Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

OJÚ ÌWÒYE BÍBÉLÌ

Ìsoríkọ́

Ìsoríkọ́

Kí ni ìsoríkọ́?

“Mo ti di aláìbalẹ̀-ọkàn, mo ti tẹrí ba mọ́lẹ̀ ní ìwọ̀n tí ó dé góńgó; Láti òwúrọ̀ ṣúlẹ̀ ni mo ń rìn káàkiri nínú ìbànújẹ́.”—Sáàmù 38:6.

OHUN TÁWỌN AṢÈWÁDÌÍ KAN SỌ

Òótọ́ ni pé gbogbo èèyàn ló máa ń ní ìdààmú lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, àmọ́ ìsoríkọ́ jẹ́ àìlera tí kì í lọ bọ̀rọ̀ tí kì í sì í jẹ́ kéèyàn lè ṣe àwọn ohun tó yẹ ní ṣíṣe lójoojúmọ́. Àwọn ọ̀mọ̀ràn kò fohùn ṣọ̀kan lórí ohun tó túmọ̀ sí láti banú jẹ́ àti ìbànújẹ́ tó ti di àìsàn síni lára. Àmọ́ ṣá o, a lè sọ pé èrò tí kò tọ́ táwọn kan máa ń ní lágbára gan-an, nígbà míì èyí máa ń jẹ́ kí wọ́n rò pé àwọn ò já mọ́ nǹkan kan, wọ́n sì lè máa dá ara wọn lẹ́bi ṣáá.

OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ

Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa àwọn ọkùnrin àti obìnrin tí wọ́n ní èrò tí kò tọ́. Bí àpẹẹrẹ, Bíbélì sọ pé, Hánà “ní ìkorò ọkàn.” Àwọn Bíbélì kan sì túmọ̀ gbólóhùn yìí kan náà sí “ìbànújẹ́ ọkàn” àti “ìdààmú tó pàpọ̀jù.” (1 Sámúẹ́lì 1:10) Nígbà kan, ìbànújẹ́ tó bá wòlíì Èlíjà pọ̀ débi pé ó gbàdúrà pé kí Ọlọ́run gba ẹ̀mí òun!—1 Àwọn Ọba 19:4.

Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù gba àwọn Kristẹni ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní níyànjú pé kí wọ́n “máa sọ̀rọ̀ ìtùnú fún àwọn ọkàn tí ó soríkọ́.” (1 Tẹsalóníkà 5:14) Ìwé kan tá a ṣèwádìí nínú rẹ̀ sọ pé gbólóhùn náà “ọkàn tí ó soríkọ́” lè tọ́ka sí àwọn “tí ìṣòro ìgbésí ayé bò mọ́lẹ̀ fún ìgbà díẹ̀.” Ó ṣe kedere nígbà náà pé, kódà àwọn ọkùnrin àti obìnrin olóòótọ́ tó wà láyé nígbà tí wọ́n kọ Bíbélì pẹ̀lú máa ń ní ìdààmú ọkàn nígbà míì.

Ṣé ẹni tó ní ìsoríkọ́ ló jẹ̀bi?

“Gbogbo ìṣẹ̀dá ń bá a nìṣó ní kíkérora pa pọ̀ àti ní wíwà nínú ìrora pa pọ̀ títí di ìsinsìnyí.”—Róòmù 8:22.

OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ

Bíbélì kọ́ wa pé àìgbọràn àwọn tọkọtaya àkọ́kọ́ ló fa àìsàn. Bí àpẹẹrẹ, Sáàmù 51:5 sọ pé: “Pẹ̀lú ìṣìnà ni a bí mi nínú ìrora ìbímọ, nínú ẹ̀ṣẹ̀ sì ni ìyá mi lóyún mi.” Róòmù 5:12 sì ṣàlàyé pé “ẹ̀ṣẹ̀ ti tipasẹ̀ ènìyàn kan [ẹ̀dá èèyàn àkọ́kọ́, ìyẹn Ádámù] wọ ayé àti ikú nípasẹ̀ ẹ̀ṣẹ̀, ikú sì tipa báyìí tàn dé ọ̀dọ̀ gbogbo ènìyàn nítorí pé gbogbo wọn ti dẹ́ṣẹ̀.” Nítorí pé a ti jogún àìpé látọ̀dọ̀ Ádámù, gbogbo wa la lè ṣàìsàn, ó lè jẹ́ àìlera tàbí ìdààmú ọkàn. Ìdí nìyẹn tí Bíbélì fi sọ pé, “gbogbo ìṣẹ̀dá ń bá a nìṣó ní kíkérora pa pọ̀ àti ní wíwà nínú ìrora pa pọ̀.” (Róòmù 8:22) Ṣùgbọ́n, Bíbélì tún fún wa ní ìrètí tí dókítà kankan kò lè fún wa. Ìrètí náà sì ni ìlérí tí Ọlọ́run ṣe pé ayé tuntun alálàáfíà kan ń bọ̀, gbogbo àìsàn àti àìlera yóò sì di àwátì, títí kan ìsoríkọ́.—Ìṣípayá 21:4.

Kí lo lè ṣe tó o bá ní ìsoríkọ́?

“Jèhófà sún mọ́ àwọn oníròbìnújẹ́ ní ọkàn-àyà; ó sì ń gba àwọn tí a wó ẹ̀mí wọn palẹ̀ là.”—Sáàmù 34:18.

ÌDÍ TÓ FI ṢE PÀTÀKÌ

Kò sí bó o ṣe lè pinnu ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sí ẹ, àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ búburú míì sì lè kàn ẹ́ nígbà míì. (Oníwàásù 9:11, 12) Àmọ́, o lè wá ọgbọ́n dá sí i tí o kò fi ní máa banú jẹ́ nígbà gbogbo.

OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ

Bíbélì sọ pé àwọn tó bá ń ṣàìsàn nílò ìtọ́jú ìṣègùn. (Lúùkù 5:31) Torí náà tó bá jẹ́ pé àìláyọ̀ ti di àìsàn sí ẹ lára, kò sí ohun tó burú níbẹ̀ tó o bá lọ gba ìtọ́jú ìṣègùn. Bíbélì tún sọ pé ó ṣe pàtàkì pé ká máa gbàdúrà. Bí àpẹẹrẹ, Sáàmù 55:22 sọ pé: “Ju ẹrù ìnira rẹ sọ́dọ̀ Jèhófà fúnra rẹ̀, òun fúnra rẹ̀ yóò sì gbé ọ ró. Kì yóò jẹ́ kí olódodo ta gbọ̀n-ọ́n gbọ̀n-ọ́n láé.” Àdúrà kì í kàn ṣe oògùn amáratuni o. Jèhófà Ọlọ́run lò ń bá sọ̀rọ̀ tó o bá gbàdúrà, ó sì “sún mọ́ àwọn oníròbìnújẹ́ ní ọkàn-àyà.”—Sáàmù 34:18.

Ó tún máa ṣe ẹ́ láǹfààní tó o bá sọ ohun tó ń ṣe ẹ́ fún ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ rẹ kan. (Òwe 17:17) Ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó ń jẹ́ Daniela sọ pé: “Ẹnì kan tóun náà jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà fara balẹ̀ bá mi sọ̀rọ̀ títí mo fi sọ fún un pé mo máa ń ní ìsoríkọ́. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ ọdún ni mo ti fi ọ̀rọ̀ náà pa mọ́, mo wá mọ̀ pé bí mo ṣe sọ ohun tó ń ṣe mi yẹn gan-an ló dáa. Ó jọ mí lójú gan-an pé ara lè tù mí pẹ̀sẹ̀ bẹ́ẹ̀.”