Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Orúkọ Ọlọ́run Di Mímọ̀ Ní Èdè Swahili

Orúkọ Ọlọ́run Di Mímọ̀ Ní Èdè Swahili

Tí ọ̀pọ̀ èèyàn bá gbọ́ ọ̀rọ̀ náà Swahili, ohun tó máa ń wá sọ́kàn wọn ni ilẹ̀ Áfíríkà àti àwọn ẹranko tó ń jẹ̀ kiri nínú ọ̀dàn ibì kan tó ń jẹ́ Serengeti. Àmọ́ ìyẹn nìkan kọ́ ni ibi tí ọ̀rọ̀ nípa èdè Swahili àti àwọn èèyàn tó ń sọ èdè náà mọ sí.

ÀWỌN èèyàn tí ó tó ọgọ́rùn-ún mílíọ̀nù ló ń sọ èdè Swahili ní orílẹ̀-èdè méjìlá ó kéré tán, láàárín gbùngbùn Áfíríkà sí ìlà oòrùn Áfíríkà. * Swahili ni èdè àjùmọ̀lò tí ìjọba fàṣẹ sí ní àwọn orílẹ̀-èdè bíi Kẹ́ńyà, Tanzania, Uganda àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Àwọn èèyàn orílẹ̀-èdè yòókù ní àgbègbè náà sì máa ń lò ó láti fi bá ara wọn sọ̀rọ̀, èyí tó mú kí òwò ṣíṣe àti ìjùmọ̀sọ̀rọ̀ rọrùn láàárín àwọn tó wá láti ibi ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀.

Èdè Swahili kó ipa pàtàkì nínú àjọṣepọ̀ tó wà láàárín àwọn èèyàn tó ń gbé ní Ìlà Oòrùn Áfíríkà. Bí àpẹẹrẹ, èdè ìbílẹ̀ tí wọ́n ń sọ ní orílẹ̀-èdè Tanzania nìkan ju mẹ́rìnléláàádọ́fà [114] lọ. Ronú nípa bó ṣe máa rí ná, ká sọ pé o kò ní rìn jìnnà ju nǹkan bí ogójì sí ọgọ́rin kìlómítà sí ilé rẹ tí wàá ti kan àwọn tó ń sọ èdè tó yàtọ̀ pátápátá sí tìrẹ! Nígbà míì sì rèé, gbogbo àwọn tí wọ́n jọ ń sọ èdè kan náà kì í ju àwọn tí wọ́n kàn jọ ń gbé ní àwọn abúlé kéékèèké mélòó kan lọ. Ǹjẹ́ kò ní ṣòro láti máa bá wọn sọ̀rọ̀? Èyí jẹ́ kí èèyàn rí ìdí tó fi dára bí wọ́n ṣe ní èdè àjùmọ̀lò.

Ìtàn Èdè Swahili

Àwọn èèyàn gbà pé, láti nǹkan bí ọgọ́rùn-ún ọdún kẹwàá ó kéré tán, ni wọ́n ti ń sọ èdè Swahili. Ọgọ́rùn-ún ọdún kẹrìndínlógún ni wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í kọ ọ́ sílẹ̀. Kì í pẹ́ tí àwọn tó ń kọ́ èdè Swahili fi máa ń rí i pé àwọn ọ̀rọ̀ kan nínú èdè náà jọ èdè Lárúbáwá. Kódà, tí wọ́n bá fi máa sọ̀rọ̀ márùn-ún lédè Swahili, ọ̀kan lára rẹ̀ máa jẹ́ ọ̀rọ̀ tó wá látinú èdè Lárúbáwá, nígbà tí ọ̀pọ̀ jù lọ lára ọ̀rọ̀ yòókù máa jẹ́ látinú èdè ilẹ̀ Áfíríkà. Torí náà, kò yani lẹ́nu pé ọ̀nà ìgbàkọ̀wé ti àwọn Lárúbáwá ni wọ́n fi ń kọ èdè Swahili fún ọ̀pọ̀ ọgọ́rùn-ún ọdún.

