Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ẹ̀KỌ́ 5

Kí Lo Máa Gbádùn Láwọn Ìpàdé Wa?

Kí Lo Máa Gbádùn Láwọn Ìpàdé Wa?

Orílẹ̀-èdè Ajẹntínà

Orílẹ̀-èdè Sierra Leone

Orílẹ̀-èdè Belgium

Orílẹ̀-èdè Malaysia

Ọ̀pọ̀ èèyàn ni kì í lọ sí ilé ìjọsìn mọ́ torí wọn ò rí ìtọ́sọ́nà tàbí ìtùnú tí wọ́n fẹ́ níbẹ̀. Kí wá nìdí tó fi yẹ kó o lọ sí àwọn ìpàdé àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà? Kí lo máa rí níbẹ̀?

Wàá láyọ̀ pé o dara pọ̀ mọ́ àwọn èèyàn tó ní ìfẹ́ àti aájò. Ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní, àwọn Kristẹni ṣètò ara wọn sí àwọn ìjọ, wọ́n sì ń ṣe àwọn ìpàdé láti jọ́sìn Ọlọ́run, láti kẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Mímọ́ àti láti gbé ara wọn ró. (Hébérù 10:24, 25) Ìfẹ́ gbilẹ̀ gan-an láàárín wọn, wọ́n sì mọ̀ pé àwọn wà láàárín àwọn ọ̀rẹ́ tòótọ́, ìyẹn àwọn arákùnrin àti arábìnrin tí wọ́n jọ ń sin Ọlọ́run. (2 Tẹsalóníkà 1:3; 3 Jòhánù 14) Àpẹẹrẹ wọn là ń tẹ̀ lé, a sì ń láyọ̀ bíi tiwọn.

Wàá rí àǹfààní tó wà nínú kéèyàn mọ bá a ṣe lè fi àwọn ìlànà Bíbélì sílò. Àwọn ọkùnrin, obìnrin àtàwọn ọmọdé máa ń pàdé pọ̀ bíi ti ayé ìgbà tí wọ́n ń kọ Bíbélì. Àwọn olùkọ́ tó kúnjú ìwọ̀n máa ń ràn wá lọ́wọ́ láti mọ bí a ṣe lè máa fi ìlànà Bíbélì sílò ní ìgbésí ayé wa. (Diutarónómì 31:12; Nehemáyà 8:8) Gbogbo èèyàn ló lè dá sí ìjíròrò, a sì jọ máa ń kọrin, èyí ń jẹ́ ká lè sọ ìrètí tí àwa Kristẹni ní.​—Hébérù 10:23.

Ìgbàgbọ́ rẹ nínú Ọlọ́run á lágbára sí i. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ fún ọ̀kan lára àwọn ìjọ tó wà nígbà ayé rẹ̀ pé: ‘Àárò yín ń sọ mí, ká lè jọ fún ara wa ní ìṣírí nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ ẹnì kọ̀ọ̀kan wa, tiyín àti tèmi.’ (Róòmù 1:11, 12) Bá a ṣe ń pé jọ déédéé pẹ̀lú àwọn tá a jọ jẹ́ onígbàgbọ́ láwọn ìpàdé wa máa ń mú kí ìgbàgbọ́ wa lágbára, ó sì ń mú ká lè máa gbé ìgbé ayé Kristẹni.

O ò ṣe wá sí ìpàdé wa tó ń bọ̀ kí ìwọ fúnra rẹ lè rí àwọn nǹkan tá a sọ yìí? A máa fi ọ̀yàyà kí ẹ káàbọ̀. Ọ̀fẹ́ ni àwọn ìpàdé wa, a kì í gbé igbá owó.

  • Àpẹẹrẹ àwọn wo là ń tẹ̀ lé ní àwọn ìpàdé wa?

  • Àǹfààní wo la máa rí tá a bá ń lọ sí àwọn ìpàdé ìjọ?