Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

KÓKÓ Ọ̀RỌ̀: ṢÉ ÌKÀ NI ỌLỌ́RUN?

Kí Nìdí Tí Àwọn Èèyàn Fi Ń Sọ Pé Ìkà Ni Ọlọ́run?

Kí Nìdí Tí Àwọn Èèyàn Fi Ń Sọ Pé Ìkà Ni Ọlọ́run?

ǸJẸ́ ìbéèrè tó wà lẹ́yìn ìwé ìròyìn yìí kò yà ọ́ lẹ́nu? Ó máa ya àwọn kan lẹ́nu torí wọ́n gbà pé Ọlọ́run kì í ṣe ọba ìkà. Àmọ́ lónìí, ọ̀pọ̀ èèyàn ló ń ṣe kàyéfì bóyá lóòótọ́ ni Ọlọ́run jẹ́ ìkà tàbí kì í ṣe bẹ́ẹ̀. Kí nìdí?

Àwọn kan tó yè bọ́ nínú àjálù, irú bí omíyalé, ìmìtìtì ilẹ̀ àtàwọn àjálù míì máa ń béèrè pé: “Kí ló dé tí Ọlọ́run fi ń jẹ́ kírú nǹkan báyìí ṣẹlẹ̀? Ṣé ọ̀rọ̀ wa ò kàn án ni? Àbí ìkà tiẹ̀ ni?”

Ohun tí àwọn míì kà nínú Bíbélì máa ń mú kí ọkàn wọn dà rú. Nígbà tí wọ́n ka àwọn ìtàn kan, irú bíi ti Ìkún-omi tó ṣẹlẹ̀ nígbà ayé Nóà, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe kàyéfì pé, ‘Báwo ni Ọlọ́run tó nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn ṣe máa pa adúrú èèyàn tó pọ̀ báyẹn dà nù? Àbí ìkà tiẹ̀ ni?’

Ṣé ìwọ náà ti rò ó rí pé ìkà ni Ọlọ́run? Àbí, táwọn èèyàn tó ń ṣe kàyéfì nípa bóyá ìkà ni Ọlọ́run bá bi ọ́ ní irú ìbéèrè yìí, o kì í mọ ohun tí wàá fi dá wọn lóhùn? Èyí ó wù kó jẹ́, jẹ́ ká kọ́kọ́ wo ìbéèrè pàtàkì kan tó máa jẹ́ ká rí ojútùú sí ọ̀rọ̀ yìí.

KÍ NÌDÍ TÍ A FI KÓRÌÍRA ÌWÀ ÌKÀ?

Ní ṣókí, ohun tó mú ká kórìíra ìwà ìkà ni pé a mọ ìyàtọ̀ láàárín ohun tó tọ́ àti èyí tí kò tọ́. A fi ìyẹn yàtọ̀ pátápátá sí àwọn ẹranko. Ìdí sì ni pé Ọlọ́run dá wa “ní àwòrán rẹ̀.” (Jẹ́nẹ́sísì 1:27) Kí lèyí túmọ̀ sí? Ó túmọ̀ sí pé Ọlọ́run dá wa lọ́nà tí a fi lè mọ bó ṣe yẹ ká máa hùwà, ká lè fìwà jọ ọ́, ó tún jẹ́ ká mọ irú ojú tí òun fi ń wo ohun tó tọ́ àti èyí tí kò tọ́. Rò ó wò ná: Tó bá jẹ́ pé Ọlọ́run ló fún wa lọ́gbọ́n tá a fi lè fìyàtọ̀ sáàárín ohun tó tọ́ àti èyí tí kò tọ́, èyí tó mú ká kórìíra ìwà ìkà, ǹjẹ́ ìyẹn kò fi hàn pé Ọlọ́run pàápàá kórìíra rẹ̀?

Bíbélì jẹ́rìí sí i pé bẹ́ẹ̀ gan-an lọ̀rọ̀ rí, Ọlọ́run fi dá wa lójú nínú Bíbélì pé: “Ọ̀nà mi ga ju ọ̀nà yín, bẹ́ẹ̀ sì ni ìrònú mi ga ju ìrònú yín.” (Aísáyà 55:9) Torí náà, tí a bá wá sọ pé ìkà ni Ọlọ́run, ṣé kì í ṣe pé à ń ta ko ohun tí Bíbélì sọ nìyẹn, bíi pé à ń dọ́gbọ́n sọ pé a mọ̀ ju Ọlọ́run lọ? Ohun tó bọ́gbọ́n mu jù lọ ni pé ká wádìí jinlẹ̀ sí i ká tó parí èrò lórí ọ̀rọ̀ yìí. Dípò ká máa béèrè bóyá ìkà ni Ọlọ́run, ohun tó yẹ ká béèrè ni pé, kí nìdí tí àwọn nǹkan míì tí Ọlọ́run ń ṣe fi jẹ́ kó dà bíi pé ìkà ni? Ká bàa lè lóye kókó yìí, ẹ jẹ́ ká wo ohun tí “ìwà ìkà” túmọ̀ sí.

Tí a bá sọ pé ìkà ni ẹnì kan, a gbà pé èrò inú ẹni náà kò dáa nìyẹn. Ìkà ni ẹni tí inú rẹ̀ máa ń dùn tó bá ń rí àwọn míì tó ń jìyà tàbí tí ìṣòro wọn kò tiẹ̀ ká a lára rárá. Bí àpẹẹrẹ, ìkà ni bàbá tí inú rẹ̀ máa ń dùn láti máa bá ọmọ rẹ̀ wí torí kó ṣáà lè fìyà jẹ ẹ́, kó sì bà á nínú jẹ́. Ṣùgbọ́n, bàbá rere lẹni tó bá ń bá ọmọ rẹ̀ wí torí kó lè kọ́ ọ lọ́gbọ́n tàbí kó lè dáàbò bò ó. Tí ẹnì kan bá ti ṣì ẹ́ lóye rí, wàá gbà pé ó rọrùn láti ṣi àwọn míì lóye, tí a kò bá mọ ìdí tí wọ́n fi ṣe ohun tí wọ́n ṣe.

Ẹ jẹ́ ká wá wo méjì nínú àwọn ìdí tí àwọn kan fi rò pé ìkà ni Ọlọ́run. Ọ̀kan ni àwọn àjálù tó ń ṣẹlẹ̀ lónìí, ìkejì sì ni àwọn ìdájọ́ Ọlọ́run tó wà nínú Bíbélì. Ṣé àwọn nǹkan yìí fi hàn pé ìkà ni Ọlọ́run lóòótọ́?