Àmọ́ lóde òní, ọ̀nà ìgbàkọ̀wé onílẹ́tà ábídí ti àwọn ará Róòmù ni wọ́n fi ń kọ èdè Swahili. Kí ló fà á? Kí nìdí tí wọ́n fi yí ọ̀nà ìgbàkọ̀wé wọn ti tẹ́lẹ̀ pa dà? Láti lè rí ìdáhùn, ẹ jẹ́ kí a ṣàyẹ̀wò ohun tó ṣẹlẹ̀ ní àárín ọgọ́rùn-ún ọdún kọkàndínlógún, nígbà tí àwọn míṣọ́nnárì láti ilẹ̀ Yúróòpù wá sí Ìlà Oòrùn Áfíríkà láti kọ́ àwọn ọmọ ìbílẹ̀ ibẹ̀ ní ẹ̀kọ́ Bíbélì.

Ìgbà Tí Bíbélì Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run Kọ́kọ́ Dé Ìlà Oòrùn Áfíríkà

Lọ́dún 1499, nígbà tí ọ̀gbẹ́ni Vasco da Gama ń rin ìrìn àjò rẹ̀ tí àwọn èèyàn mọ̀ dáadáa, dé àgbègbè gúúsù Áfíríkà, àwọn míṣọ́nnárì láti ilẹ̀ Potogí kọ́ ibùdó ẹ̀kọ́ ìsìn kan sí ìlú Zanzibar, wọ́n sì tipa bẹ́ẹ̀ mú ẹ̀sìn Kátólíìkì wọ Ìlà Oòrùn Áfíríkà. Àmọ́ láàárín igba ọdún lẹ́yìn náà, àwọn èèyàn ibẹ̀ tó ń ṣe àtakò lé àwọn ará Potogí náà kúrò ní àgbègbè yẹn, wọ́n sì fòpin sí ẹ̀sìn Kristẹni tí wọ́n dá sílẹ̀.

Ó tó àádọ́jọ [150] ọdún lẹ́yìn náà kí ẹnikẹ́ni tó tún wàásù nípa Bíbélì Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ní Ìlà Oòrùn Áfíríkà. Lọ́tẹ̀ yìí, míṣọ́nnárì kan láti ilẹ̀ Jámánì tó ń jẹ́ Johann Ludwig Krapf ló wá wàásù níbẹ̀. Nígbà tó dé ìlú Mombasa ní Kenya lọ́dún 1844, ẹ̀sìn Mùsùlùmí ló gbilẹ̀ ní etíkun Ìlà Oòrùn Áfíríkà, àmọ́ ọ̀pọ̀ àwọn tó wà ní àwọn ibi tó jìnnà sí etíkun jẹ́ ẹlẹ́sìn ìbílẹ̀. Krapf wá gbà pé ó ṣe pàtàkì kí gbogbo èèyàn ní Bíbélì.

Kíá, Krapf bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ èdè Swahili. Ní oṣù June ọdún 1844, láìpẹ́ sí ìgbà tó dé, ó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ bàǹtà-banta kan ìyẹn láti túmọ̀ Bíbélì. Ó bani nínú jẹ́ pé, ní oṣù tó tẹ̀ lé e àdánù ńlá bá a. Ìyàwó rẹ̀ tí kò tíì ju ọdún méjì tí wọ́n ṣe ìgbéyàwó kú, ọjọ́ mélòó kan lẹ́yìn ìyẹn, ọmọbìnrin wọn tó ṣì jẹ́ ìkókó náà tún kú. Lóòótọ́ ohun tí ó ṣẹlẹ̀ yìí kó ẹ̀dùn ọkàn bá a, síbẹ̀ ó ṣì ń bá iṣẹ́ ìtumọ̀ Bíbélì tí ó ń ṣe lọ. Nígbà tí ó fi máa di ọdún 1847, wọ́n tẹ orí mẹ́ta àkọ́kọ́ nínú ìwé Jẹ́nẹ́sísì jáde, òun ló sì wá jẹ́ ìwé tí wọ́n máa kọ́kọ́ tẹ̀ jáde ní èdè Swahili.

