Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

TA LÓ ṢIṢẸ́ ÀRÀ YÌÍ?

TA LÓ ṢIṢẸ́ ÀRÀ YÌÍ? Bí Ọ̀pọ̀lọ́ Gastric Brooding Ṣe Ń Bímọ Lọ́nà Àrà

TA LÓ ṢIṢẸ́ ÀRÀ YÌÍ? Bí Ọ̀pọ̀lọ́ Gastric Brooding Ṣe Ń Bímọ Lọ́nà Àrà

ORÍLẸ̀-ÈDÈ Ọsirélíà ni ọ̀pọ̀lọ́ gastric brooding tí à ń sọ yìí wà. Àwọn kan rò pé àwọn ọ̀pọ̀lọ́ yìí ò sí mọ́ láti ọdún 2002. Ohun tó jọ ọmọ aráyé lójú jù nípa ọ̀pọ̀lọ́ yìí ni ọ̀nà àrà tó gbà ń bímọ. Èyí tó jẹ́ abo á kọ́kọ́ gbé ẹyin rẹ̀ mì, ẹyin náà á sì máa dàgbà níkùn rẹ̀ fún nǹkan bí ọ̀sẹ̀ mẹ́fà. Lẹ́yìn tí àwọn ẹyin náà bá dàgbà di ọmọ ọ̀pọ̀lọ́, á pọ̀ wọ́n jáde látẹnu.

Báwo ló ṣe wá ń ṣe é tí ẹyin tó gbé mì kì í dà bí oúnjẹ ṣe máa ń dà nínú ikùn rẹ̀? Àṣírí ibẹ̀ ni pé tí ọ̀pọ̀lọ́ náà bá ti gbé ẹyin rẹ̀ mì, kì í jẹun mọ́, ásíìdì tó ń mú kí oúnjẹ dà níkùn rẹ̀ á dáwọ́ iṣẹ́ dúró. Ó dà bíi pé kẹ́míkà tó ń jáde lára ẹyin tí ọ̀pọ̀lọ́ náà gbé mì ni kì í jẹ́ kí ásíìdì sun jáde níkùn rẹ̀ mọ́.

Iṣẹ́ tí ọ̀pọ̀lọ́ yìí ń ṣe láti tọ́jú àwọn ọmọ ikùn rẹ̀ kì í ṣe kékeré, torí pé abo ọ̀pọ̀lọ́ yìí lè gbé nǹkan bí ẹyin mẹ́rìnlélógún [24] mì, nígbà táwọn ẹyin náà bá sì máa dàgbà nínú rẹ̀, ọ̀pọ̀lọ́ náà á ti wú gan-an. Kó lè yé wa dáadáa, ká sọ pé obìnrin aboyún kan wúwo tó kìlógíráàmù méjìdínláàádọ́rin [68] tí ọmọ mẹ́rìnlélógún [24] sì wà nínú rẹ̀, tí ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn sí fẹ́rẹ̀ẹ́ tó kìlógíráàmù méjì-méjì, lápapọ̀, òun fúnra rẹ̀ á ti wúwo tó nǹkan bí àádọ́fà kìlógíráàmù [110]. Bẹ́ẹ̀ gẹ́lẹ́ ni oyún ọ̀pọ̀lọ́ yìí máa ń wúwo! Ńṣe ni ikùn rẹ̀ máa ràn tantan débi pé ẹ̀dọ̀fóró inú rẹ̀ á pẹlẹbẹ mọ́ àyà rẹ̀, kò sì ní lè fi mí mọ́. Èyí ló máa ń fà á tí ó fi máa ń fi awọ ara rẹ̀ mí síta.

Lẹ́yìn ọjọ́ mélòó kan tí àwọn ẹyin náà bá ti di ọ̀pọ̀lọ́, ìyá wọn á pọ̀ wọ́n jáde. Tó bá sì fura pé ewu kan fẹ́ wu wọ́n, kì í jẹ́ kó pẹ́ tó fi máa ń pọ wọ́n jáde. Ìgbà kan wà táwọn olùṣèwádìí rí ọ̀pọ̀lọ́ yìí níbi tó ti pọ̀ ọmọ mẹ́fà jáde lẹ́ẹ̀kan náà! Nígbà tí wọ́n wọn ibi tí ọ̀pọ̀lọ́ yìí wà síbi tó pọ àwọn ọmọ rẹ̀ sí, ó tó nǹkan bí i mítà kan, torí pé ńṣe ló máa ń pọ àwọn ọmọ rẹ̀ jáde lẹ́nu bí ìgbà téèyàn bá ta ọfà!

Àwọn ẹlẹ́kọ̀ọ́ ẹfolúṣọ̀n sọ pé ọ̀pọ̀lọ́ yìí kì í ti ẹnu bímọ tẹ́lẹ̀ àmọ́ ìyípadà ń wáyé díẹ̀díẹ̀ lára rẹ̀ títí tó fi di ọ̀pọ̀lọ́ gastric brooding tó ń bímọ látẹnu, tó bá jẹ́ pé bọ́rọ̀ ṣe rí nìyẹn, ìyípadà náà ò lè wáyé díẹ̀díẹ̀, ó ní láti ṣẹlẹ̀ lójijì ni. Ọ̀gbẹ́ni Michael J. Tyler, tó jẹ́ ara àwọn ẹlẹ́kọ̀ọ́ ẹfolúṣọ̀n ṣàlàyé ìdí tọ́rọ̀ fi rí bẹ́ẹ̀, ó ní: “Kò dájú pé ṣísẹ̀-n-tẹ̀lé ni ọ̀nà ìbímọ ọ̀pọ̀lọ́ náà yí pa dà, torí pé ọ̀nà àrà tó gbà ń bímọ díjú gan-an débi pé kò ní lè bímọ tí nǹkan kékeré bá yí pa dà lára rẹ̀.” Tyler tún sọ pé: “Àlàyé tó bọ́gbọ́n mu tí mo lè ṣe ni pé ẹ̀ẹ̀kan náà ni ọ̀pọ̀lọ́ yìí di bẹ́ẹ̀.” Àwọn kan pe ìṣẹ̀lẹ̀ ẹ̀ẹ̀kan náà yìí ní iṣẹ́ ìṣẹ̀dá. a

Kí lèrò rẹ? Ǹjẹ́ bí ọ̀pọ̀lọ́ gastric brooding ṣe ń bímọ lọ́nà àrà kàn ṣàdédé rí bẹ́ẹ̀ ni? Àbí ẹnì kan ló ṣiṣẹ́ àrà yìí?

a Nínú ìwé kan tó ń jẹ́ Origin of Species, ọ̀gbẹ́ni Charles Darwin sọ pé: “Ìyípadà tó máa ń wáyé nínú àwọn ohun alààyè kò lè ṣẹlẹ̀ lójijì, díẹ̀díẹ̀ làwọn ìyípadà náà á máa wáyé.”