MARCH 15, 2022
SOUTH KOREA
Iná Ńlá Ba Ọ̀pọ̀ Nǹkan Jẹ́ Lágbègbè Méjì Lórílẹ̀-Èdè South Korea
Láti March 4, 2022, iná ńlá kan ti jó ohun tó lé ní ẹgbẹ̀rún lọ́nà mọ́kàndínlọ́gọ́ta (59,288) éékà igbó, ìyẹn sì ti mú kí ẹgbẹẹgbẹ̀rún èèyàn sá kúrò nílé wọn. Àdánù tí iná yìí ti fà ni àdánù tó tíì burú jù nílẹ̀ South Korea.
Ìpalára Tó Ti Ṣe Fáwọn Ará Wa
Akéde mẹ́rìnlélógójì (44) ló ti sá kúrò nílé wọn
Ilé kan ti bà jẹ́ pátápátá
Bá A Ṣe Ran Àwọn Ará Wa Lọ́wọ́
Àwọn akéde tó sá kúrò nílé wọn ń gbé lọ́dọ̀ àwọn mọ̀lẹ́bí wọn tàbí ọ̀dọ̀ àwọn ará míì tó ń gbé níbi tí ò fi bẹ́ẹ̀ léwu
A dá Ìgbìmọ̀ Tó Ń Ṣètò Ìrànwọ́ Nígbà Àjálù kan sílẹ̀ láti ran àwọn ará lọ́wọ́
Bá a ṣe ń ran àwọn ará lọ́wọ́, bẹ́ẹ̀ là ń tẹ̀ lé gbogbo òfin táwọn elétò ààbò ṣe lórí àrùn Kòrónà
Àdúrà wa ni pé kí Jèhófà bù kún àwọn ará lọ́kùnrin àti lóbìnrin tó ń ṣe gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe láti dúró ti àwọn ará wọn nígbà wàhálà.—Òwe 17:17.