Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

BÍBÉLÌ MÁA Ń YÍ ÌGBÉSÍ AYÉ ÀWỌN ÈÈYÀN PA DÀ

Mo Kekoo Pe Jehofa Je Alaaanu O si N Dari Jini

Mo Kekoo Pe Jehofa Je Alaaanu O si N Dari Jini
  • ỌDÚN TÍ WỌ́N BÍ MI 1954

  • ORÍLẸ̀-ÈDÈ MI KÁNÁDÀ

  • IRÚ ẸNI TÍ MO JẸ́ TẸ́LẸ̀ ONÍJÌBÌTÌ, ONÍTẸ́TẸ́

ÌGBÉSÍ AYÉ MI ÀTẸ̀YÌNWÁ:

Àgbègbè kan táwọn èèyàn ibẹ̀ ò fi bẹ́ẹ̀ rí já jẹ ni mo dàgbà sí nílùú Montreal. Mi ò tíì ju ọmọ oṣù mẹ́fà lọ nígbà tí bàbá mi ṣaláìsí, èyí sì mú kí gbogbo bùkátà ìdílé wa já lé màmá mi léjìká. Èmi ni àbígbẹ̀yìn nínú àwa mẹ́jọ tí àwọn òbí mi bí.

Bí mo ṣe ń dàgbà, ohun tí mò ń fi gbogbo ọjọ́ ayé mi ṣe kò ju pé kí n lo oògùn olóró, kí n ta tẹ́tẹ́, kí n hùwà ipá, kí n sì máa bá àwọn ọ̀daràn kẹ́gbẹ́. Nígbà tí mo pé ọmọ ọdún mẹ́wàá, mo bẹ̀rẹ̀ sí í bá àwọn aṣẹ́wó àtàwọn tó ń yáni lówó tí wọ́n sì ń gba èlé gọbọi jíṣẹ́ káàkiri. Ọ̀pọ̀ ìgbà ni mo máa ń parọ́, mo sì fẹ́ràn kí n máa lu àwọn èèyàn ní jìbìtì lónírúurú ọ̀nà tí mo bá lè gbà ṣe bẹ́ẹ̀. Ìwà yìí ti di bárakú fún mi.

Nígbà tí mo fi máa pé ọmọ ọdún mẹ́rìnlá, mo ti gbówọ́ nídìí ká tan àwọn èèyàn jẹ. Bí àpẹẹrẹ, màá ra ọ̀pọ̀ aago, ẹ̀gbà ọwọ́ àti òrùka tó ń dán bíi wúrà, màá fi àmì sára wọn pé wọ́n jẹ́ ojúlówó wúrà. Màá wá lọ tà wọ́n lójú ọ̀nà àti níbi ìgbọ́kọ̀sí láwọn ilé ìtajà. Bí mo ṣe máa dolówó láìlàágùn ló gbà mí lọ́kàn. Kódà nígbà kan, mo pa tó ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá [$10,000] owó dọ́là ti Kánádà lọ́jọ́ kan péré!

Lẹ́yìn tí wọ́n lé mi jáde nílé ìwé àwọn ọmọ aláìgbọràn lọ́mọ ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún [15], mi ò ní ibì kankan tí màá lọ gbé. Mo wá di ọmọ asùnta. Mò ń sùn láwọn ibi ìgbọ́kọ̀sí tàbí kí n lọ sùn nílé èyíkéyìí nínú àwọn ọ̀rẹ́ tí mo bá ṣáà ti pàdé.

Nítorí bí mo ṣe máa ń lu jìbìtì kiri, ọ̀pọ̀ ìgbà làwọn ọlọ́pàá máa ń yọ mí lẹ́nu. Nígbà tó sì jẹ́ pé kì í ṣe ọjà olè ni mò ń tà, wọn ò rán mi lẹ́wọ̀n rí. Àmọ́, ọ̀pọ̀ ìgbà ni mo máa ń san owó ìtanràn tó pọ̀ gan-an torí lílu jìbìtì, títa ayédèrú ọjà àti títa ọjà láìní ìwé àṣẹ. Kódà, mo tún ń bá àwọn tó ń gba owó èlé gọbọi lórí owó tí wọ́n ń yá àwọn èèyàn sin owó, torí pé mi ò kì í bẹ̀rù ẹnikẹ́ni. Iṣẹ́ yìí léwu gan-an ni, torí náà mo máa ń mú ìbọn dání nígbà míì. Lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, mo máa ń bá ẹgbẹ́ àwọn ọ̀daràn ṣiṣẹ́.