Krapf ló kọ́kọ́ lo ọ̀nà ìgbàkọ̀wé ti àwọn ará Róòmù láti kọ èdè Swahili, dípò kí ó lo ọ̀nà ìgbàkọ̀wé ti àwọn Lárúbáwá tí wọ́n fi ń kọ ọ́ tẹ́lẹ̀. Ara ìdí tó ní òun kò fi lo ọ̀nà ìgbàkọ̀wé ti àwọn Lárúbáwá ni pé “ọ̀nà ìkọ̀wé àwọn Lárúbáwá máa jẹ́ ìṣòro fún àwọn ará ilẹ̀ Yúróòpù” tó máa fẹ́ kọ́ èdè Swahili nígbà tó bá yá, àti pé “ọ̀nà ìgbàkọ̀wé àwọn ará Róòmù máa mú kí ó rọrùn fún ‘àwọn ọmọ ìbílẹ̀ Áfíríkà láti kọ́ èdè àwọn ará ilẹ̀ Yúróòpù.’” Síbẹ̀ fún ọ̀pọ̀ ọdún, àwọn kan ṣì ń fi ọ̀nà ìgbàkọ̀wé ti àwọn Lárúbáwá kọ èdè yìí, kódà wọ́n fi tẹ apá kan nínú Bíbélì jáde. Àmọ́ bí wọ́n ṣe ń lo ọ̀nà ìgbàkọ̀wé àwọn ará Róòmù, ó túbọ̀ rọrùn fún ọ̀pọ̀ láti kọ́ èdè Swahili. Ìdí nìyí tí inú àwọn míṣọ́nnárì àti àwọn tó ń kọ́ èdè Swahili fi dùn pé wọ́n ṣe ìyípadà yìí.

Yàtọ̀ sí pé Krapf ló kọ́kọ́ dáwọ́ lé títúmọ̀ Bíbélì Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sí èdè Swahili, ó tún fi ìpìlẹ̀ tó dáa lélẹ̀ fún àwọn tó ṣe iṣẹ́ ìtumọ̀ èdè lẹ́yìn tirẹ̀. Òun ni ó kọ́kọ́ ṣe ìwé ìlànà gírámà èdè Swahili àti ìwé atúmọ̀ èdè ní èdè náà.

Orúkọ Ọlọ́run ní Èdè Swahili

Ní orí mẹ́ta àkọ́kọ́ nínú ìwé Jẹ́nẹ́sísì tí wọ́n kọ́kọ́ tẹ̀ jáde, ṣe ni wọ́n kàn túmọ̀ orúkọ Ọlọ́run sí “Ọlọ́run Olódùmarè.” Nígbà tó wá di apá ìparí ọgọ́rùn-ún ọdún kọkàndínlógún, àwọn ọkùnrin kan wá sí Ìlà Oòrùn Áfíríkà, wọ́n wá ń bá iṣẹ́ títúmọ̀ Bíbélì lódindi sí èdè Swahili nìṣó. Lára wọn ni Johann Rebmann, William Taylor, Harry Binns, Edward Steere, Francis Hodgson, àti Arthur Madan.

Ara ohun tó gbàfiyèsí nínú àwọn kan lára ìtumọ̀ Bíbélì ayé ìgbà yẹn ni pé wọ́n lo orúkọ Ọlọ́run, kì í sì í ṣe ibi mélòó kan péré ni wọ́n ti lò ó, ṣe ni wọ́n lò ó jálẹ̀ Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù! Àwọn tí ó ń ṣe iṣẹ́ ìtumọ̀ ní ìlú Zanzibar pe orúkọ Ọlọ́run ní “Yahuwa,” nígbà tí àwọn tí wọ́n wà ní Mombasa pè é ní “Jehova.”

