọ̀ǹda ara wọn láìgbowó ló máa ń kọ́ ọ. Ní ọ̀pọ̀ ilẹ̀, a ti ṣètò Ẹgbẹ́ Àwọn Tí Ń Kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba. Àwùjọ àwọn tó ń kọ́lé àtàwọn tó yọ̀ǹda ara wọn máa ń lọ láti ìjọ kan sí òmíì, kódà wọ́n ń lọ sí àwọn ibi tó jìnnà ní orílẹ̀-èdè kan náà, kí wọ́n lè ran àwọn ìjọ lọ́wọ́ láti kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba wọn. Ní àwọn ilẹ̀ míì, àwọn arákùnrin tí wọ́n kọ́ṣẹ́ mọṣẹ́ máa ń bójú tó kíkọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba àti ṣíṣe àtúnṣe sí àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba tó wà lágbègbè kan. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ máa ń yọ̀ǹda ara wọn láwọn ibi tá a ti ń kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba, àwọn ará ìjọ tó máa lo gbọ̀ngàn náà ló máa ń pọ̀ jù lára àwọn tó ń ṣiṣẹ́ náà. Ẹ̀mí Jèhófà àti iṣẹ́ àṣekára táwọn èèyàn rẹ̀ ṣe tinútinú ló ń mú kí gbogbo èyí ṣeé ṣe.​—Sáàmù 127:1; Kólósè 3:23.

  • Kí nìdí tá a fi ń pe ilé ìjọsìn wa ní Gbọ̀ngàn Ìjọba?

  • Kí ló mú kó ṣeé ṣe fún wa láti kọ́ àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba káàkiri ayé?