Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

BÍBÉLÌ MÁA Ń YÍ ÌGBÉSÍ AYÉ ÀWỌN ÈÈYÀN PA DÀ

Awon Idahun Taara Ti Mo Ri Ninu Bibeli Wu Mi Lori Gan-an

Awon Idahun Taara Ti Mo Ri Ninu Bibeli Wu Mi Lori Gan-an
  • ỌDÚN TÍ WỌ́N BÍ MI: 1948

  • ORÍLẸ̀-ÈDÈ MI: HUNGARY

  • IRÚ ẸNI TÍ MO JẸ́ TẸ́LẸ̀: Ó WÙ MÍ LÁTI MỌ ÌDÁHÙN SÍ ÀWỌN ÌBÉÈRÈ PÀTÀKÌ NÍGBÈÉSÍ AYÉ

ÌGBÉSÍ AYÉ MI ÀTẸ̀YÌNWÁ:

Ìlú Székesfehérvár tó wà lórílẹ̀-èdè Hungary ni wọ́n bí mi sí. Ìlú yìí gbajúmọ̀ gan-an láyé àtijọ́, àmọ́ ó máa ń dùn mí tí mo bá rántí bí Ogun Àgbáyé Kejì ṣe bà á jẹ́.

Àwọn òbí mi àgbà ló tọ́ mi láti kékeré. Mo ṣì máa ń rántí wọn torí pé èèyàn àtàtà ni wọ́n, pàápàá ìyá mi àgbà tó ń jẹ́ Elisabeth. Màmá yìí ló fi mí mọ̀nà Ọlọ́run, èyí sì jẹ́ kí n ní ìgbàgbọ́ tó lágbára. Kódà, àtìgbà tí mo ti pé ọmọ ọdún mẹ́ta ni màmá àgbà ti kọ́ mi láti máa ka àdúrà táwọn èèyàn mọ̀ sí Àdúrà Olúwa ní ìrọ̀lẹ́-ìrọ̀lẹ́. Ṣùgbọ́n, pẹ̀lú bí mo ṣe ka àdúrà yẹn tó, mo fẹ́rẹ̀ẹ́ pé ọmọ ọgbọ̀n ọdún kí n tó lóye ohun tí àdúrà yẹn túmọ̀ sí.

Iṣẹ́ làwọn òbí mi gbájú mọ́, wọ́n ń wá owó tí wọ́n á fi ra ilé tá a lè máa gbé. Ìdí nìyẹn tó fi jẹ́ pé àti kékeré ni mo ti wà lọ́dọ̀ ìyà mi àti bàbá mi àgbà. Àmọ́ ní gbogbo ọjọ́ Sátidé kejì nínú oṣù, gbogbo wa máa ń pé jọ láti jẹun pọ̀. Mo máa ń gbádùn ìpéjọ wa yẹn gan-an.

Gbogbo ìlàkàkà àwọn òbí mi mérè wá. Lọ́dún 1958, wọ́n ra ilé kan fún àwa mẹ́tẹ̀ẹ̀ta láti gbé. Ńṣe ni inú mi ń dùn ṣìnkìn pé màá wà pẹ̀lú àwọn òbí mi. Àmọ́ kò ju oṣù mẹ́fà lọ tí ayọ̀ mi fi di ìbànújẹ́ torí pé àrùn jẹjẹrẹ pa bàbá mi.

Ọkàn mi gbọgbẹ́. Mo tiẹ̀ rántí pé mo sọ fún Ọlọ́run nígbà yẹn pé: “Ìwọ Ọlọ́run, mo sì bẹ̀ ọ́ pé kó o dá bàbá mi sí. Bàbá kan ṣoṣo tí mo ní. Kí ló dé tó ò dáhùn àdúrà mi?” Ó wù mí gan-an láti mọ ibi tí bàbá mi wà. Mo sì máa ń ronú pé: ‘Ṣé ó ti lọ sọ́run ni? Àbí ó ti lọ ráúráú nìyẹn?’ Ńṣe ni mo máa ń jowú àwọn ọmọ míì tí wọ́n ṣì ní bàbá.