BÍ BÍBÉLÌ ṢE YÍ ÌGBÉSÍ AYÉ MI PA DÀ:

Ọmọ ọdún mẹ́tàdínlógún [17] ni mí nígbà tí mo kọ́kọ́ gbọ́ ọ̀rọ̀ Bíbélì sétí. Èmi àti ọ̀rẹ́bìnrin mi la jọ ń gbé nígbà táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Àmọ́, àwọn òfin inú Bíbélì tó dá lórí ìwà híhù kò tẹ́ mi lọ́rùn, torí náà, mo fi í sílẹ̀ mo wá lọ ń gbé lọ́dọ̀ obìnrin míì tí mò ń fẹ́.

Nǹkan yí pa dà nígbà táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tún bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ ọ̀rẹ́bìnrin mi kejì tá a jọ ń gbé lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ó yí ìgbésí ayé rẹ̀ pa dà, bó ṣe túbọ̀ ń ní sùúrù tó sì ń hùwà jẹ́ẹ́jẹ́ẹ́ wú mi lórí. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà pè mí sí ìpàdé tí wọ́n máa ń ṣe ní Gbọ̀ngàn Ìjọba wọn, mo sì lọ. Àwọn èèyàn tó jẹ́ ọmọlúàbí àti onínúure ló kí mi káàbọ̀. Wọ́n yàtọ̀ pátápátá sáwọn tí mo mọ̀ tẹ́lẹ̀. Àwọn tó wà nínú ìdílé mi ò rí tèmi rò rí; ní gbogbo ìgbà tí mo fi wà lọ́mọdé, wọn ò nífẹ̀ẹ́ mi, ọ̀rọ̀ mi ò sì jẹ wọ́n lógún. Bí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe fi ọ̀yàyà kó mi mọ́ra gan-an lohun tí mò ń fẹ́. Nígbà táwọn Ẹlẹ́rìí fi ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ̀ mí, tayọ̀tayọ̀ ni mo tẹ́wọ́ gbà á.

Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ ohun tí mo kọ́ nínú Bíbélì ni ò jẹ́ kí n ti pàdánù ẹ̀mí mi. Èmi àtàwọn ọ̀rẹ́ mi méjì kan ti jọ ń gbèrò bá a ṣe máa lọ jalè ká lè rówó san àwọn gbèsè tẹ́tẹ́ tó wà lọ́rùn wa, léyìí tó lé ní ẹgbẹ̀rún lọ́nà àádọ́ta owó dọ́là [$50,000]. Àmọ́ inú mi dùn pé mo yọwọ́ nínú ọ̀rọ̀ ọ̀hún. Àwọn ọ̀rẹ́ mi àtijọ́ yìí lọ ní tiwọn. Ọwọ́ tẹ ọ̀kan, wọ́n sì pa ìkejì.

Bi mo ṣe ń bá ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì mi lọ, mo rí i pé ọ̀pọ̀ ìyípadà ni mo ní láti ṣe. Bí àpẹẹrẹ, mo rí ohun tí Bíbélì sọ nínú 1 Kọ́ríńtì 6:10 pé: ‘Àwọn olè, àwọn oníwọra, àwọn ọ̀mùtípara, àwọn olùkẹ́gàn àti àwọn alọ́nilọ́wọ́gbà kì yóò jogún ìjọba Ọlọ́run.’ Ṣe ni mo bú sẹ́kún nígbà tí mo ka ẹsẹ yẹn torí àwọn ohun tí mo ti fayé mi ṣe burú jáì. Mo rí i pé mo ní láti ṣe àwọn ìyípadà nínú ìgbésí ayé mi látòkèdélẹ̀. (Róòmù 12:2) Tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀, oníwà ipá ni mí, mo sì tètè máa ń bínú, kódà ọjọ́ kan ò lè lọ kí n má parọ́.

