Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ

Ǹjẹ́ O Lè Pinnu Bí Ìgbésí Ayé Rẹ Ṣe Máa Rí?

Ǹjẹ́ O Lè Pinnu Bí Ìgbésí Ayé Rẹ Ṣe Máa Rí?

NÍGBÀ tó o wà ní kékeré, kí làwọn ohun tó wù ẹ́ kó o gbéṣe láyé? Ó ṣeé ṣe kó wù ẹ́ láti ṣègbéyàwó, kó o nílé tara ẹ, kó o sì níṣẹ́ gidi lọ́wọ́. Àmọ́ nígbà míì, nǹkan kì í rí bá a ṣe rò. Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ àìròtẹ́lẹ̀ lè mú kí nǹkan yí pa dà bìrí.

  • Ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Anja, Delina àti Gregory nìyẹn. Àtìgbà tí Anja tó ń gbé lórílẹ̀-èdè Jámánì ti wà ní ọmọ ọdún mọ́kànlélógún [21] ló ti ní àrùn jẹjẹrẹ. Ní báyìí, ẹ̀ẹ̀kan lọ́gbọ̀n ló máa ń jáde nílé.

  • Delina, tó ń gbé lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà ní àrùn kan tí wọ́n ń pè ní dystonia, ìyẹn àrùn inú ọpọlọ tí kì í jẹ́ kí iṣan ara ṣiṣẹ́ dáadáa. Yàtọ̀ síyẹn, ó tún ń tọ́jú àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀ mẹ́ta tí wọ́n jẹ́ aláàbọ̀ ara.

  • Gregory, tó ń gbé lórílẹ̀-èdè Kánádà máa ń ní ẹ̀dùn ọkàn àti ìsoríkọ́ tó lékenkà.

Àmọ́, Anja, Delina àti Gregory kò jẹ́ kí àwọn ìṣòro yìí paná ayọ̀ wọn. Báwo ni wọ́n ṣe ṣe é?

Òwe Bíbélì kan sọ pé: “Ìwọ ha ti jẹ́ kí ìrẹ̀wẹ̀sì bá ọ ní ọjọ́ wàhálà bí? Agbára rẹ yóò kéré jọjọ.” (Òwe 24:10) Kókó ibẹ̀ ni pé: Ojú tá a bá fi ń wo ìṣòro tá a ní ló máa pinnu bí ìgbésí ayé wa ṣe máa rí. Ìyẹn ni pé tá a bá rẹ̀wẹ̀sì nígbà ìṣòro, ńṣe ni ipò wa tún máa burú sí i. Àmọ́ tí a kò bá rẹ̀wẹ̀sì, tí a kò sì ro ara wa pin, a máa lè ṣe ìpinnu tó dáa, a sì máa láyọ̀ láìka ìṣòro náà sí.

Jẹ́ ká wo bí ìmọ̀ràn yìí ṣe wúlò fún Anja, Delina àti Gregory.