Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

“Tí Kingsley Bá Lè Ṣe É, Èmi Náà Lè Ṣe É!”

“Tí Kingsley Bá Lè Ṣe É, Èmi Náà Lè Ṣe É!”

ẸNÌ KAN fọwọ́ kan Kingsley léjìká, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í ka Bíbélì, ìyẹn ni iṣẹ́ àkọ́kọ́ tí Kingsley máa ṣe ní Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run nínú ìjọ. Ó fara balẹ̀ pe ọ̀rọ̀ kọ̀ọ̀kan bó ṣe tọ́, kò sì pa ọ̀rọ̀ kankan jẹ. Àmọ́ ẹ dúró ná o, kò mà wo ìwé bó ṣe ń ka Bíbélì náà lọ! Kí ló dé?

Afọ́jú ni Kingsley, orílẹ̀-èdè Siri Láńkà ló sì ń gbé. Kì í gbọ́rọ̀ dáadáa, kẹ̀kẹ́ arọ ló sì máa ń wà tó bá fẹ́ lọ káàkiri. Báwo wá ni ọkùnrin yìí ṣe kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà, tó sì tóótun láti ṣiṣẹ́ ní Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run? Ẹ jẹ́ kí n ṣàlàyé.

Nígbà tí mo kọ́kọ́ pàdé Kingsley, ó wú mi lórí gan-an pé ó fẹ́ láti lóye Bíbélì. Ọ̀pọ̀ Ẹlẹ́rìí ló ti kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ìwé Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun ni wọ́n fi kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́. Ìwé yìí jẹ́ ti ẹ̀dà àwọn afọ́jú, ó sì ti gbó gan-an. * Kingsley gbà kí n tún pa dà bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú òun, àmọ́, a ní ìṣòro méjì.

Ìṣòro àkọ́kọ́ ni pé ilé ìtọ́jú àwọn arúgbó àti àwọn aláàbọ̀ ara ni Kingsley ń gbé. Torí pé Kingsley ò gbọ́rọ̀ dáadáa àti ariwo táwọn èèyàn tó wà nílé náà ń pa, mo máa ń gbóhùn sókè gan-an tá a bá ń ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́. Kódà, gbogbo ará ilé yẹn ló máa ń gbọ́ wa tá a bá ń ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀!

Ìṣòro kejì ni pé, ohun tí Kingsley lè kà ò tó nǹkan, ìwọ̀nba díẹ̀ sì ni ohun tó ń lóye nígbàkigbà tá a bá ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́. Torí náà, kí ìkẹ́kọ̀ọ́ wa lè túbọ̀ nítumọ̀, Kingsley máa ń múra sílẹ̀ dáadáa. Ó máa ń ka ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tá à ń lò lákàtúnkà ṣáájú ìkẹ́kọ̀ọ́ wa, á yẹ àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tí a tọ́ka sí nínú Bíbélì rẹ̀ tó jẹ́ tí ẹ̀dà àwọn afọ́jú wò, á sì fọkàn ronú ohun tí ìdáhùn sáwọn ìbéèrè inú ìkẹ́kọ̀ọ́ náà máa jẹ́. Ọ̀nà tá a gbà ń ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ wa yìí gbéṣẹ́ gan-an. Nígbà tá a bá ń ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́, Kingsley máa ń jókòó sórí rọ́ọ̀gì, á sì kó ẹsẹ̀ rẹ̀ léra wọn. Á máa fìdùnnú ṣàlàyé ohun tó ti kọ́, á wá gbóhùn sókè á sì máa fọwọ́ gbálẹ̀ bó ṣe ń sọ̀rọ̀. Ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, a bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ lẹ́ẹ̀mejì lọ́sẹ̀, wákàtí méjì la sì máa ń lò nígbà ìkẹ́kọ̀ọ́ kọ̀ọ̀kan!