Fún ọ̀pọ̀ ọdún, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ ojoojúmọ́ ni mò ń lọ sí ibi sàréè bàbá mi. Máa kúnlẹ̀ síwájú sàréè náà, màá wá gbàdúrà pé: “Ọlọ́run jọ̀ọ́, mo fẹ́ mọ ibi tí bàbá mi wà.” Mo tún máa ń gbàdúrà pé kí Ọlọ́run jẹ́ kí n mọ ohun táwa èèyàn wá ṣe láyé.

Nígbà tí mo pé ọmọ ọdún mẹ́tàlá [13], mo lọ kọ́ èdè Jámánì. Èrò ọkàn mi ni pé kí n tó ka ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ ìwé tó wà lédè Jámánì tán, màá rí ìdáhùn àwọn ìbéèrè mi. Nígbà tó di ọdún 1967, mo bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ ní ìlú Jena, tó wà ní Ìlà Oòrùn Jámánì. Mo máa ń ka àwọn ìwé táwọn onímọ̀ ọgbọ́n orí ilẹ̀ Jámánì ṣe, pàápàá èyí tó dá lórí ìgbésí ayé ẹ̀dá. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn kan sọ̀rọ̀ gidi, síbẹ̀ wọn ò dáhùn àwọn ìbéèrè mi. Mo ṣáà ń gbàdúrà pé kí Ọlọ́run jẹ́ kí n rí ìdáhùn.

BÍ BÍBÉLÌ ṢE YÍ ÌGBÉSÍ AYÉ MI PA DÀ:

Ìjọba Kọ́múníìsì ló ń ṣàkóso orílẹ̀-èdè Hungary nígbà tí mo pa dà síbẹ̀ lọ́dún 1970. Ìgbà yẹn ni mo pàdé Rose, tí mo pa dà fi ṣaya. Kò pẹ́ tá a ṣèyàwó ni a kó lọ sí orílẹ̀-èdè Austria. A pinnu pé ká ṣiṣẹ́ díẹ̀ ká tó kó lọ sí ìlú Sydney lórílẹ̀-èdè Australia, níbi tí mọ̀lẹ́bí mi kan ń gbé.

Kò pẹ́ tá a dé ìlú Austria ni mo rí iṣẹ́. Lọ́jọ́ kan, ẹni tá a jọ ń ṣiṣẹ́ sọ fún mi pé mo lè rí ìdáhùn àwọn ìbéèrè mi nínú Bíbélì. Ó wá fún mi ní àwọn ìwé díẹ̀ tó ṣàlàyé ẹ̀kọ́ Bíbélì. Kò pẹ́ rárá tí mo fi ka àwọn ìwé náà tán, ó sì wù mí láti mọ̀ sí i. Torí náà, mo kọ̀wé sí ọ́fíìsì àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó ń ṣe àwọn ìwé náà pé kí wọ́n fi àwọn ìwé míì ránṣẹ́ sí mi.

Lọ́jọ́ kan, àwọn ọ̀dọ́kùnrin méjì tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà wá sí ilé wa lọ́jọ́ tí èmi àti ìyàwó mi ń ṣe ayẹyẹ àyájọ́ ọjọ́ tí ìgbéyàwó wa pé ọdún kan. Wọ́n kó àwọn ìwé tí mo béèrè wá, wọ́n sì béèrè bóyá màá fẹ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, kíá ni mo gbà. Torí ìfẹ́ tí mo ní sí ẹ̀kọ́ yẹn, ẹ̀ẹ̀mejì lọ́sẹ̀ la máa ń kẹ́kọ̀ọ́, a sì máa ń lò tó wákàtí mẹ́rin nídìí ìkẹ́kọ̀ọ́ náà!

