Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ | NÍGBÀ TÍ ẸNI TÓ O NÍFẸ̀Ẹ́ BÁ KÚ

Bá A Ṣe Lè Tu Àwọn Tó Ń Ṣọ̀fọ̀ Nínú

Bá A Ṣe Lè Tu Àwọn Tó Ń Ṣọ̀fọ̀ Nínú

Ṣé ó ti ṣe ẹ́ rí pé o kò mọ ohun tó o máa ṣe nígbà tí ọ̀fọ̀ ṣẹ ẹnì kan tó sún mọ́ ẹ? Nígbà míì o lè má mọ ohun tó o máa sọ, kó o wá kúkú dákẹ́ láìṣe ohunkóhun. Àmọ́, àwọn nǹkan kan wà tó o lè ṣe fún ẹni tí ọ̀fọ̀ ṣẹ̀ náà.

Lọ́pọ̀ ìgbà, ohun tí àwọn tó ń ṣọ̀fọ̀ nílò kò ju pé kó o wà lọ́dọ̀ wọn, kó o sì kí wọn pé “Ẹ pẹ̀lẹ́ o, ẹ kú ọ̀rọ̀ èèyàn.” Láwọn ilẹ̀ kan, gbígbá ẹni náà mọ́ra tàbí kéèyàn rọra fọwọ́ kàn án máa fi hàn pé ò ń bá a kẹ́dùn. Tí ẹni tí ọ̀fọ̀ ṣẹ̀ náà bá fẹ́ sọ̀rọ̀, fara balẹ̀ tẹ́tí sí i. Ohun tó wá dáa jù ni pé kó o bá wọn ṣe àwọn iṣẹ́ ilé kan, bóyá àwọn tí wọn ò lè ṣe fúnra wọn lásìkò yẹn. Irú bíi síse oúnjẹ, títọ́jú àwọn ọmọ tàbí kó o bá wọn ṣètò ìsìnkú tí wọ́n bá fẹ́ bẹ́ẹ̀. Irú àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀ máa ṣe wọ́n láǹfààní ju kéèyàn kàn máa sọ̀rọ̀ ṣáá.

Bí àkókò ti ń lọ, o lè sọ̀rọ̀ nípa ẹni tó kú náà, irú bí ìwà rere tẹ́ni náà ní àti àkókò alárinrin tẹ́ ẹ jọ gbádùn. Irú àwọn ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀ tiẹ̀ lè mú kí ẹni tí ọ̀fọ̀ ṣẹ̀ náà tújú ká. Bí àpẹẹrẹ, Pam tí ọkọ rẹ̀ tó ń jẹ́ Ian kú lọ́dún mẹ́fà sẹ́yìn sọ pé: “Àwọn èèyàn sábà máa ń sọ ohun rere tí lan ṣe tí mi ò tiẹ̀ mọ̀ nípa rẹ̀ rárá, èyí sì máa ń múnú mi dùn.”

Àwọn olùṣèwádìí ròyìn pé àwọn èèyàn máa ń rọ́ lọ kí ẹni tí ọ̀fọ̀ ṣẹ gbàrà tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà bá wáyé. Àmọ́ kì í pẹ́ táwọn èèyàn á fi pa ẹni tó ń ṣọ̀fọ̀ tì. Torí náà, sapá láti máa kàn sí ẹni tó ń ṣọ̀fọ̀ náà lóòrèkóòrè lẹ́yìn ìṣẹ̀lẹ̀ náà. * Ọ̀pọ̀ àwọn tó ń ṣọ̀fọ̀ máa ń mọ rírì rẹ̀ táwọn èèyàn bá kàn sí wọn kí ẹdùn ọkàn wọn lè fúyẹ́.

Wo àpẹẹrẹ ọ̀dọ́bìnrin kan tó ń jẹ́ Kaori lórílẹ̀-èdè Japan. Ìbànújẹ́ dorí rẹ̀ kodò nígbà tí ìyá rẹ̀ kú, tí ẹ̀gbọ́n rẹ̀ náà sì tún kú ní nǹkan bí ọdún kan àti oṣù mẹ́ta lẹ́yìn náà. Àmọ́, ó rí ìtìlẹyìn látọ̀dọ̀ àwọn ọ̀rẹ́ tó dúró tì í. Ritsuko jẹ́ ọ̀kan lára wọn. Ritsuko dàgbà ju Kaori lọ dáadáa. Ó sọ fún Kaori pé kó jẹ́ káwọn jọ máa ṣọ̀rẹ́. Kaori sọ pé: “Kí n má parọ́, inú mi ò dùn sí i. Mi ò fẹ́ kí ẹnikẹ́ni gba ipò ìyá mi, mi ò tiẹ̀ rò pé ẹnikẹ́ni lè ṣe bí ìyá fún mi. Àmọ́, torí bí màmá yìí ṣe ń ṣe sí mi, mo wá bẹ̀rẹ̀ sí í sún mọ́ ọn. Ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀ la jọ máa ń lọ wàásù, tá a sì jọ máa ń lọ sí ìpàdé Kristẹni. Ó máa ń pè mí pé kí n wá mu tíì lọ́dọ̀ òun, ó máa ń gbé oúnjẹ wá fún mi, ó sì máa ń fi lẹ́tà àti káàdì ránṣẹ́ sí mi. Ìwà rere tí màmá yìí ń hù ní ipa rere lórí mi.”