Síwájú sí i, mo tún kọ́ ọ nínú Bíbélì pé Jèhófà jẹ́ aláàánú, ó sì máa ń dárí jini. (Aísáyà 1:18) Mo gbàdúrà kíkankíkan sí Jèhófà, mo bẹ̀ ẹ́ pé kó ràn mí lọ́wọ́ kí n lè jáwọ́ nínú àwọn ìwà tí mò ń hù tẹ́lẹ̀. Ó sì ràn mí lọ́wọ́, kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀ mo bẹ̀rẹ̀ sí í yí ìwà mi pa dà. Ara ìyípadà tó lágbára tí mo ṣe wáyé nígbà tí èmi àti ọ̀rẹ́bìnrin mi lọ forúkọ ìgbéyàwó wa sílẹ̀ lábẹ́ òfin.

Torí pé mò ń tẹ̀ lé àwọn ìlànà Bíbélì ló jẹ́ kí n wà láàyè títí dòní

Nígbà yẹn, ẹni ọdún mẹ́rìnlélógún [24] ni mí, mo ti gbéyàwó, a sì ti bí ọmọ mẹ́ta. Torí náà, mo ní láti wá iṣẹ́ gidi. Àmọ́ mi ò fi bẹ́ẹ̀ kàwé, kò sì sẹ́ni tó fẹ́ dámọ̀ràn mi fún iṣẹ́. Lẹ́ẹ̀kan sí i, mo fi ìtara gbàdúrà sí Jèhófà. Mo sì bẹ̀rẹ̀ sí í wáṣẹ́ kiri. Mo sọ fún àwọn tó ń gbani síṣẹ́ tí mo bá pàdé pé mo fẹ́ yí ìgbésí ayé mi pa dà, kí n sì máa fòótọ́ inú ṣiṣẹ́. Nígbà míì, mo máa ń sọ fún wọn pé mo ti ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ó sì wù mí kí n túbọ̀ wúlò fún àwọn ẹlòmíì. Púpọ̀ lára wọn kọ̀ láti gbà mí síṣẹ́. Níkẹyìn, lẹ́yìn tí mo sọ nípá àwọn nǹkan tójú mi ti rí fún ẹnì kan tó ń wá òṣìṣẹ́ nígbà tó fọ̀rọ̀ wá mi lẹ́nu wò, ó sọ pé: “Nǹkan kan ṣáà ń sọ fún mi pé ìwọ ni kí n fún níṣẹ́ yìí, bó tilẹ̀ jẹ́ pé mi ò mọ ìdí tó fi rí bẹ́ẹ̀.” Mo gbà pé bí Ọlọ́run ṣe fẹ́ dáhùn àdúrà mi nìyẹn. Nígbà tó yá, èmi àti ìyàwó mi ṣe ìrìbọmi, a sì di Ẹlẹ́rìí Jèhófà.

ÀǸFÀÀNÍ TÍ MO TI RÍ:

Torí pé mò ń tẹ̀ lé àwọn ìlànà Bíbélì tí mo sì ń gbé ìgbésí ayé Kristẹni ló jẹ́ kí n wà láàyè títí dòní. Ìdílé mi láyọ̀. Ó dá mi lójú pé Jèhófà ti dárí jì mí, èyí sì jẹ́ kí n ní ẹ̀rí ọkàn tó mọ́.

Láti ọdún mẹ́rìnlá báyìí ni mo ti ń lo àkókò tó pọ̀ láti kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Kódà lẹ́nu àìpẹ́ yìí, ìyàwó mi náà di ara àwa tá a máa ń fi ọ̀pọ̀ àkókò wàásù. Láti ọgbọ̀n [30] ọdún sẹ́yìn, mo ti ran méjìlélógún [22] lára àwọn tá a jọ ń ṣiṣẹ́ lọ́wọ́. Àwọn náà ti ń sin Jèhófà báyìí, èyí sì ń mú kí n máa láyọ̀. Mo ṣì máa ń lọ sáwọn ilé ìtajà, àmọ́ kì í ṣe torí àti lu àwọn èèyàn ní jìbìtì bí mo ṣe ń ṣe tẹ́lẹ̀. Ní báyìí, ńṣe ni mo máa ń wàásù nípa ohun tí mo gbà gbọ́ fún wọn. Ó máa ń wù mí láti fún wọn ní nǹkan, ìyẹn ni ìrètí láti gbé nínú ayé tuntun lọ́jọ́ iwájú, níbi tí kò ti ní sí oníjìbìtì kankan.—Sáàmù 37:10, 11.