Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Arákùnrin Mark Sanderson ń sọ àsọyé ní àkànṣe ìpàdé tí wọ́n ṣe nílùú Warsaw, lórílẹ̀-èdè Poland

MAY 3, 2022
ÌRÒYÌN KÁRÍ AYÉ

“Ẹ Jẹ́ Kí Àjọṣe Yín Pẹ̀lú Jèhófà Túbọ̀ Máa Lágbára Sí I”

Àkànṣe Ìpàdé Tí Wọ́n Ṣe Fún Àwọn Ará Wa Lókun Lórílẹ̀-Èdè Poland àti Ukraine

“Ẹ Jẹ́ Kí Àjọṣe Yín Pẹ̀lú Jèhófà Túbọ̀ Máa Lágbára Sí I”

Ní April 26, 2022, Arákùnrin Mark Sanderson, tó jẹ́ ọ̀kan lára Ìgbìmọ̀ Olùdarí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà lọ sí orílẹ̀-èdè Poland láti fún àwọn arákùnrin àti arábìnrin tí ogun lé kúrò ní orílẹ̀-èdè Ukraine lókun.

Àwọn arákùnrin tó ń ṣiṣẹ́ ní Gbọ̀ngàn Àpéjọ lórílẹ̀-èdè Poland

Wọ́n ṣe àkànṣe ìpàdé kan ní April 30, 2022. Gbogbo ìjọ tó wà lórílẹ̀-èdè Poland àti Ukraine ni wọ́n pè wá síbẹ̀. Lára àwọn tí a pè láti wá sí Gbọ̀ngàn Àpéjọ tó wà ní Warsaw fún àkànṣe ìpàdé tá a ṣe náà ni àwọn tí ogun lé kúrò láti orílẹ̀-èdè Ukraine àti àwọn tó ń ṣèrànwọ́ fún àwọn tí àjálù dé bá. Gbogbo àwọn tó gbádùn àkànṣe ìpàdé náà látorí ẹ̀rọ àtàwọn tó wà ní Gbọ̀ngàn Àpéjọ láti orílẹ̀-èdè Poland àti Ukraine lé ní ẹgbẹ̀rún lọ́nà igba ó lé àádọ́ta (250,000).

Arákùnrin Sanderson sọ pé: “Kárí ayé ni àwọn ará lọ́kùnrin àti lóbìnrin ń rántí yín nínú àdúrà wọn. Bákan náà, ojoojúmọ́ la máa ń gbàdúrà fún àwọn ará lórílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà àti Ukraine ní oríléeṣẹ́ wa àti láwọn ìgbà tí Ìgbìmọ̀ Olùdarí bá ń ṣe ìpàdé wọn.” Ó tún fi dá wọn lójú pé “bí ẹ tiẹ̀ ń kojú ìṣòro, kò túmọ̀ sí pé Jèhófà ti fi yín sílẹ̀. Ó mọ ohun tí ẹ̀ ń kojú, ó nífẹ̀ẹ́ yín, ó sì máa wà pẹ̀lú yín pàápàá jù lọ lásìkò tẹ́ ẹ̀ ń kojú wàhálà yìí.”

Àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin tí ogún lé kúrò nílùú ń wò àkànṣe ìpàdé ní ìlú Mariupol, lorílẹ̀-èdè Ukraine

Arákùnrin Sanderson ń bá ọ̀rọ̀ wọn lọ pé: “Ẹ jẹ́ kí àjọṣe yín pẹ̀lú Jèhófà túbọ̀ máa lágbára sí i. Ohun tó ṣe pàtàkì sí wa ni bí ìgbàgbọ́ wa ṣe máa lágbára sí i, tí àá sì túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà lẹ́yìn ìṣòro yìí. Ohun tí Jèhófà fẹ́ ká ṣe nìyẹn.”

Alàgbà kan tó ń jẹ́ Serhiy ní ìlú Odessa, lórílẹ̀-èdè Ukraine sọ pé: “Mi ò kì í fi bẹ́ẹ̀ rí oorun sùn lẹ́nu ọjọ́ mẹ́ta yìí, torí mò ń ṣàníyàn, ẹ̀rù sì ń bà mí torí mi ò mọ ohun tó lè ṣẹlẹ̀ sí mi. Àmọ́, àkànṣe ìpàdé yẹn ti jẹ́ kó túbọ̀ dá mi lójú pé Jèhófà ń bójú tó àwa èèyàn rẹ̀ lápapọ̀, kódà ó tún ń bójú tó wa lẹ́nì kọ̀ọ̀kan.”

Arábìnrin Tatiana tó wà lára àwọn tí ogun lé kúrò nílùú Kyiv, lórílẹ̀-èdè Ukraine sọ pé: “Òní ni mo rí bí Jèhófà ṣe sún mọ́ mi tó, ṣe ló dà bí ìgbà tí Jèhófà gbá mi mọ́ra, tó sì jẹ́ kí n mọ̀ pé òun nífẹ̀ẹ́ mi. Ó dá mi lójú pé ibi yòówù ká wà, Jèhófà wà pẹ̀lú wa.”

A nífẹ̀ẹ́ àwọn ará wa lọ́kùnrin àti lóbìnrin gan-an, ó sì dá wa lójú pé àkànṣe ìpàdé yìí tí jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé Jèhófà máa ń fi “ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ” hàn sáwọn èèyàn rẹ̀.​—Sáàmù 136:1.