Nígbà tó fi máa di ọdún 1895, Bíbélì lódindi ti wà ní èdè Swahili. Àwọn ìtumọ̀ míì náà tún jáde lọ́pọ̀ ọdún lẹ́yìn náà, àmọ́ wọn kò fi bẹ́ẹ̀ wọ́pọ̀ lọ́wọ́ àwọn èèyàn. Láàárín nǹkan bí ọgọ́rùn-ún ọdún kan sẹ́yìn báyìí, wọ́n ṣe ọ̀pọ̀ akitiyan láti fi ẹnu kò sí ọ̀nà kan ṣoṣo tí wọ́n á máa gbà kọ èdè Swahili ní Ìlà Oòrùn Áfíríkà. Èyí ló mú kí wọ́n tẹ ìtumọ̀ Bíbélì tí wọ́n ń pè ní Swahili Union Version jáde ní ọdún 1952, òun sì ni ìtumọ̀ tí ó wọ́pọ̀ jù lọ́wọ́ àwọn èèyàn. Èyí ló sì fà á tó fi jẹ́ pé “Yehova” ni ọ̀pọ̀ èèyàn wá mọ̀ jù pé ó jẹ́ orúkọ Ọlọ́run ní èdè Swahili.

Àmọ́ ó ṣeni láàánú pé, bí wọn kò ṣe tẹ àwọn ìtumọ̀ Bíbélì ti ìgbà àtijọ́ yẹn jáde mọ́ náà ló di pé àwọn èèyàn kò fi bẹ́ẹ̀ rí Bíbélì tó lo orúkọ Ọlọ́run mọ́. Ṣe ni àwọn ìtumọ̀ Bíbélì kan tí wọ́n ṣe lẹ́nu àìpẹ́ yìí tiẹ̀ kúkú yọ ọ́ kúrò pátápátá, àwọn míì sì fi í sílẹ̀ ní àwọn ibi mélòó kan péré. Bí àpẹẹrẹ, nínú ìtumọ̀ Bíbélì ti Union Version, ìgbà mẹ́ẹ̀ẹ́dógún péré ni orúkọ Ọlọ́run fara hàn, nínú àtúnṣe rẹ̀ tí wọ́n wá tẹ̀ jáde ní ọdún 2006, ìgbà mọ́kànlá péré ni wọ́n lo orúkọ Ọlọ́run. *

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé nínú ìtumọ̀ Bíbélì Union Version yìí, wọ́n fẹ́rẹ̀ẹ́ yọ orúkọ Ọlọ́run kúrò tán ní àwọn ibi tí ó wà tẹ́lẹ̀, síbẹ̀ ohun kan wà níbẹ̀ tó gbàfiyèsí. Wọ́n kọ ọ́ gàdàgbà sí ọ̀kan nínú àwọn ojú ìwé ìbẹ̀rẹ̀ Bíbélì náà pé Jèhófà ni orúkọ Ọlọ́run. Èyí sì ti wúlò gan-an ní ti pé ó jẹ́ kí àwọn tí wọ́n fẹ́ mọ òtítọ́ lè rí orúkọ Baba wa ọ̀run nínú Bíbélì tiwọn.

Àmọ́ yàtọ̀ sí ìyẹn, ní ọdún 1996 a tẹ Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì ní Ìtumọ̀ Ayé Titun jáde ní èdè Swahili. Bíbélì yìí ni ìtumọ̀ tí ó kọ́kọ́ dá orúkọ Jèhófà pa dà sí àwọn ibi tó jẹ́ igba ó lé mẹ́tàdínlógójì [237] tí ó wà tẹ́lẹ̀ nínú Mátíù títí dé Ìṣípayá. Lẹ́yìn ìyẹn ní ọdún 2003, a tẹ Bíbélì Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun jáde lódindi ní èdè Swahili. Ní báyìí, àpapọ̀ ẹ̀dà Bíbélì yìí tí a ti tẹ̀ jáde lédè Swahili jẹ́ ọ̀kẹ́ márùnlélógójì [900,000].

