Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ohun Tó Yẹ Kó O Mọ̀ Nípa Àìsàn Ibà

Ohun Tó Yẹ Kó O Mọ̀ Nípa Àìsàn Ibà

Àjọ Ìlera Àgbáyé fojú bù ú pé lọ́dún 2013, ohun tó lé ní 198,000,000 èèyàn ni àìsàn ibà ṣe. Nínú wọn, nǹkan bíi 584,000 ni àìsàn náà pa. Èyí tó ju 465,000 nínú wọn ló sì jẹ́ ọmọdé tí kò tíì pé ọmọ ọdún márùn-ún. Àìsàn ibà wọ́pọ̀ gan-an ní àwọn orílẹ̀-èdè tí ó tó ọgọ́rùn-ún [100] kárí ayé, èyí fi hàn pé nǹkan bíi 3,200,000,000 èèyàn ló wà nínú ewu àìsàn ibà.

1 KÍ NI ÀÌSÀN IBÀ?

Kòkòrò àrùn kan ló ń fa ibà. Ibà sì máa ń fa àwọn àárẹ̀ bí ara gbígbóná, òtútù, kéèyàn máa làágùn, ẹ̀fọ́rí, ara ríro, kí èébì máa gbé èèyàn tàbí kéèyàn tiẹ̀ máa bì pàápàá. Àwọn àárẹ̀ yìí sábà máa ń fara hàn láàárín ọjọ́ méjìméjì sí mẹ́tamẹ́ta. Ohun tó máa ń pinnu èyí ni irú kòkòrò àrùn ibà tó wọnú ara àti ìgbà téèyàn ní àìsàn náà kẹ́yìn.

2 BÁWO NI IBÀ ṢE Ǹ WỌNÚ ARA ÈÈYÀN?

  1. Tí abo ẹ̀fọn kan tí wọ́n ń pè ní Anopheles bá jẹ èèyàn, ńṣe ló máa ń pọ àwọn kòkòrò àrùn kan tí wọ́n ń pè ní Plasmodia sínú ara ẹni náà.

  2. Àwọn kòkòrò àrùn yìí máa wá lọ kó sínú àwọn sẹ́ẹ̀lì inú ẹ̀dọ̀, wọ́n á sì máa pọ̀ sí i níbẹ̀.

  3. Tí àwọn sẹ́ẹ̀lì inú ẹ̀dọ̀ táwọn kòkòrò àrùn yìí kó sí bá bẹ́, ńṣe ni wọ́n á tú àwọn kòkòrò àrùn náà jáde. Àwọn kòkòrò àrùn yìí á wá lọ kó sínú àwọn sẹ́ẹ̀lì ẹ̀jẹ̀ pupa, wọ́n á sì tún máa pọ̀ sí i níbẹ̀.

  4. Tí àwọn sẹ́ẹ̀lì ẹ̀jẹ̀ pupa táwọn kòkòrò àrùn yìí kó sí bá bẹ́, ńṣe làwọn náà máa tú àwọn kòkòrò àrùn náà jáde. Àwọn kòkòrò àrùn yìí á wá lọ máa kó sínú àwọn sẹ́ẹ̀lì ẹ̀jẹ̀ pupa míì, wọ́n á sì máa pọ̀ sí i.

  5. Bí àwọn kòkòrò àrùn yìí á ṣe máa kó sínú àwọn sẹ́ẹ̀lì ẹ̀jẹ̀ pupa lọ nìyẹn. Gbogbo ìgbà tí àwọn sẹ́ẹ̀lì ẹ̀jẹ̀ pupa bá bẹ́ ni ẹni náà á máa nímọ̀lára àárẹ̀ tí ibà ń fà.

3 BÁWO LO ṢE LÈ DÁÀBÒ BO ARA RẸ?

Tó o bá ń gbé níbi tí ẹ̀fọn pọ̀ sí . . .

  • Lo nẹ́ẹ̀tì apẹ̀fọn. Àmọ́ rí i dájú pé

    • nẹ́ẹ̀tì náà ní oògùn ẹ̀fọn lára.

    • kò fàya, kò sì ní ihò tí ẹ̀fọn lè gbà wọlé.

    • o ki nẹ́ẹ̀tì náà bọ abẹ́ bẹ́ẹ̀dì dáadáa, kò máa baà ní àlàfo èyíkéyìí.

  • Máa lo oògùn ẹ̀fọn déédéé.

  • Tó bá ṣeé ṣe, fi nẹ́ẹ̀tì sí ojú wíńdò àti ẹnu ọ̀nà. Kó o sì tan ẹ̀rọ amúlétutù tàbí fáànù, torí kò ní jẹ́ káwọn ẹ̀fọn máa fò káàkiri.

  • O lè wọ aṣọ fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ àmọ́ tó bo gbogbo ara.

  • Yẹra fún àwọn ibi tí ẹ̀fọn máa ń pọ̀ sí, irú bí ibi tí omi dárogún sí.

  • Tí ẹ̀fọn bá jẹ ẹ́, tètè lọ tọ́jú ara rẹ.

Tó o bá fẹ́ lọ sí ìlú tí ẹ̀fọn pọ̀ sí . . .

  • Kọ́kọ́ wádìí nípa bí àdúgbò náà ṣe rí kó o tó lọ. Torí pé irú kòkòrò àrùn ibà tó wọ́pọ̀ ní àdúgbò kan lè yàtọ̀ síbòmíì, èyí ló sì máa pinnu irú oògùn ibà tó o máa lò níbẹ̀. Bákan náà, ó máa dáa kó o bá dókítà rẹ sọ̀rọ̀ kó lè ṣàlàyé ohun tó yẹ kó o fi sọ́kàn nítorí ìlera rẹ.

  • Tó o bá dé àdúgbò náà, rí i dájú pé o tẹ̀ lé àwọn àbá tó wà nínú àpilẹ̀kọ yìí, èyí tá a dìídì ṣe fún àwọn tó ń gbé ní àdúgbò tí ẹ̀fọn pọ̀ sí.

  • Tí ẹ̀fọn bá jẹ ẹ́, tètè tọ́jú ara rẹ. Torí pé, ó lè tó ọ̀sẹ̀ kan sí ọ̀sẹ̀ mẹ́rin lẹ́yìn tí ẹ̀fọn jẹ ẹ́ kó o tó mọ̀ pé o ti ní àìsàn ibà.