Ohun táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kọ́ mi nínu Bíbélì wọ̀ mí lákínyẹmí ara. Ẹnu yà mí nígbà tí wọ́n fi orúkọ Ọlọ́run, ìyẹn Jèhófà hàn mí nínú Bíbélì èdè Hungary tí mò ń gbé kiri. Fún ọdún mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n [27] tí mo fi lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì, mi ò gbọ́ kí wọ́n pe orúkọ Ọlọ́run rí. Àwọn ìdáhùn tó bọ́gbọ́n mu tí mo rí nínú Bíbélì sí àwọn ìbéèrè mi wú mi lórí gan-an. Bí àpẹẹrẹ, mọ́ kẹ́kọ̀ọ́ pé àwọn òkú ò mọ nǹkan kan, àfi bíi ìgbà tí wọ́n ń sún oorun àsùnwọra. (Oníwàásù 9:5, 10; Jòhánù 11:11-15) Mo tún kọ́ nípa ìlérí tí Ọlọ́run ṣe nínú Bíbélì pé ayé tuntun kan ń bọ̀ níbi táwọn èèyàn ò ti ní kú mọ́. (Ìṣípayá 21:3, 4) Mò sì ń fojú sọ́nà láti rí bàbá mi torí pé nínú ayé tuntun yẹn, “àjíǹde . . . yóò wà.”—Ìṣe 24:15.

Ó wu Rose látọkànwá láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, òun náà sì dara pọ̀ mọ́ mi. Àwa méjèèjì jára mọ́ ìkẹ́kọ̀ọ́ wa, a sì parí ẹ̀ láàárín oṣù méjì péré! A máa ń lọ sí gbogbo ìpàdé táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń ṣe ní Gbọ̀ngàn Ìjọba, ìyẹn ilé ìjọsìn wọn. Bí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe máa fìfẹ́ hàn síra wọn, tí wọ́n ń ran ara wọn lọ́wọ́ àti ìṣọ̀kan tó wà láàárín wọn wú èmi àti ìyàwó mi lórí gan-an.—Jòhánù 13:34, 35.

Ní ọdún 1976, a kó lọ sí orílẹ̀-èdè Australia. Bá a ṣe débẹ̀ la wá àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kàn. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà níbẹ̀ gbà wá tọwọ́tẹsẹ̀. Nígbà tó sì di ọdún 1978, àwa náà di Ẹlẹ́rìí Jèhófà.

ÀǸFÀÀNÍ TÍ MO TI RÍ:

Ní báyìí, mo ti rí ìdáhùn àwọn ìbéèrè tó ń jẹ mí lọ́kàn. Bákan náà, bí mo ṣe ń sún mọ́ Jèhófà, mo ti wá rí i pé òun ni Baba tó ju baba lọ. (Jákọ́bù 4:8) Inú mi sì máa ń dùn ti mo bá ń rántí pé láìpẹ́, màá rí bàbá mi nínú ayé tuntun.—Jòhánù 5:28, 29.

Nígbà tó di ọdún 1989, èmi àti Rose pa dà sí orílẹ̀-èdè Hungary ká lè sọ òtítọ́ Bíbélì tá a ti kọ́ fún àwọn ẹbí wa, àwọn ọ̀rẹ́ wa àtàwọn míì. Látìgbà yẹn wá, ọgọ́rọ̀ọ̀rún èèyàn ni a ti láǹfààní láti kọ́ ni ẹ̀kọ́ Bíbélì. Kódà, ohun tó ju àádọ́rin [70] nínú wọn ló ti ń sin Jèhófà báyìí títí kan ìyá mi ọ̀wọ́n.

Ọdún mẹ́tàdínlógún [17] ni mo fi gbàdúrà pé kí Ọlọ́run jẹ́ kí n rí ìdáhùn àwọn ìbéèrè mi. Ọdún mọ́kàndínlógójì [39] tí gorí ẹ̀ báyìí, síbẹ̀ mo ṣì ń gbàdúrà, àmọ́ ohun tí mò ń sọ lọ́tẹ̀ yìí ni pé: “Baba mi ọ̀run, o ṣeun o, tó dáhùn àdúrà ìgbà èwe mi.”