Kì í tún ṣe pé wọ́n fi àwọn orúkọ oyè kan lásán dípò orúkọ Ọlọ́run nínú Bíbélì tàbí pé wọ́n kàn ṣáà mẹ́nu kàn án nínú ọ̀rọ̀ ìṣáájú rẹ̀ lásán mọ́. Ní báyìí, tí àwọn olùfẹ́ òtítọ́ bá ṣí Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun ní èdè Swahili, ṣe ni wọ́n túbọ̀ ń sún mọ́ Jèhófà ní gbogbo ìgbà tí wọ́n bá ń ka ọ̀kan nínú àwọn ibi tó lé ní ẹgbẹ̀rún méje [7,000] tí orúkọ rẹ̀ wà.

Ìtumọ̀ Bíbélì yìí tún lo èdè Swahili tó rọrùn, tó sì bóde mu, èyí tí gbogbo àwọn tó ń sọ èdè náà ní Ìlà Oòrùn Áfíríkà mọ̀ dáadáa. Ní àfikún sí i, àwọn àṣìṣe tó wọnú ọ̀pọ̀ ìtumọ̀ Bíbélì míì ni a ti mú kúrò nínú ìtumọ̀ Bíbélì yìí. Nítorí náà, ó máa dá ẹni tó bá ń kà á lójú pé “àwọn ọ̀rọ̀ títọ̀nà tí ó jẹ́ òtítọ́” tí ó sì ní ìmísí Ẹlẹ́dàá wa, Jèhófà Ọlọ́run, ni òun ń kà.—Oníwàásù 12:10.

Ọ̀pọ̀ èèyàn ló ti sọ̀rọ̀ ìmọrírì nípa Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun lédè Swahili yìí. Arákùnrin Vicent, ọmọ ọdún mọ́kànlélógún tó ń fi àkókò tó pọ̀ ṣe iṣẹ́ Ọlọ́run, sọ pé: “Inú mi dùn púpọ̀ nítorí èdè Swahili tó rọrùn tí wọ́n lò nínú Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun àti pé ó tún dá orúkọ Jèhófà pa dà sí ibi tí àwọn ìtumọ̀ Bíbélì mìíràn ti yọ ọ́ kúrò.” Obìnrin kan tó ń jẹ́ Frieda, tí ó ní ọmọ mẹ́ta sọ pé ìtumọ̀ Bíbélì yìí ti mú kí ó rọrùn fún òun láti máa ṣàlàyé ẹ̀kọ́ òtítọ́ inú Bíbélì fún àwọn èèyàn.

Ó ti ju àádọ́jọ [150] ọdún sẹ́yìn báyìí tí wọ́n ti ń túmọ̀ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sí èdè Swahili. Jésù sọ pé òun ‘ti fi orúkọ Baba òun hàn kedere.’ (Jòhánù 17:6) Ní báyìí, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó ju ẹgbẹ̀rún mẹ́rìndínlọ́gọ́rin [76,000] ní àárín gbùngbùn àti ìlà oòrùn Áfíríkà, tí wọ́n ń sọ èdè Swahili, ń láyọ̀ bí wọ́n ṣe ń lo Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun ní èdè Swahili torí pé wọ́n ń kópa nínú mímú kí gbogbo èèyàn mọ orúkọ Jèhófà.

^ Oríṣiríṣi ẹ̀ka èdè Swahili ni àwọn èèyàn ń sọ ní àwọn orílẹ̀-èdè yìí.