Ó ti lé lọ́dún méjìlá báyìí tí ìyá Kaori ti kú. Lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí, òun àti ọkọ rẹ̀ jẹ́ òjíṣẹ́ tó ń fi ọ̀pọ̀ àkókò wàásù. Kaori sọ pé: “Màmá yìí kò fọ̀rọ̀ mi ṣeré rárá. Tí mo bá lọ sílé, mó máa ń lọ kí i, mo sì máa ń gbádùn àwọn ọ̀rọ̀ tó ń fúnni ní ìṣírí tó máa ń sọ.”

Ẹlòmíì tó jàǹfààní látọ̀dọ̀ àwọn ọ̀rẹ́ adúrótini ni Poli, tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lórílẹ̀-èdè Cyprus. Èèyàn dáadáa ni ọkọ Poli, tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Sozos. Ọwọ́ pàtàkì ló fi mú ojúṣe rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí alábòójútó nínú ìjọ. Ó sábà máa ń pe àwọn ọmọ aláìlóbìí àtàwọn opó láti wá bá wọn ṣeré kí wọ́n sì jọ jẹun. (Jákọ́bù 1:27) Àmọ́, kókó kan tó yọ nínú ọpọlọ rẹ̀ ṣekú pa á lẹ́ni ọdún mẹ́tàléláàádọ́ta [53]. Poli sọ pé: “Mo pàdánù ọkọ mi tá a ti jọ gbé pa pọ̀ fún ọdún mẹ́tàlélọ́gbọ̀n [33].”

Wá ọ̀nà tó o lè gbà ran àwọn tó ń ṣọ̀fọ̀ lọ́wọ́

Lẹ́yìn ìsìnkú, Poli àti Daniel ọmọkùnrin rẹ̀ tó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún [15] kó lọ sí orílẹ̀-èdè Kánádà. Wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í dara pọ̀ mọ́ ọ̀kan lára ìjọ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà níbẹ̀. Poli sọ pé: “Àwọn ọ̀rẹ́ wa ní ìjọ tá a ṣẹ̀ṣẹ̀ dé yìí kò mọ ohun tó ṣẹlẹ̀ sí wa tàbí ipò tá a wà. Síbẹ̀ wọ́n máa ń sún mọ́ wa, wọ́n máa ń sọ̀rọ̀ tútù fún wa, wọ́n sì máa ń ràn wá lọ́wọ́. Ìrànlọ́wọ́ ńlá gbáà ni èyí jẹ́ fún ọmọ mi lákòókò tó nílò bàbá rẹ̀ gan-an yìí. Àwọn tó ń mú ipò iwájú nínú ìjọ kò fọ̀rọ̀ Daniel ṣeré rárá. Ọ̀kan tiẹ̀ wà lára wọn tó máa ń mú Daniel jáde tó bá fẹ́ lọ sọ́dọ̀ àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ tàbí nígbà tó bá fẹ́ lọ gbá bọ́ọ̀lù.” Nǹkan ti ń lọ dáadáa fún Poli àti ọmọ rẹ̀ báyìí.

Kò sí àní-àní pé ọ̀pọ̀ ọ̀nà la lè gbà ran àwọn tó ń ṣọ̀fọ̀ lọ́wọ́ ká sì tù wọ́n nínú. Àwọn ohun tí Ọlọ́run ṣèlérí nípa ọjọ́ ọ̀la tó wà nínú Bíbélì pẹ̀lú máa ń tuni nínú.

^ ìpínrọ̀ 6 Àwọn kan tiẹ̀ máa ń kọ déètì ọjọ́ tí ẹni náà kú sórí kàlẹ́ńdà wọn, kí wọ́n lè rántí láti tu ẹni tó ń ṣọ̀fọ̀ náà nínú nígbà tó nílò ìtùnú. Bóyá ní àyájọ́ ọjọ́ tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà wáyé tàbí lọ́jọ́ míì tó sún mọ́ ọn.