Ó BẸ̀RẸ̀ SÍ Í WÁ SÍPÀDÉ, Ó SÌ Ń KÓPA

Kingsley àti Paul

Kingsley ń hára gàgà láti lọ sí ìpàdé ní Gbọ̀ngàn Ìjọba, àmọ́ kì í ṣe ohun tó rọrùn fún un. Ó nílò ìrànlọ́wọ́ ẹni tó máa gbé e látorí kẹ̀kẹ́ rẹ̀ sínú ọkọ̀, kí wọ́n gbé e pa dà sórí kẹ̀kẹ́, kí wọ́n sì tún bá a ti kẹ̀kẹ́ rẹ̀ wọ inú Gbọ̀ngàn Ìjọba. Ọ̀pọ̀ àwọn ará máa ń ràn án lọ́wọ́ nígbà tó bá yí kàn wọ́n, wọ́n sì kà á sí àǹfààní láti ṣe bẹ́ẹ̀. Tí ìpàdé bá ń lọ lọ́wọ́, Kíngsley máa ń gbé ẹ̀rọ gbohùngbohùn kan sún mọ́ etí rẹ̀, ó máa ń fetí sílẹ̀ dáadáa, kódà ó máa ń dáhùn ìbéèrè!

Lẹ́yìn tí Kingsley kẹ́kọ̀ọ́ fún ìgbà díẹ̀, ó pinnu láti fi orúkọ sílẹ̀ ní Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run. Ọ̀sẹ̀ méjì ṣáájú ìgbà àkọ́kọ́ tó máa ka Bíbélì, mo bi í bóyá ó ń múra iṣẹ́ rẹ̀ sílẹ̀, gbogbo ẹnu ló fi dáhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni Bọ̀ọ̀dá, mo ti múra ẹ̀, ó kéré tán mo ti kà á nígbà ọgbọ̀n.” Mo gbóríyìn fún un torí iṣẹ́ tó ṣe, mo wá ní kó kà á fún mi. Ó ṣí Bíbélì rẹ̀, ó gbé àwọn ìka rẹ̀ lé e lórí, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í fi kà á lọ. Àmọ́, mo kíyè sí i pé àwọn ìka rẹ̀ kò kúrò lójú kan lórí ìwé náà bó ṣe sábà máa ń ṣe. Ó ti há gbogbo Bíbélì tó fẹ́ kà náà sórí!

Ohun tí Kingsley ṣe yìí yà mí lẹ́nu gan-an, àní ńṣe lomijé ń bọ́ lójú mi. Mo bí Kingsley pé báwo ló ṣe há gbogbo ọ̀rọ̀ náà sórí nígbà tó jẹ́ pé ìgbà ọgbọ̀n péré ló kà á. Èsì tó fún mi ni pé: “Rárá o, mo máa ń múra ẹ̀ sílẹ̀, ó kéré tán, ní ìgbà ọgbọ̀n lójúmọ́.” Ó lé lóṣù kan tí Kingsley fi ń jókòó sórí rọ́ọ̀gì rẹ̀, tó sì ń ka àwọn ẹsẹ Bíbélì náà lákàtúnkà títí tó fi mọ gbogbo rẹ̀ lórí.

Nígbà tó ṣe, àkókò tó fún Kingsley láti ṣiṣẹ́ rẹ̀ ní Gbọ̀ngàn Ìjọba. Nígbà tó parí iṣẹ́ náà, àwọn ará pàtẹ́wọ́ tó rinlẹ̀ gan-an, ọ̀pọ̀ lomijé ayọ̀ ń bọ́ lójú wọn nígbà tí wọ́n rí ìsapá ọmọ ilé ẹ̀kọ́ tuntun yìí. Akéde kan tí kò ṣiṣẹ́ nílé ẹ̀kọ́ mọ́ torí ẹ̀rù tó máa ń bà á sọ pé kí wọ́n pa dà máa fún òun níṣẹ́. Kí nìdí? Ó sọ pé, “Tí Kingsley bá lè ṣe é, èmi náà lè ṣe é!”

Ní ọjọ́ kẹfà oṣù September, ọdún 2008, lẹ́yìn ọdún mẹ́ta tí Kingsley ti ń kẹ́kọ̀ọ́, ó ṣe ìrìbọmi láti fi ẹ̀rí hàn pé òun ti ya ara òun sí mímọ́ fún Jèhófà. Kingsley kú ní May 13, ọdún 2014, ó jẹ́ adúróṣinṣin títí tó fi kú. Ó dá a lójú pé òun á máa bá iṣẹ́ ìsìn òun sí Jèhófà nìṣó pẹ̀lú gbogbo okun àti ìlera pípé nínú Párádísè. (Aísá. 35:5, 6)—Gẹ́gẹ́ bí Paul McManus ṣe sọ ọ́.

^ ìpínrọ̀ 4 A tẹ̀ ẹ́ ní ọdún 1995; àmọ́ a ò tẹ̀ ẹ́ mọ́ báyìí.